Bàbá àwọn ọmọ mi ni Damola Olatunji jẹ́, a kò fìgbà kankan ṣègbéyàwó, a sì ti pínyà– Arugba

Oríṣun àwòrán, @Arugba
Ilumọọka oṣere tiata ati sinima, Bukọla Awoyẹmi ti ọpọ mọ si Arugba ti kede pe oun ati ọkọ oun, Damọla Ọlatunji, ti oun pẹlu jẹ eekan oṣere sinima ti pinya.
O ti to ọjọ mẹta bayii ti iroyin ti n lọ kiri nipa ipo ti igbeyawo awọn mejeeji yii wa lọwọ.
Arugba fi lẹta kan ti awọn agbẹjọro rẹ kọ si oju opo Instagram rẹ lọjọ Iṣẹgun, ninu eyi to ti y oju ọrọ naa sita pe awọn mejeeji ti pinya.
Gẹgẹbi ohun ti awọn agbẹjọro rẹ kọ si inu lẹta naa, Arugba ni ko si igba kan ti oun ati ọkọ oun, Damla Ọlatunji jọ ṣe igbeyawo, bi o tilẹ jẹ wi pe wọn bi ibeji - ọkunrin kan ati obinrin kan.
“A fẹ ki ẹ m eyi pe, onibara wa, Bukọla Awoyẹmi ati Ọgbẹni Damọla Ọlatunji ko si papọ mọ. Wọn tipinya laisi ẹtanu kankan. Ko si igba kan ti wọn jẹ lọkọlaya ninu igbeyawo ṣugbọn wọn bi ibeji.”

Oríṣun àwòrán, Olubukọla_Arugba/instagram
Lẹta naa tun jẹ ko di mimọ pe awọn mejeeji ti jọ ni adehun lori jijumọ tọju awọn ọmọ mjeeji yii.








