Mo fẹ́ fi ọdún ìṣẹ̀ṣe dúpẹ́ ni àmọ́ wọ́n ni àwọn yóò pa mí nílùú Ilorin
Laipẹ yii ni ariwo sọ lori ayelujara nipa iroyin kan to ni obinrin ẹlẹsin ibilẹ kan fẹ ẹ ṣe ọdun iṣẹṣe niluu Ilorin, nipinlẹ Kwara.
Iroyin naa to bẹrẹ si ni tàn kiri ni ọjọ diẹ sẹyin ní obinrin naa, Yeye Olokun Ajesekemi Omolara, fi iwe ipe si ori ayelujara Facebook lati pe awọn eniyan sibi ọdun to fẹ ẹ sẹ.
Ni kete ti iwe ipe naa jade sita, ni awọn eeyan kan to jẹ ẹlẹsin Islam ti koro oju si i.
Eyi ko ṣẹyin bo ṣe jẹ pe ẹlẹsin Islam lo pọ ju ni ilu Ilorin, ti ọpọ si gbagbọ pe ẹsin ibilẹ ko gbọdọ fi iga gbaga pẹlu rẹ.
Iroyin naa di ariwo pupọ, paapaa bi iya oloriṣa naa ṣe fi ẹsun kàn pe awọn ẹlẹsin musulumi kan n dunkooko lati pa oun ti oun ba fi le ṣe ọdun naa.
Eyi lo mu ki BBC Yoruba gbera lọ si Ilorin lati fi ọrọ wa gbogbo awọn ti ọ̀rọ̀ naa kan lẹnu wo.
Ajọdun idupẹ ni ọdun ti mo fẹ ẹ ṣe
Yeye Olokun Ajesekemi Omolara sọ pe oun kan fẹ fi ọdun iṣẹẹṣe naa ṣe ajọdun lati dupẹ pe lọwọ awọn Irunmọlẹ pe oun ko ri wahala kankan lati igba ti oun ti n ṣe iṣẹ.
Yeye Ajesekemi ṣalaye pe oun gbagbọpe aigbọra ẹni ye lo fa bi awọn ẹlẹsin Islam ṣe ro pe oun fẹ fi ọdun naa tako ẹsin wọn niluu Ilorin ni.
O ni iwe ipe ti oun ṣe wà fun oun ati awọn eeyan oun ni, amọ iyalẹnu lo jẹ nigba ti oun ri i lori ayelujara, ti awọn eeyan kan si ti bẹrẹ si ni dunkooko mọ oun pe iru nnkan bayii ko gbọdọ ṣẹlẹ niluu Ilorin.
O ni awọn ẹlẹsin Islam to wa si ile oun dunkooko mọ ẹmi oun.
O ṣalaye pe ọdun kẹta ti oun ti n ṣe ọdun iṣẹẹṣe ni yii, ti oun kii si kọja agbala ile oun tabi fi di ẹlẹsin miran lọwọ.
“Mo mọ pe ilu Ilorin kii ṣe ibi ti wọn ti n ṣe ọdun iṣẹẹṣe, emi naa kii si kọja aye mi.”
Ao sọ pe a fẹ ẹ pa obinrin naa, a kan kilọ fun ni
Aṣoju ẹgbẹ awọn Alfa nipinlẹ Kwara, alhaji Yusuf Pakata sọ fun BBC pe lilọ ti awọn lọ si ọdọ iya oriṣa naa kii ṣe lati dunkooko mọ tabi fa wahala pẹlu rẹ.
O ni awọn tẹle awọn ọdọ adugbo lọ si ile rẹ lati pa ina wahala ti awọn ọdọ naa n gbero lati fà ni.
“Ni kete ti a gbọ iroyin pe obinrin naa n gbero lati ṣe ọdun iṣẹẹṣe, a ranṣẹ pe e ni aafin Mọgaji agbegbe rẹ. Nibi ti a ti n duro de e ni awọn ọdọ kan ti ya wa sibẹ. A si ṣe akiyesi pe awọn ọdọ naa ti pinnu lọkan wọn lati lọ da wahala silẹ nile obinrin naa. Iṣeeṣi wọn pe wọn le da nnkan ru lo mu wa tẹle wọn.
Alhaji Pakata sọ pe awọn ko fi igba kankan sọ pe awọn yoo pa obinrin naa.
Kinni ileeṣẹ ọlọpaa sọ lori wahala yii?
Ninu ọrọ tiẹ naa, agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Ajayi Okasanmi sọ fun BBC pe ko si ẹnikẹni to mu ẹsun wa si ileeṣẹ ọlọpaa pe ẹnikẹni n dunkooko mọ ẹmi oun.
O ṣalaye pe nnkan bayii ko yẹ ko fa wahala, nitori pe o wa ninu iwe ofin Naijiria pe eeyan le ṣe ẹsin to wu u, niwọn igba ti Naijiria kii ṣe orilẹ-ede ẹlẹsin kan ṣoṣo.





