Tinubu, ríi pé o ṣe déédé nìdí yíyan àwọn ọgá ológun àti ipò míràn-CAN

Aworan aarẹ Tinubu ati ami idanimọ ẹgbẹ CAN

Ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi ni Naijiria,CAN ti kesi aarẹ Naijiria tuntun Bola Tinubu pe ki o woye nipa ṣiṣe deede pẹlu yiyan awọn eeyan ti yoo ba ṣiṣẹ sipo.

CAN sọ pe ko ri pe o fun awọn eeyan ẹya ati ẹsin oriṣi lanfaani lati sin ilu ni awọn ipo wọnyi.

Ọrọ naa ti aarẹ ẹgbẹ ọhun Archbishop Daniel Okoh fi sita sọ pe awọn ko ṣaimọ pe aarẹ Tinubu n bọ sori alefa lasiko ti gbogbo ẹka lorileede Naijiria n gbẹ oungbẹ fun atunto ati iyipada.

O ni awọn mọ pataki awọn iyansipo yi ni paapa lati le mu aabo ati igbayegbadun ba awọn ọmọ orileede Naijiria.

Labẹ eleyi, CAN rọ Tinubu pe ki o ṣe deede lori iyansipo awọn ọga ologun ati awọn olori ẹka ijọba mii to le mu ki ijọba rẹ fẹsẹrinlẹ.

CAN sọ pe awọn n reti ijọba ti yoo ṣe atunṣe awọn aiṣedeede ati aiṣe dọgba to waye tẹlẹ pẹlu igbagbọ pe ''Aarẹ Tinubu yoo lo anfaani iyansipo yi lati le mu ki ọkan awọn ọmọ Naijiria balẹ.''

CAN tẹsiwaju pe ki Tinubu yan awọn to kajuẹ si eyikeyi ipo ti wọn yoo ba di mu.

Ẹgbẹ CAN ati ''Muslim Muslim Ticket'' to gbe Tinubu wọle

Ṣaaju idibo aarẹ ọdun 2023, ẹgbẹ ọmọlẹyin Kriti wa lara awọn to fi ẹhonu han lori bi ẹgbẹ oṣelu APC ti ṣe yan musulumi ni oludije ipo aarẹ ati igbakeji aarẹ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Wn ni yiyan musulumi meji lati dije dupo yi ko fi ti awọn ẹlẹsin mii ti ṣe Kristẹni ṣe.

Ọrọ yi le ni igba naa debi pe awọn kan ninu ẹgbẹ oṣelu APC to jẹ ẹgbẹ Tinubu jade sita lati tako tikẹẹti Muslim-Muslim yi.

Amọ bayii ti Tinubu ati Shettima igbakeji rẹ ti wa wọle, atẹjade CAN yi tun jẹ bi anfaani lati rọ ijọba rẹ ko ṣe deede nibi iyansipo.

Ni Naijiria, oṣelu,ẹya ati ọrọ ẹsin jẹ nkan ti awọn araalu ko fi ṣere rara.

Ni paapa bi aarẹ tabi alaṣẹ mii bi Gomina yoo ba yan eeyan sipo ,wọn a maa wo ẹya ati ẹsin to fi mọ boya ẹni naa kajuẹ ko to di pe wọn yan onitọun sipo.

Labẹ ijọba to kogba wọle, ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi bẹnu atẹ lu bi aarẹ ti ṣe n ṣe oju ṣaaju nipa ẹya ati ẹsin.

Wọn tako aarẹ lọpọ igba nipa ọrọ aabo ti wọn lo mẹhẹ to si fi awọn ẹmi Kristẹni lapa kan Naijiria sinu ọpọ ewu.

Ofin Naijiria ko fi aaye kalẹ fun pe ki wọn wo ẹsin tabi ẹya ki aarẹ to yan eeyan sipo ṣugbọn o ni ki iṣedeede wa lati fi igbalaye kalẹ fun orisi eeyan to papọ lorileede Naijiria.

Aarẹ Tinubu ko ti kede awọn ti yoo jẹ ọga ileeṣẹ ologun ati awọn ipo miran mu ni Naijiria.

Oju awọn ọmọ Naijiria si wa lọna lati mọ boya yoo pin ipo naa lọna ti ikunsinu ko ni pọ pe o gbe lẹyin ẹya kan tabi ẹlẹsin kan ni Naijiria.