Ọwọ́ tẹ ọmọ ọdún 19 tó ń gbé òògùn olóró lọ sí òkè òkun- NDLEA

Aworan

Oríṣun àwòrán, NDLEA

Oṣiṣẹ ajọ to n risi igbogunti oogun oloro ni Naijiria, NDLEA ni ọwọ awọn ti tẹ ọmọ ọdun mọkandinlogun kan fun ẹsun gbigbe ogun oloro.

Ọmọ ọdun mọkandinlogun naa ti orukọ rẹ n jẹ Benjamin Nnamani Daberechi ni ọwọ tẹ ni papakọ ofururu Nnamdi Azikiwe International Airport ni ilu Abuja.

NDLEA ni Benjamin n gbe oogun oloro Methamphetamine ti wọn gbe pamọ si inu ede( crayfish) lọ si ilẹ Yuroopu ti o ni oun lọ lati lọ kawe ni fasiti.

Akẹkọọ naa ni ọwọ tẹ ni asiko ti o fẹ lọ wọ ọkọ ofurufu Turkish Airlines.

Lasiko ti wọn n ṣe ayẹwo rẹ ni papakọ naa ni arakunrin naa ni oun lọ si Cyprus fun ẹkọ ohun, amọ lẹyin ayẹwo finifini ni wọn ri oogun oloro 7.2kg ninu apo ede to n gbe lọ.

Agbẹnusọ ajọ NDLEA, Femi Babafemi ninu atẹjade to fi lede ni ayẹwo ohun to gbe naa fihan pe oogun oloro Methampetamine lo gbe sibẹ.

Bakan naa ni ọwọ ajọ naa tẹ awọn miran ti wọn n gbe oogun oloro naa , lọna ati gbe lọ si oke okun.

Ajọ naa ni ọwọ palaba wọn ti segi, ti wọn yoo si foju wina ofin.

Wọn tun kilọ fun awọn araalu lati sọra fun iwa ọdaran, ati aṣilo oogun, ati igbiyanju lati gbe oogun oloro lọ si oke okun.