A ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ìjàkadì tó wáyé láàrín àwón òṣìṣẹ́ wa àtàwọn òṣìṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n, ọmọlúàbí ni wá – DSS

Aworan fakinfa to waye laarin awọn ajọ DSS ati ileeṣẹ ẹlẹwọn nile ẹjọ

Oríṣun àwòrán, Ibrahim Mansour

Ajọ ọtẹlẹmuyẹ Naijiria, DSS ti sọ pe oun ti bẹrẹ iwadii lati mọ kulẹkulẹ ijakadi to waye laarin awọn oṣiṣẹ rẹ atawọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn nile ẹjọ giga kan niluu Eko.

Agbẹnusọ ajọ naa, Peter Afunanya, lo fi ọrọ naa lede niluu Abuja.

Ti ẹ ko ba gbagbe, awọn oṣiṣẹ ajọ DSS ati NCS kọju ija si ara wọn nile ẹjọ naa to wa lagbagbe Ikoyi, niluu Eko lori ẹni ti gomina CBN ana, Godwin Emefiele yoo ja mọ lọwọ lẹyin ti ile ẹjọ gba beeli rẹ.

Lẹyin ọjọ diẹ ti iṣẹlẹ naa waye, DSS ti wa sọ pe iṣẹlẹ ọhun ko tumọ si pe bi awọn oṣiṣẹ oun ṣe maa n ṣe niyẹn nitori awọn maa n fi iwa ọmọluabi kun iṣẹ wọn.

Atẹjade naa ni “ajọ wa bọwọ fun ofin bẹẹ si ni a bọwọ fun ile ẹjọ gẹgẹ igun kan lara ijọba, a ko si ni ṣe ohunkohun ti yoo dojuti ile ẹjọ tabi ofin.”

“Bakan naa ni ibaṣepọ to dan mọran lo wa laarin awa atawọn ileeṣẹ eto abo mii bii NCS.”

“Bo tilẹ jẹ pe lootọ ni awọn oṣiṣẹ ajọ mejeji ṣe aṣeju, a ti bẹrẹ iwadii ni kikun lori ohun pato to ṣẹlẹ, ati ipa ti onikaluku ko ninu iṣẹlẹ ọhun.”

“A tun fẹ jẹ ki gbogbo eeyan pe ajọ DSS ko ru ofin kankan ninu ọwọ to fi mu ọrọ Emefiele bo tilẹ jẹ awọ kan n sọrọ kobakungbe lati ba orukọ wa jẹ.”

Afunanya pari atẹjade naa pe iṣẹlẹ naa ko ni di DSS lọwọ lẹnu iṣẹ rẹ.

A kò fẹ́ kí DSS àti Iléeṣẹ́ ẹlẹ́wọ̀n yìnbọ̀n lò jẹ́ ká jọ̀wọ́ Emefiele- Agbẹjọ́rò

Aworan Gomina banki apapọ tẹlẹ Godwin Emefiele

Awọn oṣiṣẹ ajọ ọtẹlẹmuyẹ lorileede Naijiria DSS ti tun mu Gomina banki apapọ Naijiria tẹlẹ Godwin Emefiele lẹyin ti ile ẹjọ gba beeli rẹ.

Adajọ Nicholas Oweibo lẹyin agbeyẹwo sọ lọjọ Iṣegun pe ki wn gba beeli Emefiele pẹlu ogun miliọnu Naira ki o si wa ni ọdọ awọn ileeṣẹ ẹlẹwọn Naijiria.

Amọ ajọ DSS fi tipa tikuku ba awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ẹlẹwọn fa wahala titi ti Emefiele fi pada ja si wọn lọwọ.

Iṣẹlẹ yi jẹ ohun to kaakiri oju opo ayelujara Naijiria to si ti n mu iriwisi ọtọọtọ wa tawọn mii n sọ pe DSS tapa si aṣẹ ile ẹjọ.

Amọ ṣa agbẹjọro agba fun Emefiele Joseph Daudu ti sọ pe awọn gba ki DSS gbe onibara awọn lọ ni ki ọrọ ma ba di wipe DSS ati ileeṣẹ ẹlẹwọn yinbọn lu ara wọn.

Ọpọ wakati ni Emefiele lo ninu ile ẹjọ lẹyin ti adajọ ti ni ki DSS jọwọ rẹ fawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ẹlẹwọn.

Nigba ti gbogbo nkan walẹ nile ẹjọ, ohun ti awọn akọroyin ri ni wi pe awọn DSS fi ọkọ Hilux gbe Emefiele lọ.

Ohun ti araalu sọ re lori fakinfa to waye nile ẹjọ lori ọrọ Godwin Emefiele ti adajọ gba beeli rẹ

Bawọn DSS ti ṣe ti gbe Gomina banki apapọ tẹlẹ ri Godwin Emefiele lọ lawọn ọmọ Naijiria bọ si oju opo ayelujara ti wọn si n sọ ero ọkan wọn.

Ninu awọn ti a ri loju opo Twitter, ko fẹẹ si ẹni to gboṣuba kare fun ajọ yi bi kii ṣe wọn n ṣe eemọ bi ija ṣe le waye laarin awọn ileeṣẹ ijọba meji.

Pupọ ni ko bojumu bi awọn ajọ DSS ati ileeṣẹ ẹlẹwọn ṣe fi ẹsin wọn han ni ita gbangba.

Wọn ni eleyi ṣafihan pe ko si ibaṣepọ to mọranyin laarin awọn to n ṣe iṣẹ lorukọ ijọba apapọ.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

Skip X post, 2

End of X post, 2

Skip X post, 3

End of X post, 3

Omoyele Sowore to fi igba kan dije dupo aarẹ ni Naijira naa da si ọrọ yi.

O kanlẹ mu afiwe wa laarin nkan to n ṣẹlẹ si Emefiele ati igba tawọn DSS mu oun gaan alara ti wọn si kọ lati tu silẹ.

Ọrọ rẹ da bi ẹni pe o n ṣe kaatan fun Emefiele to naka si pe o wa lara awọn to ṣe atọna bi DSS ṣe fi oun si ahamọ nigba kan ri.

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 4

Kí ló fà ìjà láàrin DSS àti Iléeṣẹ́ ẹlẹ́wọ̀n lẹ́yìn tí iléẹjọ́ gba béèlì Emefiele?
Aworan awọn DSS ati oṣiṣẹ ileeṣẹ ẹlẹwọn

Oríṣun àwòrán, Ibrahim Mansour

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ija nla bẹ silẹ laarin ajọ DSS ati ajọ to n mujoto ọgba ẹwọn lorilẹede Naijira lẹyin ti ileẹjọ giga to n joko niluu Eko gba beeli Gomina tẹlẹ fun banki apapọ lorilẹede Naijiria, Godwin Emefiele .

Ọrọ di iṣu ata yaunyaun ni kete ti Adajọ Nicholas Oweibo gbe idajọ ọhun kalẹ lori taani yoo gbe Emefiele si akata rẹ lẹyin idajọ.

Fọnran to tẹ Ileeṣẹ BBC lọwọ ṣafihan bi awọn osisẹ ajọ DSS se n fa asọ ya mọ ọga agba ọgba ẹlẹwọn kan laraninu ọgba ile ẹjọ.

Adajọ ti pa lasẹ saaju pe ki Emefiele wa ni akata ọgba ẹwọn 'Correctional Center' titi ti yoo fi san beeli ti ileẹjọ ni ko san.

Ko pẹ lẹyin idajọ naa ni ajọ DSS wa ọkọ ayọkẹle wọn si ẹnu ọna ile ẹjọ pẹlu erongba lati gbe Emefiele sinu rẹ kete to ba jade sita.

Eyi lo fa awuyewuye ti agbẹjọro agba fun Emefiele, Joseph Dauda ati awọn akẹgbẹ rẹ si pariwo sita.

Bẹẹ lawọn ajọ ti ọgba ẹlẹwọn naa si n gbinyanju lati gbe Emefiele.

Fakinfa waye lori ẹni ti yoo gbe Emefiele llọ ṣugbọn ajọ DSS lo pada gbe Emefiele kuro nile ẹjọ.

Fọnran fidio yi ṣafihan asiko ti wọn ya aṣọ mọ ọga ileeṣẹ ẹlẹwọn kan lara.

Skip X post, 5
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 5

Ilé ẹjọ́ pàṣẹ kí wọ́n gba béèlì Emefiele lẹ́yìn tó lo ọ̀sẹ̀ Mẹ́fà ní àhámọ́ ájọ DSS
Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ileẹjọ giga ijọba apapọ to n joko niluu Eko ti palasẹ pe ki wọn gba beeli Gomina tẹlẹ fun banki apapọ lorilẹede Naijiria, Godwin Emefiele lẹyin to ti lo ọsẹ mẹfa ni atimọlẹ pẹlu ogun milọnu naira.

Adajọ Nicholas Oweibo kede idajọ lẹyin to gbọ ọrọ lẹnu agbẹjọro Emefiele, Joseph Dauda (SAN)

Bakan naa ni adajọ wọgile ọrọ ijọba apapọ to fẹsun kan Emefiele, to si ni ijọba ko ni ẹri to peye lati ti ọrọ naa lẹyin.

Emefiele, ẹni ọdun ọmọkanlelọgọta ni oun ko jẹ bi ẹsun mejeeji ti ijọba apapọ fi kan pe ohun ija oloro wa ni akoso rẹ.

Ninu ọrọ rẹ, Dauda rọ ileẹjọ lati gba beeli Emefiele nitori ko jẹ ẹsun ti wọn fi kan.

O ni "Ko si nnkan to jọmọ pe ijọba n tako ipe fun beeli yi, ati pe olujẹjọ yii lo jẹ ilumọka osisẹ ile ifowopamọ, ti ko si salọ si ibi kankan, ti ko si le lọ irinajo.

Agbẹjọro ijọba apapọ, Nkiru Jones Nebo tako ipe fun beeli naa, to si ni wọn ko fun awọn olupẹjọ ni akoko to yẹ lati fesi si ohun ti wọn pe fuin.

"Gẹgẹ bi Gomina CBN, eeyan to lagbara ni, to si le dunkoko mọ awọn ẹlẹri. Fifun ni beele le mu ẹru ba awọn ẹlẹri to fẹ wa jẹri niwaju ileẹjọ.

"A rọ ileẹjọ lati wọgile beeli naa."