Sanusi gba Tinubu nímọ̀ràn lẹ́yìn àbẹ̀wò rẹ̀ sí ológun Niger

Aworan Emir Sanusi, ati General Tchan

Oríṣun àwòrán, twitter.com/sayyidaalhurraa

Alhaji Muhammadu Lamido Sanusi, Emir kẹrinla niluu Kano, ti sabẹwo si Olori ijoba ologun lorilẹede Niger, General Tchani.

Gomina tẹlẹ fun banki apapọ lorilẹede Naijiria gbera lati se ipade lẹyin ti ipade ajọ ECOWAS, ajọ apapọ ilẹ Adulawọ ati asoju ilẹ Amẹrika kọ lati so eso rere lori rogbodiyan iditẹgbajọba to waye lorilẹede Niger.

Ijọba ologun Niger wogile sise ipade pọ pẹlu Ajọ ECOWAS nitori fifi awọn ofin kan de orilẹede Niger, ti wọn si tun palasẹ pe ki awọn orilẹede to sumọ Niger ti ẹnu ibode wọn .

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Saaju ni Adari ikọ ọmọogun to fi ipa gbajọba ni Niger ti kọ lati gbalejo ikọ Ajọ Ecowas to fẹ sẹ abẹwo si orilẹede naa.

Awọn adari ikọ naa ni awọn ko lee gba ki wọn wọle si orilẹede wọn nitori awọn ko lee pese aabo fun awọn alejo naa.

Awọn igbimọ lati ikọ Ecowas, ikọ African Union to fi mọ ikọ United Nations ni o yẹ ki wọn balẹ si orilẹede Niger ni oni.

Rogbodiyan to n lọ ní Niger kí ṣe ti ìjọba nìkan lati yanju - Sanusi jabọ fun Tinubu

Gẹgẹ bi Emir ana se sọ fun awọn akọroyin, lẹyin to wa jabọ fun Aarẹ Bola Tinubu lori ipade to se pẹlu awọn olori ijọba Niger, o ni rigbodiyan to waye lorilẹede Niger ki i se ti ijọba nikan lati lati yanju

O ni gbogbo igbinyanju ni awọn saa lati ri pe alaafia jọba pada laarin orilẹede naa ati ajọ ECOWAS.

"Mo wa lati sọ fun Aarẹ abo ipade mi pẹlu awọn olori Niger. A ko ni dẹkun igbiyanju wa lati mu igbọraẹniye wa laarin ikọ mejeeji.

"Ọrọ yii ki se ti ijọba nikan, gbogbo ọmọ Niger ati Naijiria lo gbọdọ fọwọsowọpọ wa ọna abayọ si rogbodiyan yii.

Emir Sanusi wa jẹ ko di mimọ pe ki i se ijọba lo ran oun lọ Niger lati lọ ba awọn olori ijọba sọrọ.

"Rara ijọba kọ lo ran mi. Awọn osisẹ ijọba mọ pe mo fẹ lọ si ibẹ sugbọn emi ni mo mọmọ gbera lati lọ si Niger, ma si tẹsiwaju lati ma se ipa temi gẹgẹ bi olori."

Àkọlé fídíò, Quadruplet: Bàbá Ìbẹrin ní òun fẹ́ sálọ àmọ́ òun kò fẹ́ èpè ìyàwó òun ní òun fi dúró

Ẹgbẹ́ ajìjàgbara tuntun dìde ní Niger láti tako ológun tó dìtẹ̀gbàjọba

Rhissa Ag Boula

Oríṣun àwòrán, NIGER PRESIDENCY

Olori ẹgbẹ ajijagbara ati oloṣelu nigba kan ri lorilẹ-de Niger, Rhissa Ag Boula ti sọ pe oun ti ko ẹgbẹ kan jọ lati da Aarẹ ti wọn le kuro lori oye, Mohamed Bazoum, pada.

Afojusun ẹgbẹ ọhun, to pe orukẹ rẹ ni Council of Resistance for the Republic, CRR, ni lati da ijọba pada fun oloṣẹlu ni Niger.

Ẹgbẹ naa ni akọkọ iru rẹ ti yoo gbiyanju lati gbena woju ijọba ologun to ditẹgbajọba lorilẹ-ede ọhun.

Ajọ idagbasoke iwọ oorun Afrika, ECOWAS, to ti sọ ṣaaju pe oun yo kogun ja Niger ti sọ pe oun yoo ṣe ipade mii lọjọbọ ọsẹ yii lori rogboyan naa.

A duro ti ECOWAS lati da ijọba pada fun oloṣelu ni Niger - CRR

Atẹjade kan ti ECOWAS fi lede sọ pe “Awọn ti Niger gbẹkẹle pe yoo daabo bo o, ti dalẹ rẹ.”

Ikede ẹgbẹ Ag Boula tuntun yii n jade lẹyin ti gbogbo akitiyan ECOWAS lati yanju ọrọ naa ni wọrọwọ fori ṣọpan.

Awọn orilẹ-ede mii ti ologun ti gbajọba bii Mali ati Burkina Faso ti sọ pe digbi lawọn wa lẹyin Niger, wọn si ti ke si ajọ agbaye, UN, lati maṣe jẹ ki ẹnikẹni kogun ja Niger.

Ẹwẹ, awọn adari iditẹgbajọba naa ti fofin de awọn aṣoju African Union, United Nations, to fi mọ ECOWAS pe wọn ko gbọdọ wọ orilẹ-ede naa mọ.

CRR ti sọ pe oun yoo fọwọsowọpọ pẹlu ECOWAS atawọn ẹgbẹ mii to n gbiyanju lati da ijọba pada fun oloṣelu ni Niger.

Ta ni Rhissa Ag Boula?

Rhissa Ag Boula wa lara awọn to jijagbara fun ẹya Buzaye laarin ọdun 1990 si 2000 ni iha Ariwa Niger.

Wọn gba a siṣẹ ninu ijọba Bazoum lẹyin ija naa, toun ti aṣaaju rẹ, Mahamadou Issoufou.

Bo tilẹ jẹ pe a ko le sọ bi abara ẹgbẹ Rhissa Ag Boula ṣe pọ, amọ igbagbọ wa pe ikede ẹgbẹ rẹ ọhun yoo kọ awọn aditẹgbajọba Niger lominu.

Wayi o, lati igba ti awọn ologun ti gbajọba ni Niger ni wọn ti fi Aarẹ Mohamed Bazoum, si atimọle ninu ile rẹ.

Àkọlé fídíò, Kàyèéfì! Ojú àti ahọ́n di àwátì lára okú Goodluck l'óru mọ́jú

Ológun Niger gbégi dínà ojú òfurufú, bàálù kò lé gbéra tàbí wọlé

Awọn ologun nilẹ Niger

Oríṣun àwòrán, Reuters

Awọn ologun to gbajọba lorileede Niger ti gbegi dina iwọlejade baluu kankan loju ofurufu ilẹ ọhun

Eyi waye lẹyin ti wọn kọ eti ikun si aṣẹ ajọ Ecowas pe ki wọn da ijọba pada fun ijọba alagbada ti wọn yọ nipo bi bẹẹ kọ wọn yoo jẹ iyan wọn niṣu.

Igbesẹ yi jọ bi ẹni pe awọn ologun orileede naa ti n gbara di de igba ti awọn ọmọ ogun ajọ Ecowas yoo kogun jawọn lori iditẹgajọba.

Lọjọ Aiku yi ni gbedeke ti ajọ Ecowas fun awọn ologun wa sopin ti Ecowas ko si ti kede igbesẹ to kan bayii.

Ileeṣẹ ologun Niger sọ pe awọn ni igbagbọ pe ipalẹmọ lati kogun ja awọn ti bẹrẹ ni pẹrẹwu lorileede meji kan ni Africa ṣugbọn wọn ko tọka si ẹri to fi idi ọrọ yi mulẹ.

Lati ana ti gbedeke wa sopin, Ecowas naa ko sọ nkankan lori igbesẹ to kan.

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbégi dínà ojú pópó nítorí àìrí omi àti iná lò

Aworan afihan ọkọ ija ologun ofurufu

Oríṣun àwòrán, Nigerian Airforce

"Ẹnikẹni to ba fipa wọ ilẹ wa, la fi ipa ati agbara to le pade wọn''

Aṣoju ileeṣẹ ologun Niger kan lo kede titi pa oju ofurufu yi lori ẹrọ amohunmaworan ni irọlẹ ọjọ Aiku.

O ni awọn kẹfin ipalẹmọ ogun lorileede meji kan ni Africa ati pe awọn ko ni jẹ ki eeyan kankan ka awọn mọ lae gbe igbesẹ.

O ni ẹnikẹni to ba fipa wọ ilẹ awọn ''lawọn yoo fi ipa ati agbara to le pade iru igbesẹ bẹẹ''

Ṣaaju lọjọ Aiku yi kanna, niṣe lawọn ọgọrọ alatilẹyin ologun to gbajọba ṣe iwọde ti wọn si kora jọ si papa iṣere nla to wa ni Niamey.

Wọn kọ orin bẹẹ si ni wọn n sọ pe digbi lawọn wa lẹyin ologun bi wọn ko ṣe tẹriba fawọn orileede to fẹ tẹnu bọ ọrọ ilẹ wọn.

Iditẹgbajọba yi ni ẹlẹẹkeeje iru rẹ ti yoo waye ni iwọ oorun ati aarin gbungbun Africa laarin ọdun mẹta sẹyin

Alamuleti Niger, Burkina Faso ati Mali ti wọn wa labẹ idari ologun, ni awọn yoo gbe lẹhin Niger ti ọrọ ba di ti ogun

Ajọ Ecowas lawọn lero pe ọrọ yi yoo yanju ni tubi n nubi amọ wọn kilọ pe awọn ti ṣeto igbaradi kalẹ ti ologun fi le koju awọn aditẹgbajọba ni Niger.

Amọ ṣa ki igbesẹ kankan nipa didoju ija kọ ologun Niger to le waye, awọn olori orileede Ecowas ni lati buwọlu.

Ninu gbogbo nkan taa n wi yi naa ni alamuleti meji Niger, Burkina Faso ati Mali ti wọn wa labẹ idari ologun ti sọ pe awọn yoo gbe lẹhin Niger ti ọrọ ba di tologun.

Lati ilẹ okere naa, America ati ilẹ Faranse sọ pe digbi lawọn yoo gbe lẹhin Ecowas ṣugbọn wọn ko sọ pato boya atilẹyin to niṣe pẹlu ọmọ ogun ni.

Orileede Niger jẹ ọkan pataki lara ilẹ agbaye to n pese alumọni Uranium.

Orileede Faranse wa lara awọn to n jẹ anfaani alumọni yi lọdọ wọn.

Awọn orileede miran naa si ri Niger gẹgẹ bi alatilẹyin nipa kikoju awọn agbesunmọmi to lajọṣepọ pẹlu Islamic State ati al-Qaeda ni ilẹ Africa.