Ààrẹ Tinubu bá àwọn òbí ọmọ ọdún méjì tí àsìta ìbọn pa ní Delta kẹ́dùn

Oríṣun àwòrán, Others
Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Ahmed Tinubu ti fi ibanujẹ rẹ han si iku ọmọ ọdun meji, Ivan Omhonrina ti asita ibọn pa ni ilu Delta.
Asita ibọn naa lo waye nigba ti awọn oṣiṣẹ ajọ to n gbogun ti aṣilo oogun, NDLEA n ṣiṣẹ ni Okpanam ni ijọba ibilẹ Oshimili, ni ipinlẹ Delta.
Ninu atẹjade aarẹ naa, Tibunu ni iku ọmọ naa dun oun, ti oun si ba awọn mọlẹbi rẹ kẹdun pipadanu ọmọ naa nipaṣẹ aṣita ibọn.
‘’Ko yẹ ki Ivan ku iku oro bayii, a gbọdọ ri pe iru iṣẹlẹ naa ko waye mọ, a ko gbọdọ tun ri iru iṣẹlẹ yii mọ.’’
''Bakan naa ni mo gbadura fun Eronmonsele to farapa ninu iṣẹlẹ naa pe Edua a mu ni ara balẹ.''
''Iru iṣẹlẹ yii buru jai, to si bani ninu jẹ jọjọ, a si gbọdọ wa gbogbo ẹni to lọwọ ninu iṣẹlẹ naa sita fun idajọ otitọ.’’
Ẹwẹ, aarẹ Tinubu ti paṣẹ fun ajọ NDLEA lati rii pe wọn ṣe iwadii iṣẹlẹ naa finifini, ki wọn si fi ọwọ ofin mu ẹnikẹni to ba lọwọ ninu iṣẹlẹ naa.
Bakan naa ni aarẹ naa wa rọ awọn ẹṣọ alaabo ati awọn ẹka eto aabo to ku lati rii pe wọn ṣe iṣẹ wọn bi o ti yẹ, ni asiko to yẹ lai si aṣiṣe bi iru iṣẹlẹ yii.
Àṣìta ìbọn NDLEA pa ọmọ ọdún méjì, mọ̀lẹ́bí bẹ̀bẹ̀ fún ìdájọ́ òdodo

Oríṣun àwòrán, @laurentdarl
Awọn mọlẹbi ọmọ ọdun meji kan, Ivan Omorhiakogbe, ti iroyin sọ pe aṣita ibọn oṣiṣẹ NDLEA ṣekupa nipinlẹ Delta ti n bere fun idajọ ododo lori iku rẹ.
Ẹgbọn oloogbe ọhun tun farapa ninu iṣẹlẹ naa to waye lọjọbọ, amọ o ti n gba itọju lọwọ.
Lasiko to n ṣalaye bi iṣẹlẹ laabi naa ṣe waye fun ileeṣẹ iroyi Channels, baba awọn ọmọ ọhun sọ pe ọjọ Iṣẹgun to n bọ yii lo yẹ ki wọn ṣe ayẹyẹ pe awọn ọmọ naa yoo ṣajọyọ pe wọn bẹrẹ ile ẹkọ amọ ayọ idile oun ti di ibanujẹ.
Ọgbẹni Omorhiakogbe ni dandan ni idile oun gbọdọ ri idajọ ododo gba.
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, aṣita ibọn NDELA ba ọmọ ọdun meji naa, eyii to yọri si iku rẹ, nigba ti ẹgbọn rẹ farapa.
Ni kete ti iṣẹlẹ ọhun waye ni wọn gbe awọn ọmọde mejeji digbadigba lọ sile iwosan ijọba apapọ, FMC to wa niluu Asaba fun itọju, amọ aburo jade laye.
Ẹgbọn Ivan fi oju ṣeṣe, wọn si ti n ṣetọju rẹ ni ẹka ile iwosan naa to n ri si ọrọ oju.
Iṣẹlẹ ọhun waye lasiko ti NDLEA n gbiyanju lati mu awọn afurasi oloogun oloro kan ni ijọba ibilẹ ariwa Okapanam Oshimili, nipinlẹ naa.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ gomina Sheriff Oborevwori, iyẹn Festus Ahon fi lede, o ni ajọ NDLEA gbọdọ ṣe iwadii bi ọrọ naa ṣe waye ni kankan, ki gbọgbo awọn to lọwọ rẹ si foju bale ẹjọ.
Wayi o, ọlọpaa ipinlẹ naa ti ke si awọn araalu lati ṣe suuru, ati pe awọn ti bẹrẹ iwadii.
Ẹwẹ, ajọ NDLEA ti sọ pe awọn naa ti bẹrẹ iwadii ti wọn.
NDLEA ni “a ti n jiroro pẹlu mọlẹbi ti ọrọ naa kan lati ran wa ninu iwadii wa.”
“A fẹ fi da awọn mọlẹbi na atawọn araalu loju pe a o tu iṣu de isalẹ ikoko iṣẹlẹ yii, a o si ṣe gbogbo ohun to tọ labẹ ofin lẹyin iwadii wa.”
















