Wo àwọn gbajúmọ̀ ọmọ Yorùbá tí ilé ẹjọ́ sọ sẹ́wọ̀n gbére tàbí dájọ́ ikú fún

Awọn ti ile ẹjọ ti daku iku fun

Oríṣun àwòrán, Collage

Ẹya Yoruba jẹ ẹya to maa n wa alaafia, to si korira iwa idaluru abi ọdaran ni gbogbo ọna.

Ọwọ yẹpẹrẹ si kọ ni Yoruba fi n mu agbega aṣa ati iṣe wa to da lori iwa ọmọluabi ati iwa rere ni awujọ.

Bí Yorùbá ṣe fi ọwọ́ pàtàkì mu ìwà ọmọlúàbí náà ni wọ́n máa ń dá sèríà tàbí fi ìyà tó tọ́ jẹ ẹnikẹ́ni tó bá lòdì sí àwọn ìwà yìí.

Nínú àkọ́jọ yìí, BBC News Yorùbá ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn gbajúmọ̀ ọmọ Yorùbá tí wọ́n ti dájọ́ ikú fún ẹ̀sùn kan tàbí òmíràn.

Ọ̀mọ̀wé Ramon Adedoyin

Ramon Adedoyin

Oríṣun àwòrán, Others

Ní ọgbọ̀n ọjọ́, oṣù Karùn-ún ọdún 2023 ni ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Osun tó fi ìjókòó sí ìlú Osogbo dájọ́ ikú fún Dókítà Ramon Adedoyin lórí ikú Timothy Adegoke.

Ilé ẹjọ́ ní Adedoyin jẹ̀bi ẹ̀sùn wí pé ó lọ́wọ́ nínú ikú Timothy Adegoke, tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ìpele kejì ní ilé ẹ̀kọ́ Obafemi Awolowo University, Ile Ife èyí tó wọ̀ sùn sí ilé ìtura rẹ̀ nínú oṣù kọkànlá ọdún 2021.

Nígbà tó ń gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀, Adájọ́ Adepele Ojo ní ilé ẹjọ́ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé lóòótọ́ ni Timothy Adegoke wọ̀ sínú ilé ìtura Hilton, tó sì san owó sí àsùwọ̀n ilé ìfowópamọ́sí olùjẹ́jọ́ kéje.

Adájọ́ Ojo ní Adedoyin jẹ̀bi ẹ̀sùn gbígbọ̀mọ̀ láti pànìyàn àti ẹ̀sùn ìpànìyàn.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ìdájọ́ ikú nípa yíyẹgi fún-un ni ilé ẹjọ́ dá fún Ramon Adedoyin.

Òun àti àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ mẹ́ta ni ilé ẹjọ́ dájọ́ ikú fún lórí ikú Timothy Adegoke.

Nínú oṣù Kọkànlá ọdún 2021 ni Ọ̀mọ̀wé Ramon Adedoyin àti àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ mẹ́fà mìíràn dèrò ilé éjọ́ lórí ẹ̀sùn méjìdílógún èyí tó ní í ṣe pẹ̀lú ìpànìyàn, ìgbìmọ̀pọ̀ láti ṣekúpani pẹ̀lú ìmùlẹ̀ àtàwọn ẹ̀sùn mìíràn.

Ramon Adedoyin ló ni ilé ìtura Hilton tí Timothy Adegoke kú sí.

Bákan náà ló jẹ́ olùdásílẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ Oduduwa University àti ilé ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe, The Polytechnic, Ile-Ife, ìpínlẹ̀ Osun.

Ní ọdún 2009 ló dá ilé ẹ̀kọ́ fásitì Oduduwa University, tó sì ti dá The Polytechnic sílẹ̀ láti ọdún 1984.

Ní ọjọ́ kìíní, oṣù kìíní ọdún 1957 ni wọ́n bí Ramon Adedoyin sí ìdílé Akui, Ile Ife.

Ní ilé Ife ló ti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama, tó sì tún lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Obafemi Awolowo University níbi tó ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nípa ìmọ̀ ìṣirò lọ́dún lọ́dún 1983.

Lẹ́yìn náà ló lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga Centurion International University níbi tó ti gboyè ipò kejì.

Ó tẹ̀síwájú láti gba oyè ọ̀mọ̀wé ní ilé ẹ̀kọ́ All Saints University School of Medicine, New York lọ́dún 1996.

Dr Isola Oyenusi:

Isola Oyenusi

Oríṣun àwòrán, Others

Laarin saa ọdun 1970s ni Ishola Oyenusi da omi alaafia ilẹ Yoruba ru, ti ọpọ ẹmi si ti ọwọ rẹ bọ.

Oyenusi ni adigunjale akọkọ nilẹ Naijiria, eyi to gbajumọ ni kete ta pari ogun abẹle tan.

Ogboju adigunjale naa ni oogun abẹnu gọngọ pupọ, to si maa n rẹrin pade awọn ọlọpaa ati Sọja lasiko to ba n ṣíṣẹ ibi naa lọwọ.

Ọta ìbọn kii ran Oyenusi, bẹẹ lo maa n poora lasiko tawọn agbofinro ba fẹ mu, kii si lọ si ode idigunjale lai gba ẹmi eeyan, koda, ọdaju adigunjale pọnbele ni.

Gẹgẹ bi Oyenusi ti salaye obinrin afẹsọna oun to nilo owo nigba naa lo sun oun de idi ole jija.

Lẹyin o rẹyìn, ọwọ ofin tẹ ẹ, ti wọn si fi ẹyin rẹ ti agba ni Ọjọru, ọjọ kẹjọ oṣù Kẹsan-an ọdun 1971 ni eti okun nilu Eko.

Samuel Taiwo Oredein

Samuel Taiwo Oderein

Oríṣun àwòrán, Others

Baba oloselu kan wa, to gbajumọ lorilẹ-ede Naijiria, oun si la ba maa pe ni afọbajẹ, oun gan ni baba isalẹ oselu.

Bi o ṣe jẹ ọga patapata nidi ọrọ oselu Naijiria, bẹẹ lo tun jẹ ọwọ ọtun Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ nigba naa.

Orukọ agba oloselu naa ni Samuel Taiwo Ọrẹdẹin, o si wa lara awọn eekan oloselu to da ẹgbẹ oselu Ọlọpẹ, Action Group silẹ pẹlu Awolọwọ, ẹgbẹ yii si lo fa olootu ijọba akọkọ silẹ lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria lọdun 1955.

Lara awọn sawawu baba naa ti wọn jọ jẹ eegun sonso tii pari ike lagbo oselu ninu ẹgbẹ ọlọpẹ nigba naa ni Abiọdun Akerele, Ade Akinsanya, J.O Adigun, S.O Shonibarẹ, Ayọ Akinsanya ati Ọlatunji Dosunmu.

Bi o tilẹ jẹ pe Ọrẹdẹin ko du ipo oselu kankan nigba naa sibẹ, o lagbara ju awọn to wa nipo asẹ lọ.

Ohun to ba si sọ ni abẹ ge nigba naa nitori oun ni akọwe aato ẹgbẹ Ọlọpẹ, to si ni asẹ lati ni ki awọn to wa nipo asẹ wa kawọ pọnyin ro ẹjọ, ti ohun ti wọn se ko ba dara.

Amọ isẹlẹ kan waye lọdun 1971 eyi to milẹ titi, eyi to sọ ile ọla Ọrẹdẹin di ahoro.

Iṣẹlẹ ọhun mu ki ọlọla ati ẹni ẹyẹ di ẹni abuku, o si yẹ kawọn ọdọ ati ewe iwoyi, to fi mọ awọn eeyan to n lo igba lọwọ lagbo oselu wa fi kọgbọn.

ọjọ nla ni ọjọ Kẹtala, osu Kẹrin, ọdun 1971 nigba ti isẹlẹ idigunjale alagbara kan waye lopopona Bacita nipinlẹ Kwara nigba tawọn agbebọn kọlu ọkọ banki Barclays, to ti di Union Bank bayii, eyi to gbe owo rin.

Ọlọpa meji ati osisẹ banki meji ni wọn wa ninu ọkọ tawọn ole yii kọlu, ti wọn si ṣa wọn lọgbẹ yannayanna. Eyi to mu ẹmi ọkan lọ laarin wọn.

Awọn adigunjale naa gbe apoti owo nla kan ninu ọkọ banki yii, eyi to kun fun ẹgbẹrun mẹtala pọun, owo nla si ni laye igba naa, Awolọwọ si ni minisita feto isuna laye igba naa.

Ọga agba fawọn ọlọpaa nigba ta n wi yii, Kam Salem Kiamssa paṣẹ pe ki wọn se awari awọn adigunjale to huwa laabi yii, ko si pẹ, ko jinna, lọwọ tẹ asaaju ikọ apamọlẹkunjaye ọhun, Felix Dumeh, ti gbogbo eeyan ilẹ Naijiria si n yọ pe akara tu sepo.

Felix Dumeh bẹrẹ si ka orukọ awọn eeyan jankajankan gẹgẹ bi baba isalẹ wọn to si darukọ Oloye Taiwo Ọrẹdẹin pe oun naa wa lara awọn igi lẹyin ọgba fun oun.

Oba Samuel Adeniran Asusumasaa

Ade

Oríṣun àwòrán, Others

Ọjọ nla ni ọjọ Kẹwaa, osu Kinni, ọdun 1949 nigba ti isẹlẹ nla kan waye nilu Efon Alaaye, to wa nipinlẹ Ekiti bayii

Ọmọdebinrin kan to n jẹ Adediwura Adejolu Ojo ọmọ Abaluo, tii se ọmọ ọdun kan ati osu mẹta, lo saadede poora ninu agbala baba rẹ to ti n sere ni adugbo Ilu gbeku.

Ere ni, awada ni, wọn wa ọmọ naa titi, ti ilẹ fi su, amọ wọn ko ri eegun tii jẹ Ajikẹ, iya Adediwura sunkun titi, oju ni oun ko ran-an nisẹ.

Baba rẹ naa atawọn ọrẹ pẹlu aladugbo gan an gbarata, wọn daamu, ikun imu ọtun wọn bọ si toi si, amọ ofuutu-fẹẹtẹ, aasa ti ko ni kahun ni gbogbo wahala rẹ.

Koda, wọn mu isẹlẹ naa to Ọba Alaaye tilu Efon Alaaye leti nigba ti aayan wọn lati wa ọmọ naa ni gbogbo arọko to sunmọ wọn ja si pabo.

Bakan naa, Ọba Samuel Adeniran Asusumasa Atewogboye keji, Alaaye tilu Efon Alaaye lasiko naa, tun gbe awọn gende dide lati wa Adediwura, sugbọn ẹja ni ọrọ naa, kii se akan rara.

Ọrọ yii ko lojutu titi di ọjọ Kẹwaa, osu Keji, ọdun 1949, iyẹn nigba to pe osu kan gbako ti Adediwura poora.

Ọjọ naa si ni awọn ikọ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ mẹrin, ti orukọ wọn n jẹ Insipẹkitọ Aruah, Sajẹnti Olawaiye ati Sule Agbabiaka pẹlu Kọburu Ariyo ya bo ilu Efon Alaaye lati finmu-finlẹ nipa ibi ti Adediwura wọlẹ si.

Laarin ọjọ meji pere, awọn ọlọpaa to dantọ naa fidi rẹ mulẹ pe awọn afọmọ setutu lo gbe ọmọde yii lọ.

Nigba ti yoo si fi di ọjọ Kẹrinla, osu Keji, ọdun 1949, okiki ọrọ naa ti gba ilu kan, tawọn iwe iroyin si ti kede rẹ, bẹẹ ni ijọba eebo tutọ soke, foju gbaa, lori isẹlẹ laabi naa.

Nigba ti iwadii wọn tẹsiwaju, paapaa lori awọn akinkanju oloogun to wa ninu ilu naa, ọwọ tẹ awọn Babalawo mẹta.

Orukọ awọn onisegun ọhun ni Daniel Ojo, Enoch Falayi ati Gabriel Olabinrinjo, Falayi si lo jẹ babalawo si Alaaye tilu Efon naa.

Nigba to di osu Kẹrin, ọdun 1949, igbimọ olugbẹjọ dide ni gbọngan Obokunbusi to wa nilu Ilesa, eyi ti adajọ Majisireti WO Egbuna ko sodi.

Ọrọ ko pariwo rara nigba ti ọkan lara awọn afurasi to wa ni ahamọ ọlọpaa lori isẹlẹ yii ka boroboro nipa ohun ti wọn se, ti ile fi jona.

Ọkan lara awọn ẹlẹrii ninu igbẹjọ yii ni Aina Ola, ẹni to fọwọ gbaya pe Falayi lo ji Adediwura gbe sabẹ agbada rẹ.

Bakan naa ni ọkan lara awọn ẹlẹrii tọka si Ọba Asusumasa Atewogboye pe, oun lo ran wọn nisẹ ipaniyan naa, ti wọn si lọ mu Ọba si atimọle lọgan.

Wọn gbe ẹjọ naa lọ sile ẹjọ giga tilu Akure labẹ adajọ NS Pollard, ti awọn ẹlẹrii mọkanlelogun si yọju siwaju rẹ.

Bakan naa ni iyawo babalawo yii, Owomobi jẹrii pe inu ile awọn ni ọmọde naa wa titi di aajin, ti ọkọ oun kan an nipa fun oun lati pọn ọmọ naa sẹyin lọ sile afurasi keji, Gabriel Olabirinjo.

Agbẹjọro fun Ọba Asusumasa Atewogboye ni Oloye Obafemi Awolowo nigba ti Bode Thomas jẹ agbẹjọro fun ikọ olujẹjọ yoku, tii se awọn babalawo.

Awọn mejeeji ja fitafita lati jẹ ki ẹjọ ọhun gbe awọn onibara wọn, amọ awọn ẹri to wa niwaju ile ẹjọ fihan pe ẹpa ko boro mọ.

Asẹyinwa-asẹyinbọ, ileẹjọ kede pe Kabiyesi Ọba Samuel Adeniran Asusumasa Atewogboye Keji, Alaaye kẹtalelogoji nilu Efon Alaaye ati babalawo rẹ, awọn iransẹ ati Gabriel Olabinrinjo jẹbi ẹsun ijọmọgbe ati ipaniyan.

Ileẹjọ ni ki wọn yẹgi fun gbogbo wọn, titi ti ẹmi yoo fi bọ lara wọn, ọdun 1949 si ni awọn ọdaran naa dagbere faye.