Rachel Oluwole: Ọdún mẹ́fa ni mo wà tí Ìyá mi kú lẹ́yìn ìbímọ ṣùgbọ́n àìní kò jẹ́ kí n rówọ́ kàwé bó ti wù mí

Àkọlé fídíò, Rachel Oluwole: Ọdún mẹ́fa ni mo wà tí Ìyá mi kú lẹ́yìn ìbímọ ṣùgbọ́n àìní kò jẹ́ kí n rów

Rachel Oluwole: Ọdún mẹ́fa ni mo wà tí Ìyá mi kú lẹ́yìn ìbímọ ṣùgbọ́n àìní kò jẹ́ kí n rówọ́ kàwé bó ti wù mí.

Rachel Oluwole lo jẹ ọdọbinrin ẹni ogun ọdun to pa itiju ti to si lọ kọ iṣẹ awọn to n wa ọkọ nla ti wọn fi n kolẹko idọti ati awọn nkan mii.

O n i ọmọ ọdun mẹfa ni oun nigba ti oun padanu iya oun to ṣalaisi lẹyin to bi abikẹyin awọn.

Rachel sọ diẹ nipa awọn ipenija ti o ti dojukọ laye ko to ri owo lọ sile ẹkọ, ko to kọ idanwo aṣekagba ti ile ẹkọ girama WAEC.

Rachel Oluwole

Ogbeni Akinwumi Ogunola to jẹ ọga rẹ naa ṣapejuwe iru ọmọ ti Rachel jẹ pe o tẹpa mọ iṣẹ.

O jẹ akinkanju to tun ni ifarada.

O sọ iru awọn ọkọ nla ti Rachel le wa bii D6, D7. D8 ati Doxer.

Rachel gba awọn ọdọbinrin bii tirẹ ni iyanju lati maa ni suuru ati ifarada,.

O ni o wu oun lati lọ kawe sii nipa ẹkọ 'Mechanical engineering' lọjọ ọla ti oun ba ri iranlọwọ.

Rachel Oluwole