Ìjọba Naijiria wọ́gilé àwọn 'App' ayáni lówó kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ìjọba apapọ ti kede orukọ awọn ileeṣẹ ẹyawo ti ko forúkọ silẹ labẹ ijọba apapọ, ti wọn si kede wọn gẹgẹ bi ayederu.
Bakan naa ìjọba ni oun yọ orúkọ ileeṣẹ ẹyawo meji kuro lori ayelujara fun bi wọn ṣe dunkoko mọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria, botilẹ jẹ pe wọn forukọ silẹ.
Ajọ ijọba to n ja fun ẹtọ oníbàárà, FCCPC, ni awọn ti fi awọn orukọ ileeṣẹ ayanilowo ti wọn kọ lati forúkọ silẹ sabẹ igbogun ti.
Ninu atẹjade ọhun ti igbakeji alaga ileeṣẹ naa, Babatunde Irukera fi ọwọ si, o ni " FCCPC ti forukọ awọn ileeṣẹ ayanilowo kan lori ayelujara sita pe ayederu ni wọn nitori wọn ko forukọ silẹ pẹlu ajọ naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
"Orukọ awọn ileeṣẹ ẹyawo yii ni a ti gbe sori itakun agbaye wa fun awọn eeyan lati ri.
O ni ajọ FCCPC yoo tunbọ jara mọ isẹ lati ri pe awọn ileeṣẹ ayanilowo ati ẹka isowo mii to je ojulowo nikan ni yoo ni anfaani lati sisẹ lorilẹede Naijiria ni ọna ti ijọba pese fun wọn.
O wa rọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria lati yago fun awọn ileeṣẹ ayanilowo ti ijọba ti kede gẹgẹ bi ayederu lati ma ba a ko sọwọ awọn onijibiti .
Lasiko to n sọrọ lori awọn ileeṣẹ ayanilowo ti ijọba fofin de patapata , o ni awọn ni Sycamorer Integrated Solutions Limited , Orange Loan ati Purple Credit Limited.
Bakan naa lo ni awọn ti fofin de awọn App wọn, 'GetLoan' ati 'Camelloan' lori ayelujara.
Ọgbẹni Irukere ni awọn gbe igbesẹ yii lẹyin ti iwadi awọn fihan pe ayederu ni awọn ileeṣẹ ayanilowo naa.















