Òkúta méjì ni mo so wáyà mọ́ láti mú inà mọ̀nàmọ́ná jáde – Ayomide Oladeji

Àkọlé fídíò, Wo ọkùnrin tó mú iná mọnamọna jáde láti nínú àpáta

Ayomide Oladeji, ẹni ọdun mọkanlelogun, ni iroyin rẹ gba ori ayelujara pe o mu ina mọnamọna jade lati ninu okuta meji, to si jẹ ọpọlọpọ iyanlẹnu fun awọn eeyan.

Njẹ o ṣeeṣe lati mu ina jade lati ninu apata? Ileeṣẹ BBC Yoruba tẹ ọkọ leti lọ ilu Erijiyan nipinlẹ Ekiti, lati se abẹwo si ọkunrin oniṣẹ ara naa ati lati mọ bi o se mu ina mọnamọna jade lara okuta.

Ninu alaye rẹ, Oladeji ni oun ti maa n se atunse si awọn redio tẹlẹ ki oun to ri pe o ṣeeṣe lati mu ina jade ninu okuta meji, eyii to pe ni akọ okuta ati abo okuta.

O ni "Mo wa rọnu lọjọ kan pe bi ina se wa lara ẹja, o yẹ ki ina le jẹ yọ, ti awọn eeyan si fi foonu wọn bọ na."

"Lẹyin igba naa ti mo ri pe ina mọnamọna ni kudiẹ, ti awọn eeyan ko si ri owo ra Solar ni mọ wa ranti pe se bi mo le so okuta meji papọ, ti ina si jẹ yọ"

Ọrọ pọ ti Ayomide sọ, ṣugbọn a ni lati fidi rẹ mulẹ pe njẹ o ṣeeṣe nitootọ lati mu ina mọnamọna jade lati ara okuta.

Akọroyin BBC News Yoruba tun ba awọn Ọjọgbọn to mọ nipa Okuta sọrọ.

O nira lati gbagbọ - Ọjọgbọn Ademilua Oladimeji

Ojọbọn Ademilua Oladimeji, Ọnimọ nipa Okuta ni fasiti ipinlẹ Ekiti ni o sese, ko dẹ tun sese nitori gbogbo okuta to wa ninu ilẹ ni bi Ọlọrun se da wọn.

Oladimeji ni awọn okuta yii ni awọn ohun alumọni ti wọn ni ina mọnamọna lara sugbọn ina mọnamọna to wa lara wọn kere pupọ.

"O nira lati gbagbọ ohun ti ọmọ yii sọ."

ijọba ni lati se iwuri fun Ayomide- Onimọẹrọ Abayomi Temitope

Bakan naa ni Onimọẹrọ Abayomi Temitope, onimọ nipa ina mọnamọna, to jẹ olukọ ni fasiti Bamidele Olumilua to wa ni Ikere Ekiti tan imọlẹ si ọrọ naa.

O ni "Awọn nnkan wa ti mo ti ri to jọ mọ nnkan ti a ti ri ka , ti a dẹ ti ri gbọ ninu imọ ijinlẹ Sayẹnsi

"Nnkan temi n pe fun ni pe ki ijọba gbe yẹwo daada, ki wọn si tun gba Ayomide ni iyanju, ki wọn si se iwuri fun un."

Batiri ni o n tan, ki se Okuta rara- Ijoba Ipinlẹ Ekiti

A pari irinajo wa si ọfisi olubamọran pataki si gomina ipinlẹ Ekiti lori ọrọ ayika ati ina mọnamọna, Ọjọgbọn Mobolaju Aluko lati gbẹnusọ fun ijọba ipinlẹ Ekiti lori ọrọ ọhun.

"Igba ti a lọ si bé, eeyan mi to lọ sọ pe batiri ni ọkunrin naa tan, ki se okuta, ki emi gan to lọ sibẹ, mo mọ pe okuta ko le mu ina mọnamọna jade."

Ẹ wo fọnran yii lati mọ si nipa iwadi wa lori ọkunrin to okuta meji mu ina mọnamọna jade.