Kà nípa pàtàkì ayẹyẹ Ìwọ́pópó nínú àjọ̀dún Osun Osogbo nílùú Oṣogbo

Ayẹyẹ Ọdun Ọsun Osogbo nipinlẹ Ọṣun ti bẹrẹ loni pẹlu ayẹyẹ 'Iwopopo' ti wọn ma fi n ṣe igbalumọ àti iwure fun ṣiṣe ayẹyẹ nla naa fun gbogbo eeyan tí yoo rín ìrìnajo wa lati pada layọ sì ibugbe wọn.
Ajọdun Ọdun Ọsun Osogbo ni o jẹ ayẹyẹ ọlọdọọdun ti ẉọn maa n ṣe fun Orìṣa Ọsun ni ojubo odo omi Ọsun na niluu Osogbo.

Ataoja ti Osogbo, Oba Jimoh Abidemi Oyetunji Olanipekun Larooye keji, pẹlú awọn olori laafin, awọn oloye, awọn araalu Osogbo, onile ati alejo ni wọn kọẉọrin pẹlu Oba alade wọn lati rìn ìrin ìwọpópó lo sì agbegbè Gbeẹmu ni bí ti gbogbo eto tí gbera sọ.


Nigbati Ọba Jimoh ati gbogbo awọn eeyan de agbegbe gbeemu ni bi ti gbogbo ètò ayẹyẹ igbalumọ ati adúra ti bẹr̀ẹ ni pẹyẹru.
Lẹyin ti ọdun bẹrẹ pẹlu ayẹyẹ iwọpopo naa ni titan atupa oluju mẹrindinlogun yoo tẹle ni ojo mẹfa lẹyin igbalumọ ati adura.

Bibọ Ade Ọba yoo tẹle lati bu ọla fun awọn ti o jẹ saaju Ọba to wa lori apere lọwọlọwọ
Dida Ifa Arugba lati yan ọmọbinrin wundia lati idile Ọba ti yoo gbe ohun egbo lọ si odo Ọsun lọjọ asekagba ọdun naa
Asekagba ayẹyẹ ọdun Osun ni yoo waye ni ọjọ Kọkanla oṣu kẹjọ ọdun 2023















