Bí Tinubu bá gbé “Palliative” silẹ̀, yóò dàrú bí ìgbà Covid-19 ni o! Ohun tó yẹ k’íjọba ṣe rèé – Onímọ̀ nípa ọrọ̀ ajé

Aarẹ Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Onimọ nipa ọrọ aje to tun jẹ Ọjọgbọn ni ẹka imọ ọrọ aje ni Fasiti ti ilu Eko, Hajia Jemilat ti ni ki ijọba apapọ lo ọgbọn inu lati fi pinu iru igbesẹ pato ti wọn fẹ gbe lati mu irọrun de ba araalu lasiko wahala owo iranwọ epo (subsidy) ti wọn yọ kuro.

Jemilat gẹgẹ bi onimọ nipa ọrọ aje jẹ ko di mimọ pe lootọ igbesẹ ti ijọba gbe yii dara pupọ amọ to ba jẹ pe wọn n gbero lati maa pin nnkan fun araalu lọlọkanojọkan, wọn ni lati ṣọra gidi.

“Iwa ajẹbanu kii jẹ ki awọn nnkan iranwọ (palliative) yii de ọdọ awọn to nilo rẹ gangan tori naa, wọn ni lati rii pe “palliative” yii de ọdọ awọn alaini to jẹ wipe owo iranwọ epo ti wọn yọ kuro n ni lara gangan”.

Ki ni awọn araalu nilo gangan bayii to yẹ ki ijọba gbe yẹwo?

Onimọ nipa ọrọ aje yananana awọn nnkan to ṣe pataki lara eyi to ni pataki ibẹ ni pe ki wọn ri ounjẹ jẹ ni irọrun.

Lara awọn ohun to la kalẹ gẹgẹ bi ohun tawọn araalu nilo ju ni Naijiria niyi:

Ki ina ijọba maa wa nigba gbogbo

Jemilat ṣalaye pe bi ina ijọba ba n wa nigba gbogbo, ko ni jẹ ki awọn araalu maa lọ to si ile epo lati maa ra opo ni gbogbo igba lati ṣiṣẹ wọn a si le ri iṣẹ wọn ṣe ni irọrun.

Ẹdinwo owo ọkọ

Onimọ nipa ọrọ aje naa ṣalaye pe dindin owo ọkọ ku yoo jẹ ki araalu to ba ni ọkọ le ma maa gbe ọkọ jade ni gbogbo igba tori yoo le wọ ọkọ ijọba to dinwo.

Bakan naa lo ni ẹdinwo owo ọkọ yii yoo mu ki ọwọngogo owo ounjẹ wa silẹ.

Idi rẹ ni pe o ni awọn ọlọja yoo le ri ọkọ ti owo rẹ ko gun ni lapa wọ lati fi ko awọn ọja wọn.

Bakan naa lo ni ki ijọba maa ṣe ipade pẹlu awọn awakọ tori owo ti wọn gbe sori ọkọ funra wọn ti pọju tori diẹ ni ọrọ owo epo jẹ ninu nnkan to n mu ọkọ ṣiṣẹ tori naa ki ijọba maa ṣepade pẹlu wọn ki wọn ma gbe owo ti yoo ni araalu lara le ọkọ.

Ki ijọba maa ba araalu sọrọ

Jemilat sọ pe eleyi ṣe pataki gidi gan ki ijba ni ọna ti wn yoo fi maa ba araalu sọrọ.

“Ni Naijiria, a nilo lati maa ba ara wa sọrọ. Ki ijọba maa ba araalu sọrọ, ṣalaye pe gbogbo nnkan to n ṣẹlẹ, kii ṣe pe ijọba fẹ fi ara ni araalu o ṣugbọn ki wọn ṣalaye bo ṣe jẹ gangan”.

A ó gbé ìgbésẹ̀ lórí pípèsè nǹkan ìrọ̀rùn fún aràálú torí “Subsidy” – Ìjọba àpapọ̀

Aarẹ Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Ahmed Tinubu ti paṣẹ fun igbimọ ijọba to n ri si ọrọ aje wipe ki wọn bẹrẹ igbesẹ lati ṣiṣẹ lori awọn nnkan irọrun fraalu lati lee mu ki idẹrun ba wọn lasiko ti wọn yọ owo iranwọ epo (subsidy) kuro yii.

Aarẹ tinubu ni ki igbakeji rẹ, Kashim Shettima dari igbimọ naa to si fun wọn ni ọgbọn ọjọ lati gbe igbesẹ naa.

Gomina ipinlẹ Ogun, dapo Abiodun to dari awọn aṣoju awọn eekan ọlọja epo bẹntiroo lọ ṣe ibẹwo si aarẹ nile ijọba to wa l’Abuja lo fidi ọrọ yii mulẹ fun awọn oniroyin lẹyin ipade wọn l’Ọjọru ọsẹ.

Abiodun sọ pe igbesẹ aarẹ Bola tinubu yii fihan gbangba wipe o ni ipinu ati igboya lati mu idrun de ba awọn ọmọ Naijiria pẹlu gbogbo nnkan ti wọn ti n foju wina fun ọpọlọpọ ọdun.

“Bo tilẹ jẹ pe yiyọ owo iranwọ epo kuro yoo mu inira wa diẹ, igbesẹ yii yoo pada wulo nitori tita riro la n kọ ila”.

Ṣaaju akoko yii, awọn ọmọ Naijiria ti n fi igbe sita lori bi yiyọ owo iranwọ epo ṣe n pa wọn lara ni oniruuru ọna koda ti awọn gomina ipinlẹ kan ti gbe igbesẹ lati ran awọn araalu lọwọ.

Bakan naa, lara awọn ọlọja epo bẹntiroo to lọ si ile aarẹ fi erongba wọn han lati pese nnkan bii aadọta si ọgọrun bọọsi ero to lee gbe eeyan aadọta lati le ran awọn araalu lọwọ amọ a o mọ idaniloju eyi tabi ilu ti wọn fẹ ko awọn bọọsi naa lọ.