Tí oò bá lè ran àwọn àgbà òṣèré tó ń tọrọ fún ìrànwọ́ lọ́wọ́, jẹ́ kí wọn ó mí! – Yomi Fabiyi

Yomi Fabiyi

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Gbajugbaja oṣere fiimu Yoruba, Yomi Fabiyi naa ti jade lati sọrọ nipa bi awọn agba oṣere kan ṣe n bọ sori ayelujara lati pariwo fun iranwọ lọwọ awọn ẹlẹyinju aanu.

Yomi n sọrọ gẹgẹ bi esi si fidio kan ti agba oṣerebinrin, Jaiye Kuti fi sita ninu eyi to ti n bu ẹnu atẹ lu bi o ṣe ni awọn oṣere kan ti sọ ara wọn di alagbe.

Yomi Fabiyi bu ẹnu atẹ lu iwoye wipe awọn to n tọrọ fun iranlọwọ n doju ti awọn oṣere toku ni.

Bo tilẹ jẹ pe ko darukọ tabi na ika ọrọ rẹ si Jaiye Kuti, Yomi Fabiyi ni ko tọ ki ẹnikẹni bu wọn pe wọn n bọ si gbangba lati bẹbẹ fun iranlọwọ lasiko iṣoro wọn.

“Gbogbo awọn iṣẹ to ku loriṣiriṣi ẹka lo wa labẹ asia ẹgbẹ kan tabi omiran nitori idi eyi, ipenija ilera wọn n ri amojuto. Bẹẹ si ni akanṣe eto adojutofo wa fun owo ifẹyinti ati ilera wọn.”

Yomi jẹ ko di mimọ pe ọpọlọpọ awọn agba oṣere yii ti wọn ni ẹbun ere ṣiṣe ni wọn ti yanjẹ gidi gan lori itage ti wọn si ti lo atawọn ati oogun wọn laarin agbo tiata ati nita ti ko si si ẹni to ba wọn wa ojutuu sii paapaa ni ti ọrọ jiji iṣẹ oniṣẹ tabi wiwo fiimu wọn lọna aitọ.

Fabiyi sọko ọrọ sawọn oṣere to n fi make up yi ọmọde si agba ninu fiimu

“Ibanujẹ lo tun wa jẹ wipe awọn oṣere aye ode oni ti n pa wọn ti, dipo ki wọn maa lo awọn agbalagba yii fun fiimu ki wọn le maa ri owo, wọn a kun oju awọn ọdọ lati jẹ ki wọn jọ arugbo.”

Ṣaaju ni Jaiye Kuti ti sọ ninu fidio to fi si oju opo Instagram rẹ pe iwa ti awọn to n bẹbẹ fun iranwọ yii n hu n tabuku ba ẹgbẹ apapọ awọn oṣere (TAMPAN) atawọn ọmọ ẹgbẹ.

“ A ni ẹka ti awọn to n ṣe fiimu lede Gẹẹsi ati ti Yoruba to si jẹ pe awọn ti elede Gẹẹsi naa n doju kọ iṣoro amọ wọn a lọ bere fun iranwọ laarin ara wọn. Awọn ọmọ ẹgbẹ ti wa n mu itiju ba wa bi wọn ṣe lọ n tọrọ titi doju pe ọpọlọpọ wa n ri awọn oṣere fiimu Yoruba bii awọn to kuṣẹ nitori pe awọn kan o ṣe eto silẹ fun ọjọ ọla wọn.”

Yomi Fabiyi tun fesi wipe bi ẹ ba wo awọn to n bu nu atẹ lu awọn to lahun fun iranwọ yii daadaa, ṣe ni wọn maa n fi owo igunkọmu gun wọn lọwọ bi wọn ba pe wọn fun fiimu.

O wa rọ awọn oṣere wipe bi wọn rii pe wọn nilo iranwọ, ki wọn bere fun un.

O sọ apẹrẹ oloogbe oṣere apanilẹrin, Baba Suwe bo ṣe jade toripe o nilo iranlọwọ lootọ to si ju agbara rẹ lọ.

Atẹjade Yomi Fabiyi

Oríṣun àwòrán, Yomi Fabiyi/Instagram

Jaiye Kuti tutọ́ sókè, ó f'ojú gbàá lórí bí àwọn òṣèré ṣe n tọrọ bárà lórí ayélujára

Jaiye Kuti

Oríṣun àwòrán, JAYEOLA_MONJE/ INSTAGRAM

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gbajumọ oṣerebinrin, Jaiyeola Kuti, ti sọrọ lori bi awọn akẹẹgbẹ rẹ kan ninu iṣẹ tiata ṣe di ‘onibara’ ọsan gangan lori ayelujara.

Ninu fidio kan ti Arabinrin Kuti fi si ori ayelujara Instagram rẹ lo ti ni o jẹ nnkan to jẹ itiju ati ibaniloju jẹ pe awọn oṣere kan ti sọ ara wọn di alagbe

Oṣere naa ni lootọ ni awọn eeyan kan ti kilọ fun oun lati má sọ ohunkohun nipa ihuwasi awọn osṣere naa, o ni ṣugbọn otitọ ọrọ to gbọdọ jẹ́ sisọ ni.

O ni ko bojumu bi awọn oṣere Yoruba kan ṣe ma n reti pe awọn akẹẹgbẹ wọn ni ko tọju wọn ti wọn ba n ṣaisan tabi wa ninu iṣoro.

O ni ihuwasi awọn to n ṣe bẹẹ dabi igba ti wọn n bu Ọlọrun pe iṣẹ oṣere ko ni laari, nigba to jẹ pe ọpọ awọn to n ṣe bẹẹ lo n fi owo ko obinrin jọ tabi ṣe apọju faaji.

O ni awọn oṣere Yoruba kan ti sọ iwa naa di nnkan to n ba ẹka ere Yoruba ni orukọ jẹ, ti awọn eeyan si ti n kan awọn ni abuku nibikibi ti awọn ba de.

Awọn kan lara wa, ọti mimu ati obinrin ni wọn n fi owo iṣẹ tiata wọn ko jọ nigba ti wọn wa ni ọdọ, ti wọn a si pada wa si ori ayelujara lati wa ma a sọ pe iṣẹ naa ko lere nitori ki awọn eeyan le ran wọn lọwọ.

“Ẹlomii ko tọju ọmọ rara tabi hu iwa ti wọn fi le ni ọla.”

Kuti sọ pe ojuṣe awọn oṣere kọ ni lati ma a tọju awọn akẹẹgbẹ wọn to ba darugbo.

O ni nnkan to han ni pe iṣẹ tiata ko ni owo ifẹhinti, eyi to yẹki kaluku ma a pọn omi silẹ dohungbẹ nipa fifi owo pamọ fun ifẹhinti.

“Lootọ ni awọn aisan nla kan ma n wa to nilo iranlọwọ ẹlomii, amọ kii ṣe bi ki awọn oṣere ma a tọrọ owo lati jẹun.”

O ni ẹni ti ko ba ti ṣe nnkan to yẹ ko ṣe nigba ọdọ, ko gbọdọ jade ni ọjọ iwaju lati ma a ba awọn oṣere ẹgbẹ rẹ lorukọ jẹ.

“A wa oniwasu, ta a wa fẹ sọ ara wa di ẹni yẹyẹ.”

Arabinrin Kuti gba awọn akẹẹgbẹ rẹ ni imọran lati ma a fi owo pamọ ni oṣooṣu fun ifẹhinti, ki wọn si tọju awọn ọmọ wọn ki wọn le tọju wọn lọjọ iwaju.

O ni awọn oṣere ọkunrin mii, iwa agbere ni wọn n fi owo iṣẹ wọn ṣe.

O ni ika, to fẹ ba ọ̀la awọn oṣere yooku jẹ́ ni awọn to n tọrọ bara lori ayelujara.

Ọrọ ti osẹre yii sọ n waye lasiko ti awọn oṣere kan n bẹ̀bẹ̀ fun ile ati ọkọ̀ ayọkẹlẹ lori ayelujara.

Lati bi oṣu Kẹfaa, ọdun 2023 si asiko yii, ko din ni oṣere tiata Yoruba marun-un to ti tọrọ dukia lọwọ awọn ọmọ Naijiria.

Eyi to mu ki awọn ololufẹ wọn ati afẹnifẹre da owo jọ lati ra a fun wọn.

Kii ṣe Arabinrin Jaiye Kuti ni yoo kọkọ pariwo sita lori bi awọn oṣere kan ṣe n tọrọ fun iranlọwọ lori ayelujara.

Toyin Adegbola

Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pẹlu BBC Yoruba, agba osẹre, Toyin Adegbola, ti ọpọ mọ si Ajoke Asewo to re Mecca, foju abuku wo asa kawọn onitiata maa tọrọ owo lasiko aisan.

Nigba to n tara poro lori asa to gbode kan, nibi ti wọn ti maa n tọrọ owo fawọn osere tiata to ba n saisan, Adegbola ni eyi ko bojumu rara.

Gbajumọ osere naa wa woye pe se lo yẹ kawọn osere tiata se ọmọ ti wọn ba bi ni iwọn eku ni iwọn itẹ, ki wọn ma si da omi ju iyẹfun lọ.

"Asilo anfaani lọdọ araalu ni ki osere tiata maa tọrọ owo lọwọ wọn"

O woye pe bi eeyan ko ba tọju ọmọ lasiko to wa ni opepe, tabi to bimọ ju eyi ti agbara rẹ le tọju lọ, awọn ọmọ naa le ma yege lati tọju onitọun lọjọ alẹ.

Bakan naa lo gba awọn osere tiata lọkunrin nimọran pe ki wọn yee fẹ ọpọ iyawo lasiko ti okiki wọn ba n tan, nitori alaafia wọn lọjọ alẹ.

Adegbola wa woye pe asa ki awọn osere tiata maa bọ sori ayelujara lati tọrọ owo lasiko ti aisan ba de lọjọ alẹ lọwọ awọn ololufẹ wọn kii se iwa to bojumu.

O ni gbogbo eeyan lo ni ohun to n la kọja, bi igba ti eeyan si n si anfaani to ni lo ni, tawọn onitiata to n saisan ba n tọrọ owo lọwọ awọn ololufẹ wọn.