Ọkàn àwọn èèyàn ìlú Sokoto kò balẹ̀ mọ́ nítorí ogun tó ṣeéṣe kó wáyé ní Niger

Oríṣun àwòrán, GIFT UFUOMA/BBC
Iwọnba wakati diẹ lo ku bayii fun ijọba ologun to ditẹgbajọba ni Niger lati da ijọba pada fun Aarẹ Mohamed Bazoum tabi ko maa mura ogun ECOWAS.
Ọjọ Aiku to kọja ni awọn adari ECOWAS, ti Aarẹ Bola Tinubu jẹ olori fun, fun awọn ologun naa ni gbedeke ọjọ meje lati da ijọba pada tabi ki wọn koju ogun.
Amọ ni iha Ariwa Naijiria to sunmọ Niger, ọpọ awọn olugbe agbegbe naa ni ẹru ti n ba bayii lori ohun to le ṣẹlẹ, ọpọ wọn si ti bu ẹnu atẹ igbesẹ ECOWAS lati lọ kogunja Niger, to jẹ alabagbe wọn.
Gẹgẹ bii ohun ti a mọ pupọ ninu awọn ogun ti yoo koju Niger lo jẹ ọmọ ogun lati orilẹ-ede Naijiiria.
Ẹwẹ, ọpọ igba ni awọn ọmọ Naijiria maa n wọ Niger, ti awọn ọmọ orilẹ-ede Niger naa si maa ṣe bẹẹ bakan naa.
Lọjọ Abamẹta ni ile igbimọ aṣofin Naijiria ke si ijọba apapọ lati wa ojutu mii si ọrọ naa yatọ si ogun.
Lọwọ yii, ọkan awọn eeyan ipinlẹ Sokoto ti ikọ ọmọ ogun Naijiria ‘8 Division’ wa, to wa ni fẹgbẹkẹgbẹ Niger, ko balẹ mọ.
Sokoto ni ilu to pin Naijiria ati Niger, o si ṣeeṣe ko jẹ pe ibẹ naa ni awọn ologun ti yoo koju Niger yoo ti pade.

Oríṣun àwòrán, GIFT UFUOMA/BBC
Gẹgẹ bii ohun ti awọn olugbe Sokoto sọ, eeyan kan ninu marun un to wa ni Sokoto lo jẹ ọmọ orilẹ-ede Niger.
Fun apẹrẹ, pupọ ninu awọn eeyan agbegbe Sabon-Gari Girafshi lo jẹ ọmọ orilẹ-ede Niger, ti ẹru si n ba wọn pe ti ECOWAS ba kogun ja Niger, yoo kan awọn mọlẹbi awọn.
Ọkunrin kan to jẹ oniṣowo ẹṣọ ara, Sulaiman Ibrahim sọ pe ilu Niamey, ni Niger ni iyawo atawọn ọmọ oun kan wa, wọn si ti ha sibẹ latari iditẹgbajọba to waye nibẹ.

Gẹgẹ bi ohun to sọ, gbogbo igba ti oun ba n pe ẹrọ ilewọ rẹ ni ki n lọ, ti oun ko si mọ irufẹ ipo to wa.
Zainab Saidu, to jẹ ọmọ bibi ilu Dosso ni Niger amọ to fẹ ọkrunrin ọmọ Naijiria ni Sokoto sọ pe ọmọ oun abikẹyin to jẹ ọkunrin ṣi wa ni Niger, ẹru si n ba oun lori ohun to le ṣẹlẹ si ti ogun ba bẹrẹ.
O ni “Ẹru n ba mi, Ọlọrun n gbọ, ẹru n ba gbogbo wa ti a wa lati Niger, ko si ẹni ti ọkan rẹ balẹ paapaa lẹyin ti a gbọ pe Naijiria le kogun ja Niger.”

Oríṣun àwòrán, GIFT UFUOMA/BBC
Lọjọ Ẹti ni awọn olori ologun ni iwọ oorun ilẹ adulawọ sọ pe awọn ti ṣetan lati bẹrẹ ogun, amọ awọn adari ECOWAS ṣi n tẹsiwaju lati ba awọn ologun to gbajọba naa jiroro fun ọna abayọ.
Amọ ṣa, pẹlu gbogbo ohun to n ṣẹlẹ lọwọ, awọn ologun to gbajọba ni Niger ni awọn ko ṣetan lati gbe ijọba kalẹ.
Ibeere to wa gba ẹnu ọpọ eeyan bayii ni pe, ki ni yoo ṣẹlẹ lẹyin ti gbedeke ti ECOWAS fun awọn aditẹgbajọba naa ba ti pari?












