Wo àwọn Ìpínlẹ̀ tó ti gbé igbésẹ̀ lórí ìgbáyégbádùn òṣìṣẹ́ lẹ́yìn ọ̀wọ́ngógó èpo

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bi ajọ NNPC ṣe kede afikun si owo iye epo bẹnitoo lorilẹede Naijiria ni inira ti de ba awọn araalu, ti pupọ si bẹrẹ si pariwo sita fun iranlọwọ, pe ki ijọba ṣaanu wọn lati mu nnkan dẹrun.
Ipe yii ni awọn gomina kan gbọ, ti wọn si kede pe awọn fẹ ṣe atunṣe si owo oṣu awọn oṣiṣẹ, eyi ti yoo mu nnkan dẹrun fun araalu naa.
Ṣaaju ni awọn Gomina meji otọọtọ lati ipinlẹ Ọyọ ati Kwara ti gbe igbesẹ lati mu ki aye dẹrun fun awọn oṣiṣẹ ijọba to n ke irora nitori ipinnu ijọba apapọ lori 'Subsidy'.
Awọn Ipinlẹ naa re
Ipinlẹ Oyo
L'ọjọ Aje ni Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde mẹnuba erongba rẹ lati ṣe atungbeyẹwo owo oṣu awọn oṣiṣẹ ijọba n'ipinlẹ naa lati mu adinku ba tita-riro to n ba wọn finra nipasẹ iyọkuro owo iranwọ ori epo bẹntiro.
Nipasẹ eleyii si ni Makinde fi ṣe ifilọlẹ igbimọ to ni ọwọ awọn aṣoju ẹgbẹ oṣiṣẹ ati aṣoju ijọba ninu.
Lara wọn ni; Alamojuto awọn oṣiṣẹ ijọba, awọn akọwe ẹka to n mojuto ọrọ oṣiṣẹ, onimọ iṣiro owo agba ati akọwe ẹka eto iṣuna.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Ipinlẹ Kwara
Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq kede wi pe ọjọ mẹta pere ni awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ naa yoo fi maa wa si ibi iṣẹ bayii, nitori ọwọngogo epo bẹntiro ati ipenija to n koju eto ọrọ aje.
Ọjọ mẹta pere ni awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ naa yoo fi maa ṣiṣẹ bayii dipo ọjọ marun un ti wọn fi n ṣiṣẹ tẹlẹri.
Ireti wa wi pe awọn alakoso oṣiṣẹ ijọba yoo ṣe agbekalẹ awọn ilana itọni lori ipa ti agbekalẹ naa yoo ko lori awọn oṣiṣẹ eto ilera ati awọn ti o jẹ olukọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Ipinlẹ Ogun
Bakan naa ni ipinlẹ Ogun, Gomina Dapo Abiodun kede pe oun ti ṣe ipade pọ pẹlu awọn ẹgbẹ osisẹ nipinlẹ lati jiroro lori ọna lati pese ohun iranwọ fun awọn osisẹ nipinlẹ, eyi ti yoo mu nnkan dẹrun fun wọn.
Gomina ni igbesẹ ijọba lati yọ owo iranwọ Subsidy ni yoo pada jẹ ohun ti tọmọde tagba yoo jẹ anfani rẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
Ipinlẹ Edo naa ti darapọ awọn ipinlẹ lorilẹede Naijiria ti wọn se ipade pọ pẹlu ẹgbẹ oṣisẹ lati jiroro lori ọna lati pese ohun iranwọ fun awọn osisẹ ijọba.
Awọn ipinlẹ ti wọn ko tii kede ohun kankan nipa bii wọn se fẹ pese iranwọ fun awọn osisẹ wọn ni ipinlẹ Eko, Ipinlẹ Ekiti, Ipinlẹ Osun, ipinlẹ Ondo ati bẹẹ bẹẹ lọ.