'Ìtọ̀ la n mu lábẹ́ ọkọ̀ ojú omi táa sá pamọ́ sí láti Eko dé Brazil'

Àwọn ọkùnrin naa

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Meji lara awọn ọmọ Naijiria ti wọn doola ninu ọkọ̀ oju omi kan ni Brazil ti sọ pe ìtọ̀ ara wọn ni wọn mu lasiko irinajo wọn.

Àwọn ọkùnrin mẹ́rin naa gba ọ̀nà ẹ̀bùrú wọ abẹ ọkọ̀ oju omi nla kan to gbera lati ipinlẹ Eko, ni ireri pe ilẹ̀ Europe lo n lọ.

Ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹfà, ọdun 2023 ni wọn gbéra nílùú Eko.

Lẹyin ọjọ mẹrinla ni ọkọ oju omi naa gúnlẹ̀ si ìlú Vitória , ni orilẹede Brazil.

Awọ́n eniyan naa sọ pe ọrọ̀ ajé ti ko dara ni Naijiria, ipenija ààbò ati wahala oṣelu, lo mu ki àwọn sa kuro nílùú.

Ninu ọrọ ti meji lara àwọn ọkùnrin naa sọ ninu fidio kan to tẹ BBC lọ́wọ́, wọn ni irinajo naa jẹ eyi to léwu pupọ.

Ẹnikan lara wọn, Roman Goimene Friday sọ pe ìyàlẹ́nu lo jẹ nigba ti ọkọ oju omi naa gúnlẹ̀, tí àwọn ọlọpaa to fẹ ko wọn sọkalẹ sọ pe Brazil ni àwọn wà.

"Irinajo naa léwu pupọ, mi o si ni gbe iru ìgbésẹ̀ bẹẹ mọ láyé mi."

Ẹnikeji, Thankgod Opemipo Mathew, sọ pe ìrírí buruku gba a ni irinajo naa jẹ́.

"Mo ti pinnu ninu ọkan mi lati kuro ni Naijiria, mo kan lo ìgboyà lati rinrinajo naa ni."

Ninu iroyin ti ileeṣẹ iroyin Daily Mail gbé jáde, 5,600 ni kilomita ti wọn rìn lati Eko si Vitória ni Brazil.

Àwọn ọkùnrin naa sọ fun ileeṣẹ iroyin ọ̀hún pe ìtọ̀ ti awọn ba tọ̀, ati omi òkun ni awọn n mu lẹyin ti oúnjẹ ati omi ti wọn kó dání tán.

Bakan naa ni wọn ni awọn ti pinnu lati duro ni Brazil. Awọn meji yòókù ti pada si Naijiria lẹyin ti wọn ba àwọn aláṣẹ ni Brazil sọ̀rọ̀ lati da wọn pada.

Iléèṣẹ́ iroyin Reuters sọ pe lasiko irinajo ẹgbẹrun mẹta maili ọ̀hún, awọn ọkunrin naa so ara wọn mọ àwọ̀n (net) ti wọn so mọ abẹ ọkọ̀ oju omi, ki wọn o ma ba à jábọ́ sinu òkun.

Bakan naa ni wọn ko sọ̀rọ̀ nitori ki àwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀ oju omi ma baa gbọ́ ohùn wọn.