“Ọdún 1854 ni wọ́n gbé ilé ẹjọ́ yìí kalẹ̀, a kò ní agbẹjọ́rò, kò sì sóhun tó lè yẹ ìdàjọ́ wa”

Àkọlé fídíò, Ile ẹjọ Idi Ere

Njẹ o mọ pe ile ẹjọ ibilẹ kan wa nipinlẹ Ogun, nibi ti awọn eeyan maa n gbe ẹjọ wọn lọ ti wọn si ti maa n pari ẹjọ naa lai si wahala kankan?

Alaga ile ẹjọ ibilẹ ọhun, Samuel Olufemi Tanimoowo to jẹ Oluwo Ake, ṣalaye fun BBC Yoruba pe wọn gbe ile ẹjọ naa kalẹ lati maa ran kabiesi lọwọ.

Idi Ere, ni aafin Alake ilẹ Ẹgba ni ile ẹjọ ọhun wa, wọn si ti ṣagbekalẹ rẹ lati ọdun 1854 nigba ti Alake akọkọ jẹ.

Ile ejo

“Ile ẹjọ yii lo ga julọ”

Ile ẹjọ naa fara jọ ile ẹjọ to ga julọ ti ijọba apapọ.

Gẹgẹ bii ohun ti Tanimoowo sọ, ki wọn to gbe ẹjọ wa sọdọ awọn, wọn ti maa n kọkọ ṣe ẹjọ naa ni igboro, ti baale agbegbe naa ko ba le yanju rẹ, wọn maa gbe lọ sile Ogboni.

Ti apa wọn ko ba ka ẹjọ naa nile Ogboni, ni wọn to maa n gbe lọ si ọdọ awọn ni idi Ere.

O ni “Gbogbo ẹjọ ti wọn n da nibi, ibi lo maa n pari si... ẹjọ ti wọn ba ti gbe wa sibi, ohun ti a ba da nibi lo maa jẹ opin ẹjọ naa.

“Idi niyi ti awọn eeyan fi maa n sọ pe ẹjọ ku s’Ake.”

Irufẹ ẹjọ wo ni wọn n da ni Idi Ere?

Alaga ile ẹjọ naa ṣalaye pe awọn ẹjọ to jọ mọ ọrọ ilẹ ni awọn ṣa ba maa n da ju.

O ni “Ikini, ẹjọ ilẹ, ẹjọ ẹbi tabi ilẹ, boya awọn ẹbi kan, wọn n ja tori wọn pin ilẹ wọn.”

“Awọn ti ariyanjiyan wa lori oko tabi ilẹ ti baba wọn fi silẹ ti wọn ko dẹ le yanju rẹ laarin ara wọn, wọn maa gbe wa sibi.”

Tanimoowo ni awọn ko ni agbẹjọro kankan, awọn funra wọn lo n ṣe ifọrọwanilẹnuwo fun ẹni to ba gbe ẹjọ wa ti awọn yoo si ṣe ẹjọ naa bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ.

Wo fidio oke yii fun ẹkunrẹrẹ.