Wike,El Rufai,Alake wà lára àwọn tí Tinubu kéde orúkọ wọn sípò Mínísítà

Aworan awọn Minista ti wọn forukọ wọn ranṣẹ

O ti pada wa tu sita.

Orukọ awọn ti aarẹ fi ṣọwọ sile aṣofin fun ayẹwo sipo minisita ti pada wa di nkan to han si araalu.

Ninu awọn orukọ ti aarẹ Buhari fi ranṣẹ si ile aṣofin fayẹwo ati ibuwọlu la ti ri Gomina tẹlẹ ipinlẹ Rivers Nyesom Wike.

Gomina tẹlẹ Kaduna ati Ebonyi, Nasir El Rufai ati David Umahi wa lara awọn orukọ taa ribi fidi rẹ mulẹ.

Gomina ipinlẹ Jigawa,Muhammad Badaru Abubakar naa ko gbẹhin.

Ni bayi orukọ mejidinlọgbọn ni aarẹ yi ti fi ṣọwọ fawọn ti yoo ba ijọba rẹ ṣiṣẹ.

Ile aṣofin agba labẹ idari aarẹ Sẹnẹtọ Godswill Akpabio kede orukọ yi ti Femi Gbajabiamila olori oṣiṣẹ nile ijọba fi sọwọ lorukọ aarẹ Tinubu.

Ikede orukọ yi waye lasiko ijoko ile ti o si jẹpe wọn kede orukọ bi gbedeke ti ofin faaye kalẹ ṣe ku ọjọ kan.

Dele Alake to jẹ agbẹnusọ fun aarẹ wa lara awọn orukọ taa ri.

Bẹẹ naa si ni orukọ oludije nigba kan ri fun ipo Gomina ipinlẹ Oyo Adebayo Adelabu.

Ali Pate to jẹ minisita keji fun ileeṣẹ ilera Ali Pate ti pada si ouran pẹlu bi wn ṣe kede orukọ rẹ naa.

Ninu awọn obinrin la ti ri Nkiru Onyejiocha to jẹ ọmọ ile aṣojusofin ri ati Betta Edu olori awọnobirin labẹ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress.

A ṣetán láti kéde orúkọ àwọn mínístà tó kúnjú òṣùwọ̀n láìpẹ́- Amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ Tinubu

Bola Ahmed Tinubu

Oríṣun àwòrán, Other

Ọkan pataki lara amugbalẹgbẹ Aarẹ Bola Tinubu ti sọ fun awọn ọmọ Niajiria pe ki wọn lọ fọkan balẹ.

O sọ pe laipe ni won yoo kede orukọ awọn minista ti yoo ba Tinubu ṣiṣe lati sun Naijiria siwaju.

Amugbalegbe Tinubu yii sọ pe Tinubu mọ ofin tuntun Naijiria pe ọgọta ojọ kò gbọdọ pe ki aarẹ kankan to yan awọn minista ti yoo ba a ṣiṣẹ.

Atip e ọla, ọjọ Eti, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu keje yii ni gbendeke naa yoo pe mọ Tinubu lọwọ.

Ṣé lóòtọ́ ni ilé aṣòfin yóò kéde àwọn mínísítà lónìí? Nnkan tí a mọ̀ nípa rẹ̀ rèé

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Iroyin to n lọ ni pe o ṣeeṣe ki ile aṣofin agba Naijiria, kede orukọ awọn ti Aarẹ Tinubu n gbero lati yan si ipo minisita.

Eyi n waye pẹlu bo ṣe ku ọjọ mẹrin pere ti gbedeke ti ofin lakalẹ fun awọn gomina ati aarẹ lati kede awọn ti yoo ba wọn ṣiṣẹ.

Ninu atunṣe si ofin ọdun 1999, ọgọta ọjọ pere ni awọn gomina ni lati kede awọn kọmisanna wọn, ti aarẹ naa si gbọdọ kede awọn to fẹ yan ni minisita.

Eyi tumọ si pe Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ni titi di ọjọ Satide, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Keje, ọdun 2023, lati kede awọn to fẹ́ yan.

Ọjọ naa ni yoo pe ọgọta ọjọ to bura wọle gẹgẹ bi aarẹ Naijiria tuntun.

Aarẹ yoo fi akọsilẹ orukọ naa ranṣẹ si ile aṣofin, lẹyin naa ni aarẹ ile aṣofin yoo ka orukọ naa jade fun awọn akẹẹgbẹ rẹ.

Iroyin si ti n lọ pe oni, ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹẹdọgbọn ni Sẹnetọ Godswill Akpabio yoo ka awọn orukọ naa.

Eyi ko ṣẹyin bi ẹni to ti fi igba kan jẹ oluranlọwọ fun Aarẹ tẹlẹ, Muhammadu Buhari, Bashir ahmad, ṣe kede loju opo Twitter rẹ pe igbesẹ naa yoo waye.

O ni eyi yoo ri bẹẹ, ti ko ba fi si atunṣe kankan ti ileeṣẹ aarẹ fẹ sẹ si awọn orukọ naa.

Ṣugbọn a ko tii le fi idi iroyin naa mulẹ.

Ọjọ Iṣẹgun, Ọjọru ati Ọjọbọ ni awọn aṣofin ma n ni ijoko wọn.

Akọsilẹ orukọ awọn minisita naa ni igbagbọ wa pe o gbọdọ ni orukọ eeyan kan lati ipinlẹ kọọkan.

Ilana wo ni Naijiria n gba yan awọn minisita rẹ?

Aarẹ orilẹ-ede Naijiria ni ofin fun ni anfaani lati ṣe akojọpọ orukọ awọn minisita to fẹ ba a ṣiṣẹ ninu ijọba rẹ.

Ni ọpọ igba, awọn oloṣelu lati inu ẹgbẹ oṣelu ti aarẹ ti wa, ati diẹ lara awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu alatako lo ma n wa ninu akọsilẹ orukọ naa.

Aarẹ si tun le yan awọn akọṣẹmọṣẹ ti kii ṣe oloṣelu.

Nitori pe ipinlẹ mẹrindinlogun lo wa ni Naijiria, orilẹ-ede Naijiria ma n ni minisita to pọ̀, nitori pe lati ipinlẹ kọọkan, ati ilu Abuja, ni o kere tan, minista kan ti ma n wa.

Lẹyin ti aarẹ ba ṣe akojọpọ awọn orukọ naa tan, lẹyin iranlọwọ, ijiroro, ati ipade oriṣiriṣi pẹlu ẹgbẹ oṣelu rẹ, ni yoo fi orukọ naa ranṣẹ si ile aṣofin.

Awọn aṣofin ni yoo sẹ ayẹwo ati ifọrọwanilẹnuwo fun awọn ti aarẹ fi orukọ wọn ranṣẹ.

Eto ayẹwo yii ma n waye lori awọn iwe ẹri wọn, awọn ibi ti wọn ti ṣiṣẹ ri, awọn ipo ti wọn di mu, ọna ti wọn yoo gba lati yanju awọn ipenija to wa ni ẹka ti wọn fẹ dari, ati bẹẹbẹẹ lọ.

Ẹni to ba yege niwaju awọn aṣofin ni wọn ma n fi ontẹ lu fun aarẹ lati yàn.