Yóò ṣòro fún ológun láti gbàjọba ní Naijria nítorí...

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Olumide Owaduge
- Role, Akọroyin BBC
Onimọ nipa eto abo kan, Akin Adeyi ti sọ pe yoo ṣoro ki awọn ologun to fi ipa gbajọba ni Naijiria gẹgẹ bo n ṣe waye lawọn orilẹ-ede Afirika mii to yi Naijiria ka lẹnu ọjọ mẹta yii.
Ọrọ yii lo n jade lẹyin iṣẹlẹ ifipagbajọba to waye lana lorilẹede Niger, nibi ti awọn ologun orilẹede naa ti gba ijọba lọwọ Aarẹ Mohamed Bazoum.
Adeyi, to ti fi gba kan jẹ oṣiṣẹ ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ Naijiria, DSS, sọ pe irufẹ ẹya ti pupọ awọn ologun Naijiria ti wa, awọn alakalẹ ti ijọba ti ṣe sẹyin ati awọn idojukọ to n ṣẹlẹ labẹle ni Naijiria yoo mu ko ṣoro ki ologun gbajọba.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, awọn to n sọ pe o yẹ ki awọn ologun gbajọba ni Naijiria ko mọ ohun ti wọn n sọ, nitori ibẹrẹ ogun nikan ni eeyan n mọ, ko si ẹni to n mọ ipari ogun.
Idi ti o ṣe ṣoro fun awọn ologun lati gba ijọba ni Naijiria
Adeyi ni “Lootọ ni ibọn wa lọwọ wọn, ṣugbọn ti ẹ ba wo ọpọlọpọ wọn gan ti wọn wa loke ninu iṣẹ ologun bayii, oloṣelu ni wọn, nitori naa o maa jẹ ko ṣoro fun wọn lati ronu irufẹ nnkan bẹẹ.”
“Ati pe ẹya ṣe pataki ni Naijiria, bi ẹya ṣe n pin wa, to n fiya jẹ wa ni Naijiria naa ni ẹya tun ni anfani tirẹ.”
“Ẹya to wa ninu iṣẹ ologun nji Naijiria bayii yoo jẹ ko ṣoro.
“Nitori bi awọn kan ba n sọ pe ki wọn gbajọba, awọn mii ko ni fọwọ si.”
“Ati pe awọn isọrọ eto abo abẹle ti awọn ọmọ ologun wa n dojukọ lọwọlọwọ bayii ko le jẹ ki wọn le ronu rẹ.”
Gẹgẹ bii ohun ti Adeyi sọ, bi awọn kan ṣe wa ni Bornu ti wọn n koju Boko haram, lawọn mi wa ni Kaduna ti wọn n koju awọn janduku.
O ni ologun ti ko ba niṣẹ lọwọ lo maa n ronu iditẹgbajọba.
Bakan naa lo mẹnuba mii bii imọ ẹrọ, eyii ti yoo mu ko ṣọro fun awọn ologun lati gbimọpọ gbajọba yatọ si bo ṣe maa n waye laye atijọ ti wọn le ṣe ipade ninu yara kan ti ẹnikẹni ko si ni gbọ.
Ki ni ki ijọba ṣe?
Oṣiṣẹ DSS tẹlẹri naa ṣalaye siwaju si pe ijọba gbọdọ mu aye dẹrun fun awọn araalu ki wọn ma ba a maa ronu kan ọrọ awọn ologun ati iditẹgbajọba.
O fi kun pe ko yẹ ki ijọba sun asunpiye nitori pe awọn ologun rẹ le ma gbero iditẹgbajọba.
Adeyi pari ọrọ rẹ pe owo ti ijọba Naijiria fi n ṣe ijọba ti pọ ju, o yẹ ko din awọn owo naa ku ko si na le awọn nnkan amayedẹrun lori fun irọrun awọn araalu.
Getty Images












