"Ìgbéyàwó àbúrò mí là lọ ṣe, lẹyìn ogójì ọjọ́ là tó jáde ní àhámọ́ ajínigbé"

''Kilomita marun un lo ku taa fi wọ inu ilu Kankara nigba taa bẹrẹ si ni gbọ iro ibọn.
A da ọkọ wa duro, ṣadede la ri awọn to yọ si wa pẹlu ibọn lọwọ''
Bayi ni Sani Ismail ( a ko da orukọ rẹ gangan) ti o ṣeṣẹ moribọ lẹyin ogoji ọjọ lọwọ awọn ajinigbe, ti ṣe juwe ohun ti oju rẹ ri.
Igbeyawo aburo rẹ lọkunrin lo mu wọn ṣe irinajo lọ si Kankara ni ipinlẹ Katsina.
Sani, aburo rẹ ati awọn mọlẹbi mẹta gbera kuro ni Kano lọjọ Abamẹta taa n wi yii, lae mọ pe ewu nla n bẹ lọna fun wọn.
''O ti pẹ ti mo ti n gbọ nipa awọn ajinigbe ṣugbọn mi o foju ri wọn ri titi di ọjọ ti a pade wọn yii''
''Irinajo naa ko yatọ si awọn eyi taa ti ṣe ṣaaju.
A n rojọ lọ ninu ọkọ ki iro ibọn to mu wa duro. Ka to mọ ohun to n ṣẹlẹ, awọn agbebọn ti ja wa bọlẹ ninu ọkọ''
O tẹsiwaju pe ''wọn fi nkan bo wa loju ki a ma ba mọ ibi ti wọn gbe wa lọ''
Sani, nigba to n sọ ohun ti oju rẹ ri ṣalaye pe ''ọpọ wakati la fi rin, wọn si tun gbe wa lori alupupu ka to de ibi ti wọn gbe wa pamọ si''
"Wọn fi waya de wa lọwọ ati ẹsẹ, pẹlu ibọn la fi n sẹyọ, ẹẹkan lọjọ mẹ́ta ni wọn n fun wa lounjẹ to kere ju oju lọ"
Sani sọ pe nigba tawọn de ibi ti wọn gbe awọn pamọ si yi ni wahala ṣẹṣẹ bẹrẹ.
''Ẹẹkan laarin ọjọ mẹ́ta ni wọn n fun wa lounjẹ. Ounjẹ ti wọn n gbe wa ọhun kere ju oju lọ''
O fi kun pe omi diẹ ni awọn n ri mu lojumọ.
''Mo kan n ronu nipa iyawo ati ọmọ ti mo fi silẹ nile ati pe bawọ ni wọn ṣe fẹ ṣe lairimi.''
Sani kẹjọ ro pe wọn fi waya de awọn lọwọ ati ẹsẹ ati pe bi awọn ba fẹ ṣe ẹyọ, ibọn ni wọn fi n sin awọn lọ tọ.
''Adura ni gbogbo wa n gba pe ki inira yi wa sopin. Lẹyin ogoji ọjọ la to ribi bọ lọwọ wọn. Mi o le gbagbe iriri yii ti maa fi jade laye''
Nipa igbeyawo to ni awọn lọ ṣe, arakunrin yii ni ko si ohun ti yoo di igbeyawọ naa lọwọ.
''A o ni tori iṣẹlẹ yi ka wa ni ki aburo mi ma fẹ iyawo mọ lati Katsina. Ohun to ṣẹlẹ ti ṣẹlẹ. Igbeyawo yoo tẹsiwaju''
Sani wa sọ pe ohun faramọ ọrọ ti Gomina Zamfara tẹlẹ, Ahmed Yerima sọ pe ijiroro lọna kan gbogi, nikan ni wọn le fi wa ojutu si ipenija ijinigbe ati janduku to ti wa nilẹ lati ọjọ yi.
Tinubu ko ni pẹ ṣiṣọ loju ọna abayọ si ijinigbe - Shettima
Igbakeji aarẹ Tinubu,Kashim Shettima sọ pe ko ni pẹ mọ ti aarẹ yoo fi ṣiṣọ loju ọna abayọ rẹ si ipenija aabo ati ijingbe to sodo ni ariwa Naijiria.
''Laarin ọsẹ meloo kan si asiko yi ni ao kede ọna abayọ Pulaaku ti yoo koju gbogbo ipenija tawọn eeyan wa ni iwọ oorun ariwa n koju''
Shettima ni eleyi yoo koju wulẹ́wulẹ ọrọ to wa nidi ajinigbe ati wahala awọn janduku agbebọn ni ilẹ Ariwa.
Laipẹ yi Gomina Zamfara tẹlẹ Sani Ahmed Yarima sọrọ nipa ipenija yi ti Zamfara to sunmọ Katsina naa n koju.
''Ọna abayọ ti e mi ro ni pe ka joko jiroro pẹlu awọn janduku gẹgẹ bi ijọba ṣe ṣe pẹlu awọn agbebọn ti Niger Delta nigba kan ri''
O sọ pe ''eleyi yoo mu opin ba wahala yi patapata.Ọmọ Naijiria lawọn taa n wi yi to si ṣe pe diẹ ajoji ilẹ yi lo wa lara wọn.''
Bẹẹ ni Yarima ṣalaye fun BBC ninu ifọrọwanilẹnuwo.















