Bazoum fojú hàn fún ìgbà àkọ́kọ́ lẹ́yìn táwọn ológun yẹ àga mọ́ ọ nídi ní Niger

Aarẹ Deby ati Bazoum

Oríṣun àwòrán, Mahamat Idriss Deby Itno/Facebook

Fun igba akọkọ lẹyin igba ti awọn ologun yẹ aga mọ s ni idi, Aarẹ Mohammed Bazoum ti orilẹede Niger tifoju han ninu fọto kan ti oun ati aarẹ orilẹede Chad, Mahamat Idris Deby jijọ ya.

Aarẹ Mahamat Deby lọ si ilu Niamey ti ṣe olu ilu orilẹede Niger gẹgẹbi ara igbesẹ lati pẹtu si aawọ laarin awọn ọmọ ogun aditẹgbajọba a6ti ajọ orilẹede iwọ oorun afrika, ECOWAS.

Ọjọ meje pere lajọ ECOWAS fun awọn ọmọogun aditẹgbajọba lorilẹede Niger lati fi gbe ijọba pada fun aarẹ Bazoum.

Awọn ọmọ ogun alaabo ni ile aarẹ orilẹede Niger lo ditẹ gba ijọba mọ Bazoum lọwọ lọjọru ọjọ kẹrindinlọgbọn.

Lati igba naa wa ni ẹnikẹni ko ti ri oju rẹ ni gbangba mọ, ti ko si si ẹni to le sọ boya aye lo wa tabi wọn ti da ẹmi rẹ legbodo.

Awọn orilẹede agbaye, tofi m awọn ajọ agbaye gbogbo bii UN, ECOWAS, ilẹ Amẹrika, France ati Russia lo ti n ke sawọn ọmọogun aditẹgbajọba naa pe ki wọn tu aarẹ Bazoum ati ẹbi rẹ silẹ.

Mọ nípa àbájáde ìpàdé ECOWAS lórí ìditẹ̀gbàjọba Niger
Aworan

Oríṣun àwòrán, TWITTER/ECOWAS

Ni bi ipade ti awọn olori orilẹede ajọ ECOWAS se lana ni awọn kede pe awọn fun ikọ ologun orilẹede Niger ni gbedeke ọsẹ kan pere lati da ijọba pada fun Aarẹ Mohammed Bazoum.

Ajọ ECOWAS jẹ ko di mimọ pe awọn setan lati lo gbogbo ọna lati da ijọba awarawa pada si orilẹede Niger.

Awọn igbesẹ yii ni awọn kede pe o le waye ni tipatipa ati pe awọn olori ikọ ologun orilẹede ti bẹrẹ ipade lori asẹ naa.

Bakan naa ni wọn iditẹgbajọba ọhun ni o n koko mọ dukia ati ẹmi awọn ọmọ orilẹede Niger.

Nnkan mẹjọti awọn olori orilẹede pinnu lati se ni kiakia

  • Titi gbogbo ẹnu ibode, lori ilẹ ati ofurufu orilẹede ECOWAS ati Niger
  • Fifi opin si irinajo ọkọ ofurufu to n lọ tabi to n bọ lati orilẹede Niger
  • Fidi opin tarakata laarin orillẹede Niger ati orilẹede Ecowas
  • Titi apo owo orilẹede naa pa
  • Titi gbogbo dukia orilẹede Niger pa, eyi to wa ni banki apapọ Ecowas
  • Fifi opin ipese iranlọwọ fun orilẹede Niger
  • Gbigbe igi dana iwe irinna awọn ologun to kopa ninu iditẹgbajọba naa
  • Bakan pẹlu gbogbo awọn mọlẹbi awọn ologun, awọn eeyan ilu, ilẹẹkọ ati ileeṣẹ ijọba to fọwọ iditẹgbajọba naa.

ECOWAS fáwọn ológun Niger lọ́jọ́ méje láti dá ìjọba padà fún Bazoum

Asia awọn orilẹ ede ECOWAS

Oríṣun àwòrán, PIUS UTOMI EKPEI

Awọn olori orilẹede to wa ninu ajọ ECOWAS ti fun ikọ ologun orilẹede Niger ni gbedeke ọsẹ kan pere lati da akoso orilẹ ede naa pada fun Aarẹ Muhammed Bazoum gẹgẹ bi aarẹ.

Ipinnu yii lo waye lẹyin ipade ti Aarẹ Bola Ahmed Tinubu to alaga ECOWAS ṣe pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ yooku.

Lati igba ti awọn ologun ti gba ijọba ni Niger ni awọn ẹsọ alaabo to n ṣọ Aarẹ Aarẹ Bazoum ti fi si ahamọ.

Olori awọn ẹsọ alaabo naa, Ọgagun Abdourahamane Tchiani kede ara rẹ gẹgẹ bi Olori ijọba.

Ipade ọhun to waye lọjọ Aiku niluu Abuja ni awọn alasẹ ti jẹ ko di mimọ pe Aarẹ Bazoum nikan ni awọn mọ gẹgẹ bi olori orilẹede naa.

Bakan naa ni wọn tun pa a lasẹ fun awọn orilẹede yooku lati ti ẹnu ibode wọn to wọ orilẹede Niger, ti wọn si tun wọgile irina ọkọ ofurufu lọ si orilẹ ede naa.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Aarẹ ajọ ECOWAS, Omar Touray lo kede igbesẹ naa, to si ni imọsi gbogbo awọn olori orilẹede ati awọn olori ologun ajọ ECOWAS ni igbesẹ naa, eyi ti yoo si da Aarẹ Bazoum pada gẹgẹ bi Aarẹ.

O fikun pe ; "Ajọ ECOWAS yoo gbe gbogbo igbesẹ lati da ijọba awaarawa pada si orilẹede Niger.

Touray ṣalaye pe awọn igbesẹ naa le jẹ lilo iwa ipa, to si paṣẹ pe ki gbogbo awọn olori ologun ECOWAS ṣe ipade ni kiakia.

Bakan naa, Touray ni ECOWAS ti fofin de idokoowo laaarin Niger atawọn orilẹ ede to jẹ ara ẹgbẹ ECOWAS ati ti ẹkun Asia.

ECOWAS tun gbe ẹsẹ le karakata laaarin awọn orilé ede yii to fi mọ pipeseawọn ohun amuṣagbara.

"A ti gbẹsẹ le awọn ohun alumọni Niger to wa ni ile ifowopamọ Aqual Central Bank fun igba kan naa ati gbogbo eto idokoowo pẹlu awọn ile ifowopamọ yooku."

Fífi òfin de àwọn ìrànwọ́ tí Niger ń rí gbà lọ́wọ́ àwọn àwọn ilé ìfowópamọ́ tún wà lára àwọn ìjìyà tí ECOWAS fún àwọn ologun tó gbàjọba Niger.

Lara awọn Aarẹ orilẹede to wa nibi ipade naa ni Aarẹ Umaro Sissoco Embalo ti orilẹede Guinea Bissau, Alassane Ouattara ti Cote D'Ivoire ati Faure Gnassingbe ti Togo.

Awọn yooku ni Macky Sall ti Senegal, Patrice Talon ti Benin ati Aarẹ Nana Akufo Addo ti Ghana.

Mó nípa Ààrẹ Niger tuntun, Ọ̀gágun Abdourahmane Tchiani

Aworan

Oríṣun àwòrán, TELE SAHEL

Àkọlé àwòrán, Ogagun Abdourahmane Tchiani

Lọjọ keji ti awọn ologun gbajọba lọwọ Aarẹ Mohamed Bazoum lorilẹede Niger, Ọgagun Abdourahmane Tchiani ti ọpọ mọ si Omar Tchiani farahan lori tẹlifisọn, to si ba awọn araalu sọrọ.

Eyi fihan pe oun ni Aarẹ ologun tuntun fun orilẹede naa.

Ki iditẹgbajọba to waye, oun ni lori awọn ọmọ ologun to n sọ aarẹ.

Iditẹgbajọba yii ti fopin si ijọba awarawa to ti wa lati ọdun 1960 ti orilẹede ti gba ominira.

Tani Abdourahmane Tchiani?

Ẹni ọdun Mejilelọgọta ni aarẹ tuntun naa

Ọgagun Tchiani di olori awọn ẹsọ alabo to n sọ aarẹ lọdun 2011.

Mahamadou Issoufou, ẹni ti Bazoum gba ijọba lọwọ rẹ lo da awọn ẹsọ alabo naa si lẹ lati da bobo ara rẹ lọwọ awọn ologun to n gbinmọ lati gba ijọba nitori igba mẹrin ọtọọtọ ni iditẹgbajọba ti waye ni Niger lati igba ti wọn ti gba ominra lọwọ orilẹede France

Bo ti lẹ jẹ pe ko farahan lasiko ti awọn ọmọ ologun n kede ijọba tuntun naa sugbọn, o ti han gbangba pe Tchaini ni yoo lewaju ijọba ologun naa.

Tchiani ni wọn ti kọkọ fẹsun kan pe o n gbero lati gba ijọba lọdun 2015 sugbọn o farahan ni ileẹjọ lọdun 2018 pe oun ko lọwọ ninu iditẹgbajọba naa,

Bakan naa. ileeṣẹ iroyin L'Enqueteur ni lọjọ kẹtadingbọn oṣu keje ki iditẹgbajọba to waye ni Aarẹ Bazoum fẹ yọ Ọgagun naa gẹgẹ bi olori ọmọ ologun ninu igbinyanju rẹ lati yi nnkan pada ninu idari awọn ọmọ ologun lorilẹede naa.

Ninu oṣu kẹrin, Bazoum parọ Ọga agba fun awọn ọmọ ologun, eyi ti iwe iroyin Jeune Afrique ni o lo sokunfa bi ariyanjiyan se waye laarin awọn ologuin.

Lọjọ Kẹtadinlọgbọn oṣu keje, awọn sọrọsọrọ lori tẹlifisan TV5 Monde ni bi ileeṣẹ ologun se n ijakunlẹ lati ọwọ ijọba, iwa jẹgudujẹra ati ẹlẹyamẹya se wọpọ laarin awọn ologun wa lara nnkan to fa iditẹgbajọba naa