Tinubu kọ̀wé sílé aṣòfin lórí àwọn ìpinnu ECOWAS fún Niger

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK
Ààrẹ Nàìjíríà, Bola Ahmed Tinubu ti kọ̀wé ránṣẹ́ sílé aṣòfin àgbà láti bèèrè fún àtìlẹyìn láti ṣe àmúṣẹ àwọn ìpinnu àjọ ECOWAS lórí àwọn ìgbésẹ̀ tako orílẹ̀ èdè Niger níbi tí àwọn ológun ti fipá gba ìjọba ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá.
Gẹ́gẹ́ bí Tinubu ṣe sọ nínú lẹ́tà tó kọ ránṣẹ́ sílé aṣòfin ní ìgbésẹ̀ náà jẹ́ títẹ̀lé ìfẹnukò àjọ ECOWAS láti wá ojútùú sí bí àwọn ológun ṣe yẹ àga mọ́ ààrẹ Mohamed Bazoum nídìí.
Ohun tí Tinubu kọ sínú lẹ́tà ni pé ó ń bèèrè fún àtìlẹyìn láti ti ẹnubodè Nàìjíríà sí Niger àti pé ọkọ̀ òfurufú kò gbọdọ̀ ná Nàìjíríà sí Niger mọ́ lásìkò yìí.
Bákan náà ló bèèrè fún ìgbáradì àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà láti kọ kojú àwọn ológun Niger tó bá ṣe wí pé gbogbo ọ̀nà láti pẹ̀tù sí ááwọ̀ náà kò bá wáyé ní tùbí-ǹ-nùbí.
Ní ọjọ́ Àìkú tó kọjá ni ECOWAS fẹnukò lórí àwọn ìjìyà kan tako Niger, tí wọ́n sì fún àwọn ológun náà ní ọjọ́ méje láti dá ìjọba padà ààrẹ Bazou tí àwọn ènìyàn dìbò yàn.
ECOWAS tún gbé ìgbìmọ̀ dìde lọ́jọ́bọ̀, ọjọ́ Kẹrin oṣù Kẹjọ láti lọ jíròrò pẹ̀lú àwọn ológun orílẹ̀ èdè Niger lórí bí wọ́n ṣe máa dá ìjọba padà sétò ìjọba àwaarawa.
Ẹ̀wẹ̀, ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ẹtì ọjọ́ Karùn-ún oṣù Kẹjọ ni àwọn ológun Niger kéde pé àwọn kò ní àjọṣepọ̀ kankan pẹ̀lú Nàìjíríà, Amẹ́ríkà, Togo àti France mọ́ lẹ́yìn tí ìjíròrò tí ikọ̀ ECOWAS lọ báwọn ṣe forí sọ́pọ́n.
Ní ọjọ́ Ẹtì yìí bákan náà ni ìgbìmọ̀ àwọn ọmọ ẹkùn ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Adúláwọ̀ yóò parí ìpàdé ọlọ́jọ́ mẹ́ta tó ń wáyé ní Abuja níbi tí wọ́n ti ń jíròrò lórí bóyá kíkó ogun ja Niger yóò ti wáyé tí gbogbo ọ̀nà ìpẹ̀tù sááwọ̀ kò bá kó ẹsẹ járí.
Gbogbo ìjìyà ECOWAS fún Niger la faramọ́ – UK

Oríṣun àwòrán, TWITTER
Orílẹ̀ èdè United Kingdom ti juwọ́ káare sí àwọn adarí àjọ ECOWAS fún àwọn ìgbésẹ̀ àtàwọn ìjìyà tí wọ́n gbé tako àwọn ológun tó dìtẹ̀ gba ìjọba ní orílẹ̀ èdè Niger.
Akọ̀wé ilẹ̀ òkèrè UK, James Cleverly ló sọ ọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn tó ṣèpàdé pẹ̀lú ààrẹ Nàìjíríà, Bola Ahmed Tinubu ní ìlú Abuja ní ọjọ́rú.
Clerverly ló ṣe àbẹ̀wò sí Nàìjíríà lára ìrìnàjò rẹ̀ sí àwọn orílẹ̀ èdè ilẹ̀ Adúláwọ̀ mẹ́ta èyí tó bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀sẹ̀ yìí.
Nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìpàdé tó ṣe pẹ̀lú Tinubu, tó tú jẹ́ alága ECOWAS, Cleverly ní UK faramọ́ àwọn ìgbésẹ̀ ECOWAS náà àti pé ó túmọ̀ sí pé wọn ò ní fi ààyè gba ìwà ipá láti fi máa mú àyípadà bá ìṣèjọba.
Cleverly ṣàlàyé pé UK ní ìfarajìn sí ètò ìjọba àwaarawa ní Nàìjíríà àti àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn ní ẹkùn Adúláwọ̀ àti pé yóò dùn mọ́ àwọn nínú láti rí kí àwọn alágbádá gba ìjọba padà ní Niger láìpẹ́.
Ó fi ku pé kí èyí le wa sí ìmúṣẹ, ìjọba UK yóò máa ní àjọsọ pẹ̀lú àwọn orílẹ̀ èdè ECOWAS láti lè dá àláfíà àti ètò ìjọba àwaarawa padà ní Niger.
Bákan náà ló tún ṣàlàyé pé òun àti Tinubu jọ sọ̀rọ̀ lórí ètò ààbò, ìdókoòwò àti pàápàá bí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà yóò ṣe kópa nínú àpèrò ìdókoòwò tó jẹ̀ àjọṣepọ̀ láàárín UK àti ilẹ̀ Adúláwọ̀ tí yóò wáyé ní London lọ́dún tó ń bọ̀.
Ó tun kan sáárá sí Tinubu fún àwọn ètò àtúnṣe tó ti bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà tó ti gba ipò ààrẹ tó sì ní ìrètí wà pé láìpẹ́ UK yóò túnbọ̀ fẹ́ dókoòwò pẹ̀lú Nàìjíríà.
Ogun ńlá yóò wáyé tí ẹ bá fi ogun dá Bazoum padà sí ìjọba - Ààrẹ ológun Mali àti Bukina Faso

Oríṣun àwòrán, Reuters
Awọn olori ijọba ologun lorilẹede Mali ati Burkina Faso ti se ikilọ fun ajọ ECOWAS lori ipinnu wọn lati lo ogun fi da Aarẹ Mohamed Bazoum pada si ijọba ni jasi oogun nla pẹlu wọn
Eyi lo waye lẹyin idunkoko ti ajọ ECOWAS se pe awọn setan lati lo gbogbo ọna lati da Aarẹ naa pada.
Bazoum ni o si wa ni ahamọ awọn olori ologun lẹyin ti iditẹgbajọba naa waye
Orilẹede Burkina Faso ati Mali ni ibasepọ pẹlu orilẹede oke okun paapa orilẹede France ati Russia.
Ikilọ yii lo wa ninu atẹjade kan to orilẹede mejeeji buwọlu lẹyin ti Aarẹ Chad, Mahamat Idris Deby balẹ si orilẹede NIger, to si ti bẹrẹ igbesẹ pẹlu asẹ ajọ ECOWAS lati yanju awọn naa.
Ninu atẹjade ti Burkina Faso ati Mali buwọlu, wọn dunkoko mọ ajọ ECOWAS pe ti wọn ba if kesi awọn ologun lati da si ọrọ naa, awọn yoo fi ẹgbẹ ECOWAS silẹ, ti awọn yoo si gbe lẹyin orilẹede Niger
Orilẹede Faso, Mali ati Guniea ni ajọ ECOWAS fofin de lẹyin ti iditẹgbajọba waye nibẹ.
Lọjọ Aiku ni ajọ ECOWAS kede pe awọn fun ologun ni gbedeke ọjọ meje lati da ijọba pada fun Aarẹ Bazoum, ẹni to si wa ni ahamọ wọn.
Awọn olori ologun ni Niger ko ti fesi si ọrọ yii sugbọn wọn jẹ ko di mimọ pe awọn setan lati da bobo orilẹede Niger lọwọ ẹnikẹni to ba fẹ fi ogun ja orilẹede naa
Bakan naa ni wọn fẹsun kan orilẹede France pe o n gbero lati fi ogun ja orilẹede Niger sugbọn France ko ti fesi si ẹsun naa.















