A ó ṣiṣẹ́ láti ripé àwọn lọ́balọ́ba ní àṣẹ́ lábẹ́ òfin Naijiria- Abenugan Ilé Aṣòfin

Aworan

Oríṣun àwòrán, Twitter

Abẹnugan Ile Aṣofin ni Naijiria, Abbas Tajudden ti ni awọn aṣofin n ṣiṣẹ lati ri pe awọn lọbalọba ni Naijiria ni ẹtọ ni abẹ ofin.

Abbas ni eyi pọn dandan nitori ipa ti awọn lọbalọba naa n ko ni awujọ lorilẹede Naijiria.

Afin Emir ilu Zazzau, Nuhu Bamalli lo ti sọ bẹẹ lasiko to ṣabẹwo si ilu Zaria, ni ipinlẹ Kaduna fun igba akọkọ.

Abbas to ni oye Iyan ti Zazzau, lo n soju ẹkun Zaria ni ile aṣofin agba fun igba kẹrin.

Lasiko abẹwo rẹ naa lo ni ipa pataki ni awọn ọba n ko ni awujọ, to si ni iwe ofin Naijiria ti ọdun 1999 gbọdọ fi aye gba wọn.

‘’Ọdun mẹta ṣẹyin ni a ṣe ipade lati jiroro lori atunto iwe ofin Naijiria, ti a si sọrọ lori iṣẹ ti o yẹ ki awọn lọbalọba maa ṣe labẹ ofin Naijiria.’’

‘’Mo fẹ fi da yin loju pe asiko naa ti ṣi silẹ bayii, ti emi ọmọ yin gẹgẹ bi adari yoo tun gbe abadofin naa yẹwo lati ri pe awọn ọba ni anfaani to tọ si wọn ni ijọba.’’

Bakan naa ni wọn rọ awọn lọbalọba naa lati ṣiṣẹ pẹlu wọn, ki awọn aṣofin ba le ni itẹsiwaju.

Ninu ọrọ rẹ, Emir naa ni ohun ibanujẹ lo jẹ fun awọn wipe awọn oloṣelu ma n lo awọn ni alopati lẹyin ti wọn ba ti wọle tan, lẹyin idibo.

‘’Ibẹru wọn ni pe a fẹ da ijọba silẹ ni abẹle, ti ko si ri pe, ki wọn fun wa ni aye labẹ ofin Naijiria.’’

Emir naa wa kesi awọn aṣofin naa lati gbe abadofin naa yẹ wo, ki wọn si ṣe ohun to tọ fun awọn lọbalọba.