Woodberry, kòríkòsùn Hushpuppi rí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́jọ he l'Amẹ́ríkà

Oríṣun àwòrán, Others
Ileẹjọ lorilẹede Amẹrika lọjọ ti gbe idajọ kalẹ pe ki Olalekan Ponle, ti ọpọ mọ si Woodberry, lọ ṣe ẹwọn ọdun mẹjọ lọgba ẹwọn fun ẹsun jibiti.
Woodberry, jẹ ọkan lara awọn korikosun Ramon Abbas ti ọpọ mọ si Hushpuppi, ọmọ orilẹede Naijira miiran to n gba atẹgun lọgba ẹwọn lori ẹsun jibiti ori ayelujara.
Ọwọ awọn agbofinro ilẹ Dubia tẹ Hushpuppi ati Woodberry fun ẹsun jibiti ati gbajuẹ ori ayelujara.
Adajọ Robert Gettleman tun pasẹ pe ki Woodberry fara rẹ kalẹ fun ajọ irina lorilẹede Amẹrika lati se eto bi wọn yoo se fi soko pada si orilẹede Naijiria lẹyin to ba pari ọdun mẹjọ rẹ lọgba ẹwọn.
Bakan naa ni Woodberry yoo san owo toto miliọnu mẹfa dọla ($6m) fun eeyan meje to lu ni jibiti.
Tani Hushpuppi ati Woodberry?

Oríṣun àwòrán, Others
Ramon Abass ati Olalekan Ponle, ti ọpọ eeyan mọ si Hushpuppi ati Woodberry ni wọn dero ọgba ẹwọn lẹyin ti ọwọ tẹ lorilẹede UAE lọjọ kẹwaa ọdun 2020 fun orisirisi ẹsun jibiti.
Ileeṣẹ ọlọpaa Dubia fi fọnran bi ọwọ se tẹ wọn sita sori ayelujara.
Iwadii fihan pe Hushpuppi ti lu eeyan toto ẹgbẹrun ni jibiti bilọnu mejidinlaadọsun.
Ileeṣẹ Ọlọpaa kede pe awọn ri owo to to milọnu mẹrindinlogun owo dirham pada.















