Ìdájọ́ kò dá ọkọ mi padà ṣùgbọ́n mó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìdájọ́ òdodo- Ìyàwó Timothy Adegoke

Aya oloogbe Timothy Adegoke, Bolatito Adegoke ti salaye bi inu rẹ ati ti awọn ọmọ oloogbe ṣe dun si idajọ ti ile ẹjọ gbe kalẹ fun awọn afurasi ti ofin mu lori Iku ọkọ rẹ.
Timothy Adegoke, akẹkọọ fasiti Obafemi Awolowo lo jade niluu Ile Ife lẹyin to sun ni Ile ìtura kan, tí iwadi ati ototonu Ile ẹjọ fihan pe awọn osisẹ Ile Ìtura naa ṣekupa ni.
Ninu idajọ rẹ, Onidajọ Adepele Ojo fi idi rẹ mulẹ pe lootọ ni Timothy Adegoke wọ sinu ile itura Hilton Hotel, o si sanwo sinu aṣuwọn ifowopamọsi olujẹjọ keje.
Ileẹjọ naa tun fi kun un pe ẹri to wa niwaju ilẹ ẹjọ ọhun fihan pe Oyetunde Kazeem wa lara awọn to ṣe iṣẹ ibi naa, nitori eyi oun pẹlu jẹbi ẹsun wọnyii.
Nigba to n sọrọ, Aya oloogbe ni idajọ ti wọn ile ẹjọ gbe kalẹ ko da ọkọ oun pada sugbọn idajọ ododo to jẹyọ dun mọ ohun ninu pupọ.
O ni Ọlọrun ti ja fun idile Adegoke, ti ko si si nnkan to yí pada.
"Inu mi dun, ayọ mi kun lori idajọ naa. O jẹ ki idajọ mi kun si pe Ọlọrun alaye si wa pẹlu wa.
"Mo ti sọ ireti nu lori idajọ ododo ati pe ko si Ọlọrun mọ.
"N ko le parọ lati igba ti ọkọ mi ti ku, gbogbo nnkan ti mo n ro ko ba ti eeyan mu mọ sugbọn nigba ti idajọ ododo waye, inu mi dun.
Iyawo Timothy Adegoke ni bi ileęjọ ṣe ni kí awọn idile Adedoyin san ọwọ ile ẹkọ awọn ọmọ ko da ọkọ oun pada sugbọn ko si nnkan to da.
"Pe wọn yoo ma san ọwọ ile ẹkọ awọn ọmọ mi ko da nnkan sugbọn pe a rí idajọ ododo gba lọ dun mọ wa ninu ju.















