"A ti gbé FUNAAB lọ sílé ẹjọ́ àmọ́ síbẹ̀, kò gbà wá láàyè láti lo Niqob"
Awọn Musulumi ti wọn fẹsun kan fasiti imọ ẹkọ eto ọgbin to wa niluu Abeokuta, FUNAAB, pe ko faye gba awọn lati ṣe idanwo nitori Niqob ti sọ pe awọn yoo fi ile ẹkọ naa silẹ.
Awọn ẹlẹha naa lo sọ ọrọ yii ninu ifọrọwerọ kan lasiko ti BBC ṣabẹwo si ọgba ile ẹkọ ọhun niluu Abeokuta.
Eyi lo n waye lẹyin ti wọn ti kọkọ fẹsun kan awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa pe wọn dẹyẹ si awọn nitori imura awọn, ati pe wọn ko jẹ ki awọn ṣe idanwo nitori imura ọhun.

“Awọn alaṣẹ ko fun wa laaye lati mura bo ṣe wu wa lẹyin ti a lọ sile ẹjọ”
Ọkan lara awọn akẹkọọ naa sọ fun BBC pe iyalẹnu lo jẹ bi wọn ko ṣe jẹ ki awọn ṣe idanwo nitori awọn ti gbe ọrọ naa lọ sile ẹjọ ṣaaju, nibi ti awọn ti bori.
O ni “A ti lọ sile ẹjọ, ile ẹjọ si sọ pe a le maa lo Niqob, eredi ree ti ọpọ awọn akẹkọọ tuntun mii ṣe wa si FUNAAB.”
“Ṣugbọn to ba di akoko idanwo, wọn maa n yọ wa lẹnu pe ki a lo ibomu, eyii n lọ bẹe titi di ọsẹ yii ti gbogbo rẹ dojuru.”
“Wọn ko jẹ ki awọn kan to fẹ sẹ idanwo wọ gbọgan idanwo nitori pe wọn wọ Niqob, nigba mii wọn maa jẹ ki wọn wọle, amọ wọn tun maa pada le wọn bọ sita.”
O ṣoro fun obinrin lati maa wọ agbada ṣe iṣẹ ọgbin - FUNAAB
Ọmọwe Bola Adekola, to jẹ akọwe agba ile ẹkọ naa ṣalaye fun BBC pe imura awọn akẹkọọ naa yoo mu ko ṣoro fun wọn lati kẹkọọ nipa imọ eto ọgbin ti wọn ba wa sile ẹkọ naa.
O ni “Nibi, inu iwe ti wọn ni ka fi kọ yin, gbogbo nnkan to ba wa nibẹ ni a o fi kọ yin.”
“Titi de ibi pe o baa jẹ ọkunrin tabi obinrin, a o kọ wọn bi wọn ṣe n wa ọkọ ‘tractor’ nitori pe ara iṣẹ ọgbin ni.”
“Ṣe ẹni to ba fẹ ṣe gbogbo iyẹn ninu oko le wọ agbada ni?”
“Awa naa ni a mọ irufẹ aṣọ to ṣee ṣe iṣẹ oko... a ti ni khaki... ni a fẹ.”
“Awọn kan tun ti ko ara wọn jọ, ti wọn ni ẹsin tawọn ko gba ki awọn obinrin maa wọ ṣokoto.
Ṣe o ṣeeṣe lati ro iro lọ sinu oko ni, tabi lati ro iro lọ gun tractor? Awa ni a mọ nnkan ti a fẹ ṣe, a si sọ pe a ko fẹ.”
Ọmọwe Adekola ni ọrọ naa ko ni nnkankan ṣe pẹlu ẹsin kankan, bi ko ṣe ohun ti yoo rọ awọn akẹkọọ naa lọrun gẹgẹ bii iṣẹ ti wọn wa kọ.
O fi kun pe awọn alaṣẹ ile ẹkọ ọhun ko ni gba ki awọn kan maa fi ẹsin wọn di iṣẹ lọwọ nitori ti wọn ba gba iru rẹ laaye, awọn mii yoo tun dide ti wọn a si sọ pe “ẹsin tawọn ko gba ki wọn maa mu ada dani.”
Wo fidio oke yii fun ẹkunrẹrẹ ohun ti awọn Musulumi naa atawọn alaṣẹ FUNAB ba wa sọ.
Fásitì FUNAAB kò jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́bìnrin Mùsùlùmí mẹ́ta tó lo Niqob ṣe ìdánwò, ariwo sọ

Oríṣun àwòrán, THURIST
Awọn Musulumi kan ti fẹsun kan ile ẹkọ ijọba apapọ to wa fun eto ọgbin, Federal University of Agriculture Abeokuta, FUNAAB, pe o n dẹyẹ si awọn Musulumi, paapaa awọn ẹlẹha.
Ninu fidio kan ti ẹgbẹ to n ja fun ẹtọ awọn Musulumi, THURIST, fi lede, o ni awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa ko faye gba awọn ẹlẹha ọhun lati ṣe idanwo, ayafi ti wọn ba ṣi aṣọ oju wọn.
Ọkan lara awọn ẹlẹha naa ti ko fi orukẹ rẹ lede sọ pe awọn alaṣẹ FUNAB fi tipatipa mu ohun lati yọ aṣọ oju oun ki oun to kọ indawo.
Wọn fi agidi mu mi yọ ‘niqob’ mi ki n to ṣe idanwo – Akẹkọọ
Bo tilẹ jẹ pe ẹlẹha naa ni oun ṣẹṣẹ wọ ipele kinni nile ẹkọ naa ni, ati pe oun ko ni kaadi idanimọ gẹgẹ bii akẹkọọ, gbogbo akitiyan oun lati sọ irufẹ ẹni ti oun jẹ lai yọ nikọọbu naa lo ja si pabo.
O ni “wọn ni dandan ni ki n yọ nikọọbu mi ti mo ba fẹ ṣe idanwo naa, mo tilẹ gbiyanju lati lo ibomu, sibẹsibẹ, wọn ko gba fun mi.”
“Olori awọn ẹṣo alaabo (CSO) pe mi, o sọ fun mi pe kii n ṣe idanimọ ara mi, mo si sọ fun pe mo ti ṣe bẹẹ.. lẹyinorẹyin, o ni ko si ohun ti oun le ṣe ayafi ti mo ba tẹlẹ ofin to ni ki n ṣi oju mi silẹ.”
Akẹkọọ naa ni kii ṣe igba akọkọ ree ti oun yoo ṣe idanwo pẹlu nikọọbu amọ oun gbọ pe awọn alaṣẹ FUNAB ti gbe ofin tuntun jade ninu atẹjade kan, eyii to tako lilo nikọọbu lasiko idanwo.
Akẹkọọ mii to sọrọ sọ pe oun tilẹ ti n kọ idanwo naa lọwọ ki wọn to gba iwe idanwo ọhun lọwọ oun, ti wọn si le oun jade ninu gbọgan idanwo naa.
Gbogbo akẹkọọ lo gbọdọ fi oju han sita, a si ni ilana aṣọ wiwọ, ti wọn gbọdọ tẹle – FUNAAB
Ẹwẹ, awọn alaṣẹ ile ẹkọ FUNAAb ti salaye bi ọrọ se jẹ niha tiwọn ninu atẹjade kan to fisita lọjọ Aje, ọjọ Kẹtadinlogun osu keje ọdun 2023..
FUNNAB, ninu atẹjade naa salaye pe gbogbo akẹkọọ ile ẹkọ naa lo gbọdọ maa fi oju wọn han ni gbogbo igba.
Akọwe agba FUNAAB, Ọmọwe Bola Adekola lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan.

Oríṣun àwòrán, FUNAAB
O ni “awọn alaṣẹ ile ẹkọ yii fẹ sọ fun awọn akẹkọọ ati oṣiṣẹ lẹẹkan si pe ohun ti a fẹnuko si lọjọ kẹrinla, oṣu Kẹwaa, ọdun 2021 lori bi awọn akẹkọọ yoo ṣe maa mura ko yipada.”
“Atẹjade ti a fi lede lọjọ naa sọ kedere pe gbogbo akẹkọọ lo gbọgbọ maa ṣi oju wọ silẹ ni gbogbo igba fun ami idanimọ.”

Oríṣun àwòrán, FUNAAB













