Wo bí àwọn ọmọdé yìí kò ṣe bẹ̀rù ikú láti wọ Yúróòpù nípa gbígba orí omi Mediterranean

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ló máa ń kú sínú alagbalúgbú omi Mediterranean Sea nígbà tí wọ́n bá gbèrò láti gba ibẹ̀ lọ sí Yúróòpù, síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ló ṣì ń gba ọ̀nà yìí.
Lára àwọn kan tí orí kó yọ nínú àjálù omi yìí láìpẹ́ tilẹ̀ sọ fún BBC pé kò sí nǹkan tó le dá òun dúró láti dé Yúróòpù.
Àwọn yìí ló bá akọ̀ròyìn BBC, Alice Cuddy sọ̀rọ̀ nínú ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n lọ fi dóòlà wọn nígbà tí ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n wọ̀ fẹ́ rì.
Bí ọkọ̀ ojú omi ńlá tó ń dóòlà àwọn ọkọ̀ yìí ṣe dé ààrin gbùngbùn omi Mediterranean Sea ni wọ́n rí ọkọ̀ ojú omi kan tó ti wà ní bèbè kó rì.
Àwọn òṣìṣẹ́ tó ń dóòlà àwọn ènìyàn lórí òkun Mediterranean sáré wọ aṣọ ààbò wọn, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní dóòlà àwọn ènìyàn náà lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan.
Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin náà, tí ọ̀pọ̀ wọn jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè The Gambia, ló ti wà lórí omi fún wákàtí mẹ́ẹ̀dógún tí wọ́n sì ti rin ìrìn máìlì 54 láti ìlú Castelverde lẹ́bàá Tripoli ní orílẹ̀ èdè Libya.
Àwọn kan nínú sọ fún BBC pé ìjà ti fẹ́ wáyé nínú ọkọ̀ ojú omi tí àwọn wà kí wọ́n tó wá dóòlà àwọn nítorí àwọn kan ṣì fẹ́ tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò náà pẹ̀lú bí ọkọ̀ tí àwọn wà nínú rẹ̀ ṣe wà ní bèbè pé ó fẹ́ rì tí àwọn mìíràn sì fẹ́ padà sílé.
Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn yìí ni kò sí oúnjẹ tàbí omi lọ́wọ́ wọn, tí wọn ò sì le wẹ odò àyàfi túùbù táyà ọkọ̀ tí àwọn kan mú dání láti fi dóòlà ẹ̀mí ara wọn tí ọ̀rọ̀ bá di nnkan míì, tí wọ́n bá bá ara wọn nínú omi.

Ọ̀kan nínú àwọn ọmọkùnrin náà sọ pé nígbà tí wọ́n ti wá dóòlà àwọn ni ọkàn tí balẹ̀ pé òun ti wọ Yúróòpù.
Àwọn tó lọ dóòlà àwọn ọ̀dọ́ yìí sọ fún àwọn aláṣẹ Italy tí wọ́n sì ní kí wọ́n máa kó wọn lọ ibùdó ti ìlú Bari lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí òfin tuntun orílẹ̀ èdè náà tó ní kété tí wọ́n bá ti ṣe àwárí àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n máa kó wọn lọ sí ibùdó dípò tí wọ́n máa wá àwọn ọkọ̀ ojú omi mìíràn tó tún wà nínú ìṣòro kiri.
Ọjọ́ mẹ́ta ni wọ́n máa lò láti fi dé ìlú Bari.
Bí ìrìnàjò náà ṣe ń tẹ̀síwájú ni àwọn ọ̀dọ́ náà sọ wí pé àwọn mọ̀ nípa ewu tí àwọn máa kojú àti pé ìgbà àkọ́kọ́ àwọn kọ́ nìyí láti wọ Yúróòpù lọ́nà yìí.
Àwọn kan ní orí ló yọ àwọn lọ́wọ́ ikú nígbà tí àwọn kọ́kọ́ gbèrò ìrìnàjò náà tí wọ́n sì dá àwọn padà sí Libya nígbà tí orí kó àwọn yọ tán.
"Ìgbà keje rèé tí mò ń gbìyànjú láti wọ Yúróòpù." ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún kan sọ fún BBC.
Gbogbo àwọn arìnrìn-àjò yìí ló ní ọ̀rẹ́ tó ti pàdánù ẹ̀mí wọn sínú irú ìrìnàjò yìí. Ọ̀pọ̀ wọn ló mọ̀ nípa ọkọ̀ ojú omi Greek níbi tí ìgbàgbọ́ wà pé ènìyàn tó kú nínú rẹ̀ tó 750.
Ní Libya náà ni ọkọ̀ ojú omi náà ti gbéra nígbà náà.
Ọ̀kan nínú wọn sọ pe òun kò jẹ́ kí ìròyìn náà da omi tútù sí òun lọ́kàn tàbí yí ìpinnu òun padà nítorí èrò tó wà lórí òun ló máa wà lórí àwọn onítọ̀hún.

Ó ní òun ti pinnu pé ó ṣeéṣe kí òun dé Yúróòpù tàbí kí òun pàdánù ẹ̀mí òun sínú òkun náà.
Ìdá ọgọ́rin nínú àwọn tó nínú ọkọ̀ náà ló jẹ́ ọmọdé tí ọjọ́ orí wọn kò ì tíì pé ọdún méjìdínlógún tí wọ́n ti kúrò nílé láti ọjọ́ pípẹ́ láti fi wá iṣẹ́ lọ kí wọ́n le máa fi owó ránṣẹ́ sílé.
Púpọ̀ nínú ló sọ wí pé àwọn tí pàdánù àwọn òbí àwọn àti pé gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí àwọn nílò láti ran àwọn àbúrò àwọn lọ́wọ́.
Ọ̀pọ̀ wọn ló jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Gambia, ọ̀kan nínú àwọn orílẹ̀ èdè tó tálákà jù ní àgbáyé.
Àjọ International Organisation for Migration (IOM) ní orílẹ̀ èdè Gambia ní àwọn ènìyàn ti sá kúrò jùlọ lẹ́nu ọdún díẹ̀ sẹ́yìn.
Nígbà tí ọkàn àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin náà tí balẹ̀ pé àwọn ti mórílé Yúróòpù, wọ́n ṣàlàyé pé àwọn onírúurú ọ̀nà ni àwọn gbà dé Libya nípa títẹ̀lé àwọn onífàyàwọ́.
Wọ́n ṣàlàyé pé ilé àwọn onífàyàwọ́ yìí ni àwọn ń ṣe gbé ní Libya láti wá owó tí àwọn fi ṣe ìrìnàjò yìí èyí tó ná wọn tó 3,500 dinars Libya.
Àwọn mìíràn ní àwọn lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù ní àhámọ́ ní Libya nígbà tí wọ́n ká wọn pé wọ́n fẹ́ gba orí omi lọ sí Yúróòpù.
Suma, ẹni ọdún méjìdínlógún ní ohun tí wọ́n sọ fún òun ni pé kò ní ju àádọ́ta sí ọgọ́ta ènìyàn tó máa wà nínú ọkọ̀ ojú omi àwọn àmọ́ irọ́ ni nítorí àwọn tí àwọn padà wọ ọkọ̀ náà lé ní ọgọ́rin.
Adama ní tirẹ̀ sọ pé òun ti wọ ọkọ̀ ojú omi tó rì rí àmọ́ òun wà lára ènìyàn 94 tó móríbọ́ nínú ìjàm̀bá náà.
Àwọn mìíràn ní àwọn mọ̀ pé kò sí bí àwọn ṣe lè dé Yúróòpù lọ́wọ́ ara àwọn àmọ́ àwọn ní ìgbàgbọ́ pé wọ́n máa dóòlà àwọn.

Àwọn lámèyítọ́ ní ìgbésẹ̀ láti máa dóòlà àwọn ènìyàn yìí yóò túnbọ̀ máa jẹ́ kí àwọn arìnrìn-àjò náà fẹ́ máa wọ Yúróòpù lọ́nà àìtọ́.
Agbẹnusọ àjọ náà ní bí àwọn kò bá dìde ìrànwọ́ síbẹ̀ àwọn ènìyàn náà kò ní dáwọ́ ìgbésẹ̀ wọn dúró.
Gẹ́gẹ́ bí àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé ṣe sọ, àwọn ènìyàn 64,000 ló ti wọ Italy gba orí omi Mediterranean ní ọdún yìí nìkan.
Àwọn ọ̀dọ́ náà ní àwọn rí Yúróòpù bí ibi tí wọ́n ti lè rí ìgbé ayé tó rọrùn, padà sí ilé ẹ̀kọ́ àti rí iṣẹ́ gidi.
Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló ní àwọn fẹ́ dàbí agbábọ́ọ̀lù bíi Ronaldo, Marcus Rashford àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Àmọ́ ohun tó wà níwájú àwọn ọ̀dọ́ yìí ni wọn kò mọ̀.
Nígbà tí wọ́n balẹ̀ sí Bari, oníkálùkù wọn gbe ẹrù wọn láti nà án sí àwọn òṣìṣẹ́ aṣọ́bodè tó wà ní ibùdó náà.
Sara Mancinelli, tó jẹ́ alákòóso Red Cross ní nígbà tí wọ́n bá ṣe àyẹ̀wò wọn tán ni wọ́n máa mọ àwọn tó lè dúró ní orílẹ̀ èdè Italy.
Chiara Cardoletti, aṣojú àjọ UN fún àwọn aṣàtìpó ní Italy ní látàrí bí àwọn ènìyàn ṣe ń wọ orílẹ̀ èdè náà, ó ṣeéṣe kí wọ́n má le gba gbogbo wọn dúró.












