Raheem Adedoyin ọmọ Olóyè Rahmon Adedoyin tí di ọ̀daràn tí wọ́n wá káàkiri àgbayé títí ọwọ́ òfin yóò fi tẹ̀ẹ́!– Adájọ́

Oríṣun àwòrán, Others
Adajo Àgbà ile ejo giga ni ilu Osogbo ipinle Osun, Onidajo Adepele Òjó, ti ni pe Raheem Adedoyin Ọmọ Dókítà Rahmon Adedoyin ti da ọdaran ti wọn n wa kaakiri agbaye bayii.
Adajọ Ojo lo sọ bẹẹ lasiko to n ka idajọ lori bi wọn ṣe ṣekupa arakunrin Timothy Adegoke to jẹ akẹkọọ fasiti OAU, ni ipinlẹ Osun.
Saaju ni awọn ẹlẹri ti ni Raheem Adedoyin lo gbe oku naa sinu ọkọ lọ ju si opopona, lẹyin to sọ fun ọkan lara awọn oṣiṣẹ pe oun ti pe ọlọpaa ti ọlọpaa si ti ni ki awọn gbe oku naa lọ si mọsuari.
Amọ lẹyin ti wọn ṣe oku naa baṣubaṣu ni arakunrin naa na papa bora ti wọn ko si ri lati ọjọ pipẹ.
Ninu idajọ rẹ, Adajọ ni nitori ọmọkunrin naa na papa bora lẹyin to lọwọ ninu iṣekupani naa, o ti di ọdaran, ti orukọ rẹ si ti wa ninu awọn ti wọn n wa kaakiri agbaye, titi ti ọwọ ofin yoo fi tẹ ẹ.
Saaju ni adajọ ti dajọ iku nipa yiyẹgi fun baba rẹ, Dokita Rahmọn Adedoyin lẹyin ti adajọ ni pe o jẹbi ẹsun ipaniyan ati gbigbimọpọ pa eniyan.
Adajọ da ẹjọ naa fun oludasilẹ ile itura Hilton Hotel nilu Ile Ifẹ, Ọmọwe Ramon Adedoyin atawọn oṣiṣẹ ile itura naa mẹta miran lori iku akẹkọọ fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ, OAU ti ilu Ile ifẹ, Timothy Adegoke.

Oríṣun àwòrán, @Others
Kini Adajọ Ojo tun sọ?
Adajọ agba ipinlẹ Ọṣun, Adepele Ojo wa dajọ ki wọn lọ yẹgi fun Oloye Adedoyin.
Oloye Adedoyin di ero ile ẹjọ pẹlu awọn mẹfa lara awọn oṣiṣẹ rẹ lori ẹsun mejidinlogun to nii ṣe pẹlu ipaniyan, igbimọpọ lati ṣekupani pẹlu imulẹ atawọn ẹsun miran.
Adajọ agba ipinlẹ Ọṣun, Onidajọ Adepele Ojo, ninu idajọ to gbe kalẹ lori ẹjọ naa lọjọ Iṣẹgun, tu mẹta ninu awọn olujẹjọ silẹ labẹ ẹsun ipaniyan, igbimọ pọ lati ṣeku pani.
Awọn ti wọn tu silẹ naa ni Magdalene Chiefuna, Lawrence Oluwole ati Adedeji Adesola.
Amọ ṣa, Onidajọ Adepele Ojo ni wọn jẹbi awọn ẹsun yooku.
Adajọ naa ni Oloye Adegoke Adedoyin jẹbi ẹsun ikini, ikeji, ikẹta, ikeje, ikẹsanan, ikarundinlogun ati ikẹrindinlogun.
Awọn oṣiṣẹ ile itura naa mẹta ti ile ẹjọ da lẹbi pẹlu Oloye Adedoyin ni Adeniyi Aderogba, Oyetunde Kazeem ati Adebayo Kunle.
Bakan naa ni adajọ tun ni idajọ tẹsiwaju ni ọla lẹyin ti awọn agbẹjọro bẹbẹ fun ọkan lara awọn oṣiṣẹ naa, ti wọn si ni pe oun gan an lo jẹ ki wọn ri kulẹ kulẹ iṣẹlẹ naa.
Ohun miran wo lo wa ninu idajọ naa?
Ile-ẹjo tún pàṣẹ e pè ki ilé ìtura Hilton, Ile ifẹ, tó jẹ́ tí Dókítà Rahmon Adedoyin dí tí ijoba Ìpínlẹ̀ Ọsun.
Ilé ìtura Hilton yìí ni Timothy Adegoke tí ó jé akẹ́kọ̀ọ́ Fáṣítì OAU kú sí losu kọkànlá, ọdún 2021.
Lara ìdájọ́ Onidajo Adepele Ojo tún sọ pé kí moto Hilux funfun tí ọmọ Dókítà Adedoyin, Raheem, àtàwọn òṣìṣẹ́ rẹ méjì fí gbé òkú Timothy Adegoke lọ ju sínú igbó ni òpópónà Ede yíò dí tí ijọba Ìpínlẹ̀ Ọsun.
Adajọ àgbà nipinlẹ Ọsun, Onidajo Adepele Ojo sọ nínú ìdájọ́ rẹ pé Abdulraman Adedoyin, Kazeem Oyetunde àti Adeniyi Aderogba ló jẹ́bí ẹ̀sùn tí wọn fí kàn wọn, tí wọn sì ìdájọ́ ikú fún wọn.
Ìdájọ́ náà tún tesiwaju pé kí wọn má a fi dúkìá Dókítà Abdulraman Adedoyin tí wọ́n dájọ́ ikú fún ati awọn òṣìṣẹ́ rẹ gbọ bùkátà àwọn ọmọ olóògbé Timothy Adegoke títì ti wọn yóò fí parí ilé ẹkọ Fáṣítì.












