Bí Oọ̀ni ẹni ọdún 18 ṣe fún ara rẹ̀ lóyún tó sì bímọ

Oọ̀ni to bímọ

Oríṣun àwòrán, JOE WASILEWSKI

Awọn alaṣẹ ọgbà ẹranko ni Costa Rica ti tọka si ọ̀ọni kan to fun ara rẹ loyun.

Aṣiri tu lẹyin to bi ọmọ kan to fi ìdá 99.9% gbogbo 'gene' ara rẹ jọ ọ.

Iru nnkan bayii sábà wọpọ laarin awọn ẹyẹ, ẹja ati awọn ẹranko afàyàfà, àmọ́ kò sẹlẹ ri laarin awọn ọọ̀ni.

Àwọn onimọ sayẹnsi sọ pe o le jẹ ajogunba lati ara àwọn to pilẹ̀ ìran.

Oṣu Kini, ọdun 2018 ni abo ọọ̀ni kan to ti pe ọdun méjìdínlógún lati America, yé ẹyin naa ni ọgbà ẹranko Parque Reptilania.

Sugbọn abiku ni ọmọ to wa ninu ẹyin naa pada ja sí.

Ọdun meji ni ọọ̀ni naa wa nigba ti wọn gba a si ọgbà ẹranko naa, wọn si yàá si ọ̀tọ̀ ni gbogbo ọjọ́ aye rẹ.

O le jẹ́ 'Parthenogenesis'

Nitori pe ọọ̀ni naa dá wà ni, awọn onimọ sayẹnsi lọgba ẹranko naa ranṣẹ si ikọ kan to mọ nipa oyún wúńdíá, ni ile ẹ̀kọ́ giga Virginia Polytechnic.

Oyún wúńdíá ni wọn n pe ni parthenogenesis, ninu imọ sayẹnsi.

Wọ́n ṣe agbeyẹwo ọmọ ti oọ̀ni naa bí, wọn si ri pe ìdá 99.9% ni awọn eroja 'gene' ara rẹ fi jọ ti iya rẹ - eyi tumọ si pe ko ní bàbá.

Ninu akọsilẹ kan ninu Royal Society Journal Biology Letters, àwọn to ṣe iwadii naa sọ pe o ṣeéṣe kí oyun wundia ti máa waye laarin awọn oọ̀ni, lai si ẹni to mọ titi di asiko yii.

Lòótọ́ ni ko tii si ẹni to mọ ìdí ti oyun wúńdíá fi n waye laarin orisirisi ẹ̀dá, ṣugbọn ọ̀rọ̀ nipa rẹ n jẹyọ ninu awọn iwe imọ sayẹnsi.

Sugbọn ohun kan to daju ni pe o n sẹlẹ laarin awọn ẹ̀dá tí ìran wọn ti n tán l'ori ilẹ̀ ayé.