Agbébọn fi ẹ̀wọ̀n so èèyàn mẹ́ta mọ́ òpó ilé bíi ẹran

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police
Ara meeriri, mo ri ori ologbo lori atẹ ni isẹlẹ kan to gba ẹnu tan, eyi to waye nipinlẹ Anambra lọsẹ to kọja.
Awọn ọkunrin mẹta kan ni awọn agbebọn so mọ ara opo ile, ti wọn si fi ẹwọn so wọn mọlẹ bii ẹran.
Atẹjade kan ti ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Anambra fi sita lọjọ Aiku lo sisọ loju isẹlẹ yii.
Gẹgẹ bi atẹjade naa, eyi ti Ikenga Tochukwu, tii se alukoro fun ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ naa fọwọsi salaye pe agboole Onyeka Aduba, ti ọpọ eeyan mọ si Totoritor.
Ile naa si lo wa ni abule Umuohi nilu Okija, ni wọn so awọn ọkunrin mẹtẹẹta naa mọ.
Bawo ni asiri ọrọ naa se tu?
Ileesẹ ọlọpaa ni gbajumọ olori ikọ agbebọn naa, Totoritor, ẹni ti ọwọ ọlọpaa tẹ laipẹ yii, lo n ka boroboro nipa ọpọ ọsẹ ti ikọ rẹ ti se, eyi to mu ki asiri isẹlẹ naa tu.
Atẹjade naa ni ọkunrin kan to fi ara gbọta lọwọ Totoritor lo naka aleebu si agbebọn naa, eyi to mu ki ileesẹ ọlọpaa gba mu.
Ikenga ni “Deedee aago mẹrin irọlẹ lọjọ Ẹti, ni ikọ ọlọpaa to wa ni adugbo Akwuzu morile agboole Totoritor, ti wọn si ba ọkunrin mẹta ti wọn so wọn mọlẹ bii ẹran.”
Bakan naa lo salaye pe ọwọ ileesẹ ọlọpaa naa tẹ afurasi agbebọn meji mii lori isẹlẹ naa.
Orukọ awọn ọkunrin afurasi naa ni Okika Chukwujekwu, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn ati Slyvester Okorie Ikwuanusi, ẹni ọdun marundinlọgọta.
“Iwadii ileesẹ ọlọpaa si fihan pe ọjọ ti pẹ ti wọn ti so awọn eeyan naa mọlẹ lai jẹ ki wọn ba ẹnikẹni sọrọ.
Aayan wa si n tẹsiwaju lati gba awọn ọmọ ikọ agbebọn yoku mu laipẹ.

Oríṣun àwòrán, nigeria Police
Ẹ maa fi asiri awọn ọdaran tẹ ba furasi to ileesẹ ọlọpaa to ba sun mọ yin leti – Kọmisana ọlọpaa ni Anambra
Wayi o, Kọmisana ọlọpaa nipinlẹ Anambra, Aderemi Adeoye ti wa rọ awọn eeyan ipinlẹ naa lati kọ eti ọgbọin sawọn asọdun tawọn ikọ ọdaran kan n se kiri.
Amọ o rọ awọn araalu lati maa fọwọsowọpọ pẹlu awọn ileesẹ agbofinro nipinlẹ naa, ki alaafia le jọba pada.
Ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Anambra wa ke sawọn araalu lati maa fi awọn eeyan ti wọn ba fura si pe ọwọ rẹ ko mọ, tabi rin gbere gbere kiri to ileesẹ to ba sun mọ wọn leti.
Adeoye tun rọ wọn lati maa fi oju sọri bii alakan, ki wọn maa baa ko sọwọn awọn agbebọn to n dalu ru kiri.















