Wole Soyinka sọ ìdí tó fi ni òun a fi màálù Fulani ṣe súyà fáwọn èèyàn abúlé
Títí di bí a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, èmi gan an kò mọ irú ẹni tí Wole Soyinka jẹ́- Ojọ̀gbọ́n Wole Soyinka
Wole Soyinka: ìyàtọ̀ gedegbe wà láàrin ẹgbẹ́ Pirate Confraternity táwa dá sílẹ̀ lọ́dún 1952 àti ǹkan áwọn ọmọ ayé òde òní ń ṣe.
Apeja orukọ rẹ ni Akinwande Oluwole Babatunde Soyinka ṣugbọn ti gbogbo agbaye m si Wole Soyinka. Onkọwe, olukọ ewi ati olukọ arosọ.

Koda awọn oyinbo nla nla lẹ le fi mọ awọn aṣeyọri wọn ati ọpọlọpọ oye ti o ti gba laye - iyẹn ni pe lowe lowe la n lu ilu agidigbo...
'Màálù tó bá tàsẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ níwájú ilé mi, ó dẹran àsun!"
"Titi di bi mo ṣe n sọrọ yii emi funra mi o mọ ọ gidi, ẹni ti Wole Soyinka jẹ" lèsì Ọjọgbọn fun BBC Yoruba nigba ti a ni ki o juwe ara rẹ.
- Wole Soyinka rèé láti kékeré
- Soyinka: Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ayédèrú ìròyìn ti pa mí
- Caterpillar ni ọ̀rẹ́ mi, kò fún mi láàyè láti máa jáde- Rachel ọ̀dọ́mọbìnrin tó n wa ọkọ̀ kólẹ̀kòdọ́tìí
- N kò le è dìbò yan Buhari tàbí Atiku ní olórí mi láéláé - Soyinka
- Mo ti ṣe Bíríkìlà, Apọnmita àti òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ búrẹ̀dí rí kí n lè rówó ra 'Boot'- Taiwo Awoniyi
- ‘Àwọn asèbàjẹ́ gbọ́dọ̀ fi ẹ̀wọ̀n ju 'ra’
- Ajínígbé gba 5 million, páálí Mílíìkì, Malt àti páàlì sìgá méji ní Iwo kí wọ́n tó fi wà sílẹ̀- Pasítọ Omotoso C.A.C
Wole Soyinka ti a bi lọjọ kẹtala oṣu keje ọdun 1934 kii ṣe ọmọde mọ lonii ṣugbọn gbigba ami ẹyẹ gẹgẹ bi ọjọgbọn ko tii wọn lápó rẹ̀.
Nínú ìrìnàjò BBC Yorùbá sí ilé Ọ̀jọ̀gbọ́n Wole Soyinka nínú igbó kìjikìji tó múlé sí ni ilu Abeokuta tii ṣe ilu ibi rẹ gangan, omi pọ lamu ohun ti BBC Yoruba ba bọ.
- Wo àwọn ǹkan tí o kò mọ̀ nípa Ọba Lamidi Adeyẹmi, òṣìṣẹ́ adójútòfò àti Abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò tó wàjà
- Yorùbá kìí ṣe egúngún oníhòhò, ìwà wèrè ni sinimá oníhòhò táwọn òṣèré kan ń ṣe- Lere Paimo
- Igi ẹ̀fọ́, ojú ẹlẹ́gba àti oríṣi orúkọ̀ míì ní wọ́n ń pè mí nítorí pé Òbí mi kọlà sí ojú mi- Damilola
- ''Ìrìn wákàtí mẹ́fà la rìn nínú igbó kí ilẹ̀ tó sú bá wa, tí wọ́n sì di ọwọ́, dí ẹ̀sẹ̀ mí mọ́lẹ̀..''
Latẹnu ọna igbo ti ẹ o gba wọ ile baba lẹ o ti ro pe inu igbo irumọlẹ tẹẹ maa n ka ninu itan gan lẹ ti de yii ayafi bi ẹ ba wọle tan.
Ṣe latara awọn igi to wa labawọle igbo aginju ti ile rẹ wa ni ti awọn akọle awo bẹru wa.
Tabi awọn igbo kijikiji ati igi gogogro to yi ọgba ile ọjọgbọn ka.

- Èrò àwọn lọ́balọ́ba ní ìpínlẹ̀ Ogun ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí òfin tó dé sínsin òkú àwọn Ọ́ba tí ìjọba ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé jáde
- Pius Adesanmi: Awọn ọmọ Nàìjíríà ń ṣelédè lẹ́yìn akọni
- Adedibu ti mọ̀ pé ọ̀lọ́jọ́ ti dé lọ́jọ́ tó kú, ó ní àpò ẹ̀wà kàn ni ká fi dín àkàrà láì mọ̀ pé àkàrà òkú rẹ̀ ni - Bose Adedibu
- O ṣójú mí kóró bí wọ́n ṣé fí àdó olóró pa Dele Giwa lọdún 1986- Soyinka
- Wo ọkùnrin tó ń wọ àṣọ ìdámọ̀ Nàíjíríà lójoojúmọ́ láti wá ire orílẹ̀èdè yìí
Ọ̀rọ̀ ẹnu lásán ló fi pàṣẹ̀ àti ìkìlọ̀ fún màálù àtàwọn tó ń dà wọ̀n tó bá tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ wọn ò sì bí baba màálù kankan dáa.

Soyinka sọ ohun to difa fun akọle yii pe "igba ti awọn daran daran fẹ wa jọba le wa lori ninu ile ti mo kọ ni mo kọ akle naa mo si sọ fun baalẹ ati ọlọpaa agbegbe yii".
O ni oun dẹ sọ fun wọn pe maalu to ba wa lẹyin eleyii, ko fara mọ ohun toju ẹ ba ri. Tori naa mo ṣe kọ akọle sara igi pe, maalu to ba kọja aye rẹ o, aa sọ ọ di suya".
- Wo àbọ̀ ìwádìí BBC lórí ẹni ọdún 21 tó ‘mú iná mọ̀nàmọ́ná jáde lára òkúta’ ní ìpínlẹ̀ Ekiti
- Adedibu ti mọ̀ pé ọ̀lọ́jọ́ ti dé lọ́jọ́ tó kú, ó ní àpò ẹ̀wà kàn ni ká fi dín àkàrà láì mọ̀ pé àkàrà òkú rẹ̀ ni - Bose Adedibu
- Wo àǹfààní orin kíkọ àti ijó jíjó fún àwọn olóyún.
- Àwọn ikọ̀ tí Naijiria yóò kojú àtàwọn nǹkan tó yẹ kí o mọ̀
- Mọ̀ nípa ààrun tó le mú kí o máa ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ tí o bá n rìn láì mu ọtí yó
"Fraternity ní ìtàn tirẹ̀ ó dẹ̀ lápẹrẹ oríṣirísi ṣùgbọ́n ..."
Nipa itan ti ọpọlọpọ ma n sọ lori bi ẹgbẹ okunkun ṣe bẹrẹ lawọn ile iwe giga oni eyi ti wọ́n ma n lọ mọ ẹgbẹ "Pirate Fraternity" ti Wole Soyinka atawọn ọrẹ rẹ mẹfa kan da silẹ lọdun 1952.
Soyinka ni "ko yẹ keeyan tilẹ maa ronu lọ sibẹ rara tori ibanujẹ gbaa ni. Awọn ọmọ olowo, oniwakuwa, ti wọn o lẹkọọ lo da ẹgbẹ ti wọn ti wọn n pe ni "Fraternity".
Eyi lo ti wa di ẹgbẹ okunkun to n da awọn ile iwe giga ati igboro ru lode oni. Ọjọgbọn ni "àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn òde òní kàn ń ba orúkọ ẹgbẹ́ tí àwa dá sílẹ̀ ní 1952 jẹ́ ni".
Ayaworan: Samuel Agbaje

