Kent Edunjobi: Àṣírí tó wà nínú orin Ebenezeri àti bí mo ṣe gba àmì ẹyẹ AMVCA rèé

Àkọlé fídíò, Kent Edunjobi ṣàlàyé bó ṣe máà ṣe é tó ń fi orin kó owó jádé lápò àwọn gbajúmọ̀ òṣèré, olóṣèlú?

O ti pẹ ti Hazzan Kehinde Daniel ti n ṣe akọsilẹ orin to si n gbe awo orin jade amọ ko tii ju ọjperete lọ ti o di gbajumọ lori ayelujara tori orin rẹ kan to ṣeeṣe ki ẹ maa gbọ lẹnu gbogbo eeyan bayii.

Ebenezeri ni akọle orin naa to si kan jẹ ọkan lara orin ajọdun ti awọn akọrin ijọ Celestial kan ni ipinlẹ Eko kọ.

Hazzan Kehinde ni ga awọn akọrin ijọ naa to si ṣalaye ninu ifọrọwanilẹnuwo yii pẹlu BBC Yoruba bi orin naa ṣe bẹrẹ gan.

"Ajọdun ni a n gbaradi fun ni ijọ wa ti awọn ọmọ ẹgbẹ akọrin mi si wa ba mi pe ṣe a o ni ni orin tuntun kankan ti a o kọ lọdun yii ni".

Kent ni oun ro o daadaa oun si wọle adura lọ si Ọlọrun. "Ọrọ kan ṣoṣo to kan n wa si mi lọkan ni Ebeniseri Ẹbeniseri".

Bẹẹ ni o ṣe mu gege to si kọ orin naa jade bi imisi rẹ ṣe n wa latọdọ Ọlọrun gẹgẹ bo ṣe se fun wa.

Kent Edunjobi tun ba BBC Yoruba sọrọ lori bi oun ati ẹgbẹ akọrin rẹ ṣe ti kọkọ ta orin Ebenezeri danu pe ki wọn ma gbe e jade ṣe di bii "okuta ti awọn ọmọle kọ silẹ to wa di pataki igun ile".

Bakan naa, Kent mu ẹnu ba oniruuru nnkan mii to ti n ṣe ko ti di pe o di gbajumọ pẹlu orin to kọ yii.

O ti maa n kọrin fun awọn gbajugbaja oṣere ninu fiimu wọn amọ ko fi bẹẹ si ẹni to mọ ọ lọ titi.

Kent ati O#sere fiimu Kunle Afolayan

Oríṣun àwòrán, Kent Media

Ẹwẹ, laipẹ yii lo gba ami ẹyẹ pataki ti AMVCA gẹgẹ bi ẹni to kọ orin to jẹ ogidi ju ni dun yii. Eyi waye tori orin to kọ ninu sinima Anikulapo ti ogbontagi oni fiimu, Kunle Afolayan gbe jade ti oun naa si gba ami ẹyẹ tori fiimu naa.