Ìpínlẹ̀ Oyo àti Kwara ṣètò láti mú nǹkan dẹ́rúnfún àwọn òṣìṣẹ́

Aworan

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

Lori ọrọ owo iranwọ ori epo 'Subsidy' ti ijọba apapọ wọgile, awọn Gomina meji otọọtọ lati ipinlẹ Ọyọ ati Kwara ti gbe igbesẹ lati mu ki aye dẹrun fun awọn oṣiṣẹ ijọba to n ke irora nitori ipinnu ijọba apapọ lori 'Subsidy'.

L'ọjọ Aje ni Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde mẹnuba erongba rẹ lati ṣe atungbeyẹwo owo oṣu awọn oṣiṣẹ ijọba n'ipinlẹ naa lati mu adinku ba tita-riro to n ba wọn finra nipasẹ iyọkuro owo iranwọ ori epo bẹntiro.

Nipasẹ eleyii si ni Makinde fi ṣe ifilọlẹ igbimọ to ni ọwọ awọn aṣoju ẹgbẹ oṣiṣẹ ati aṣoju ijọba ninu.

Lara wọn ni; Alamojuto awọn oṣiṣẹ ijọba, awọn akọwe ẹka to n mojuto ọrọ oṣiṣẹ, onimọ iṣiro owo agba ati akọwe ẹka eto iṣuna.

Ni igun ikeji, awọn aṣoju ẹgbẹ oṣiṣẹ wa lati inu ẹgbẹ; 'Nigeria Labor Congress' NLC, 'Nigeria Union of Teachers' NUT, 'Nigeria Union of Local Government Employees' NULGE, 'Nigeria Union of Pensioners' NUP, 'Joint Health Sector Union' JOHESU, 'Joint Negotiating Council' JNC, ati alaga ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ijọba agba.

Makinde fun igbimọ naa ni ọsẹ mẹjọ lati ṣe afihan abajade apero wọn pẹlu atungbeyẹwo owo oṣu oṣiṣẹ ti o kere ju.

O ni, "Ninu iṣejọba yii pẹlu gbogbo otitọ inu, a lero wi pe o ti to akoko lati gbe igbesẹ ki a si riidaju wi pe a ṣe ohun ti o tọ lori ohun to n bọ tabi ti o n ṣẹlẹ lati ọwọ ijọba apapọ. A ti mura silẹ fun un, a si le ṣe agbekale eto ti wa.

Bi ẹ ko ba gbagbe, mo ti sọ tẹlẹ wi pe ko si nnkan to di ipinlẹ Ọyọ lọwọ lati ma le san ju owo oṣu oṣiṣẹ ti o kere julọ ti ijọba apapọ n san ti a ba ri ọna gbee gba, mo si mọ wi pe a le ṣee ti a ba mu eto ọrọ aje wa gbooro sii.

A le san owo fun awọn oṣiṣẹ ipinlẹ Ọyọ ju ti ijọba apapọ lọ, a si ni agbara lati mu ọrọ aje wa gbooro lati riidaju pe ibaṣepọ to danmọran wa laarin awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ ati ijọba pẹlu ifojusun kan naa."

Ipinlẹ Kwara naa gbe igbesẹ ọtọ

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Saaju iroyin lati ipinlẹ Ọyọ ni Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq kede wi pe ọjọ mẹta pere ni awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ naa yoo fi maa wa si ibi iṣẹ bayii, nitori ọwọngogo epo bẹntiro ati ipenija to n koju eto ọrọ aje.

Ọjọ mẹta pere ni awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ naa yoo fi maa ṣiṣẹ bayii dipo ọjọ marun un ti wọn fi n ṣiṣẹ tẹlẹri.

Ireti wa wi pe awọn alakoso oṣiṣẹ ijọba yoo ṣe agbekalẹ awọn ilana itọni lori ipa ti agbekalẹ naa yoo ko lori awọn oṣiṣẹ eto ilera ati awọn ti o jẹ olukọ.

Ijọba ipinlẹ Kwara ti ni oun yoo tẹwọgba amọran lati ọwọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorii igbayegbadun ara ilu ati aleekun owo oṣu.

Lara awọn aṣoju ẹgbẹ oṣiṣẹ to wa nibi ipejọpọ ti ikede naa ti waye ni alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ labẹ aburada NLC, Muritala Olayinka, alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ TUC, Joseph Meshach, alaga ẹgbẹ awọn onimọ iṣegun Oyinbo, Ola Ahmad, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Muritala Olayinka ti o jẹ alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ labẹ aburada NLC sọ nibi ipade naa pe igbesẹ naa tọka bi Gomina ṣe jẹ adari rere si. O ni apero naa san ju iyanṣẹlodi lọ lasiko yii gẹgẹ bi o ṣe n parọwa si alaga igbimọ awọn Gomina orilẹede Naijiria lati da si ọrọ naa ki wọn si wa ojutu sii.

O parọwa si ijọba lati ṣe otitọ ninu gbogbo ijiroro to niṣe pẹlu owo oṣu oṣiṣẹ ti o kere ju ati ipesẹ iranwọ fun awọn eeyan ilu.