GWR gbọ́dọ̀ fún 'Àgbákò' ní àmì ẹ̀yẹ òṣèré tíátà tó dàgbà jùlọ -Muyiwa Ademola

Aworan gbajumọ osere tiata, Agbako

Oríṣun àwòrán, Muyiwaauthentic/instagram/others

Gbajugbaja oṣere tiata, Muyiwa Ademola ti ke si ajọ ami ẹyẹ Guinness World Record lati fun agba osere Charlse Olumo ni ami ẹyẹ gẹgẹ bi osere to dagba ju, ti ara rẹ ji pepe ni ẹni ọgọrun ọdun.

Eyi wa lara ọrọ ikini ku ọjọ ibi ọgọrun ọdun ti Muyiwa Ademola fi si oju opo ayelujara rẹ lati fi ki eekan ere tiata Yoruba ti ọpọ mọ si Agbako.

Muyiwa Authentic, ni bi eekan osere tiata naa ṣi je n ta kebekebe lẹni ọgọrun ọdun to eyi ti o yẹ ki ajọ afun ni laami ẹyẹ, Guiness World Records (GWR) yẹ ko boju wo fun ami ẹyẹ.

Muyiwa Ademọla ni ko buru o ti baba Agbako ba gba ami ẹyẹ gẹgẹbi oṣere tiata to dagba julọ lorilẹede NAijiria bayii.

Amọṣa, ko si ẹni lee sọ o boya ajọ GWR maa n gbe iru ami ẹyẹ bẹẹ kalẹ.

" Laisi aniani, O da mi loju pe Baba ni osere tiata to dagba julọ bayii loke erupẹ ni Naijiria , to si tun ji pepe ni ẹni ọgọrun ọdun.

"@guinnessworldrecords, a n reti iwe ẹri lati ọdọ yin o, ko wulẹ nilo ka kọ lẹta si yin mọ.

"A ki yin ku ọjọ ibi lẹẹkansi Baba Charly Agbako, ninu ayo ati ilera to pe ye."

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Gbajugbaja agba oṣere, Charles Olumo ti ọpọ mọ si Agbako ni iroyin n gbe e pe o ti pe ẹni Ọgọrun ọdun loke erupẹ bayii.