Àlàyé rèé tí a fi gbé owó gọbọi lórí iye owó jálá èpo bẹntiróò - NNPC

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Lọsẹ to kọja ni Ileeṣẹ epo bẹntiróò lorilẹede Naijiria, NNPC kede afikun owo epo bẹntiroo jakejade lorilẹede Naijiria.

NNPC fi sita ninu atẹjade ti wọn fi lede loju opo Twitter wọn lati kede iye owo tuntun ti wọn n ta epo bayii.

NNPC ni bi oju ọja ṣe ri bayii lo mu ki awọn ṣe afikun iye ti wọn n ta epo lasiko yii.

Bakan naa ni wọn fi alaye sita lori idi ti wọn gbe igbesẹ naa ati bi o ṣe ṣe koko pe ki awọn ọmọ orilẹede mọ nipa rẹ.

Ajọ ọhun ni lati ọdun 2022 ni ijọba ti san owo igunpa ori epo sọbusidi gbẹyin, ti NNPC si pinnu lati maa san owo nitori igbayegbadun awọn ọmọ orilẹede Naijiria.

Atẹjade ajọ NNPC

Oríṣun àwòrán, NNPC/Twitter

"Ijọba jẹ wa ni owo to to N2.8trn"

Alaye naa ni ijọba n jẹ Ajọ NNPC ni apapọ owo to to triliọnu meji ati ẹgbẹrun mẹjọ owo sọbusidi.

“Fun NNPC lati maa le pese epo, wọn fowo kun owo epo lati ri owo pese epo.”

Alaye naa tẹsiwaju pe yoo nira fun awọn ontaja epo bẹntiro lati ri owo ra epo ti wọn ba n taa ni iye to wa tẹlẹ.

“Ajọ NNPC ko lẹtọ lati ṣe agbekalẹ iye ti wọn ma ta jaala epo bẹntirol.

“Awọn ontaja epo ni yoo maa ta epo ni iye to ba wu wọn.

“Ayipada yoo maa de ba iye epo bi wọn ba n se ra epo naa, awọn miiran le taa ni owo bọọku ki wọn le ri onibara.”

Bakan naa ni alaye naa fihan pe ko ki n ṣe Ajọ NNPC nikan ni yoo ni anfani lati pese epo bẹntiroo ati pe ofin to wa bayi ni awọn ontaja ko gbọdọ gba ju ida ọgbọn lọ lori epo bẹntiroo.

NNPC ni ojuṣe ijọba ni lati rii pe gbogbo nnkan lọ bi o ṣe yẹ ko lọ.

Ajọ ọhun ni idasilẹ ileeṣẹ ifọpo Dangote Refinery yoo se ọpọlọpọ anfani bi epo bẹntiroo yoo ṣe pọ jaburata lorilẹde Naijiria.