Ifá ti sọ̀rọ̀ lórí "subsidy" àti ìgbésẹ̀ ìjọba Naijiria

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Awọn ẹlẹsin ibilẹ nipinlẹ Osun ti gbe ẹsẹ IFA kan jade to sọrọ pe igbesẹ kan wa ti ijọba gbe ti yoo mu inira dani ni ibẹrẹ ṣugbọn itura ni yoo pada jẹ fun aaralu.

Dokita Oluseyi Atanda, ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu ileeṣẹ BBC News Yoruba ni IFA ti sọrọ, to si ki awọn alaṣẹ ni ikilọ pe ki wọn fi otitọ se gbogbo igbesẹ ti wọn ba gbe lasiko yii.

O tẹsiwaju pe IFA rọ awọn araalu lati ṣe suuru, ki wọn si ni aforiti fun gbogbo ohun to n waye lasiko yii nitori didun ni ọsan yoo so ni igbẹyin.

“Ifa ma n wo oye ni, Ifa ni igbesẹ kan wa ti awọn alasẹ gbe lasiko yii, Ifa ni oju ọna ni wọn wa.

“Ifa ni igbesẹ naa yoo mu inira lọwọ pupọ ṣugbọn awọn alaṣẹ ni lati ṣe e pẹlu otitọ, bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ.

“Ifa ni ti wọn ba se bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ pẹlu aforiti awọn araalu, Ifa ni ọti ati oyin ni yoo gbẹyin rẹ.”

Bakan ni Dokita ni ki awọn araalu wo awọn igbesẹ kan ti ijọba gbe to maa kọ wọn lominu ṣugbọn o ti dandan fun wọn lati ni iforiti.

O ni bi igbesẹ naa ṣe mu ibẹru ati ojo dani fun awọn araalu ni o ṣe ṣe koko fun ijọba lati ṣalaye ohun ti awọn araalu yoo jere nipa igbesẹ ti wọn gbe.