Ilẹ̀ Yoruba kìí ṣe Biafra, ẹ má gbé ‘sit-at-home’ yín dé ọ̀dọ̀ wa – Gani Adams sí IPOB

Gani Adams

Oríṣun àwòrán, @Ooduagraphics

Aareonakakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams ti sọ fun awọn ajijagbara ilẹ Biafra, IPOB, pe ki wọn maṣe dabaa lati gbe ofin ma lọ oko ma lọ ọja ti wọn gbe kalẹ nilẹ Igbo de ilẹ Yoruba.

O ni ilẹ Yoruba kii ṣe ilẹ Igbo bẹẹ si ni kii ṣe ilẹ Biafra, nitori naa, ki wọn ma ronu lati gbe aṣa naa wa silẹ Yoruba.

Gani Adams lo sọ ọrọ yii ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ iroyin Nigeria Tribune.

Ṣaaju ni ileeṣẹ iroyin kan ti kọkọ sọ pe IPOB ti n mura lati gbe ofin ma lọ oko, ma lọ odo naa wa siluu Eko lọna ati fẹhonuhan lori bi ijọba apapọ ṣe ti Nnamdi Kanu mọle.

Iroyin ọhun ni agbẹnusọ IPOB, Simo Ekpa kede fun awọn ẹya Igbo to wa niluu Eko lati maa mura silẹ fun ofin igbele tiwọn ti yoo bẹrẹ laipẹ.

“Atunto ni ilẹ Yoruba nilo”

Amọ nigba ti Gani Adams n ba ileeṣẹ iroyin Tribune sọrọ, o kilọ fun Ekpa lati ko ila kuro lara ẹkọ, nitori ẹkọ ko kọ ila.

O ni “yoo ṣoro fun mi lati lọ si iha Guusu ila oorun lati lọ maa paṣẹ ohun ti awọn eeyan to wa nibẹ yoo ṣe fun wọn.”

“Nitori naa ko ṣeeṣe ki ẹnikẹni gbe ohun ti wọn ṣe nibẹ wa silẹ wa, a gba a ni imọra lati maṣe dawọle erongba naa rara.”

“Ko gbọdọ dan iru rẹ wo, ilẹ Yoruba kii ṣe ilẹ Biafra, a ṣetan lati bẹgi dina gbogbo igbesẹ lati gbe Biafra republic le wa lori, o gbọdọ jawọ ninu aṣiṣẹ ti awọn kan ṣe lasiko ọdun 1970.”

Ẹwẹ, Adams pari ọrọ rẹ pe ohun ti ilẹ Yoruba n fẹ ni atuntọ ijọba Najiria, ki ẹkun kọọkan le maa ṣakoso ara rẹ bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ.