Bí wọn kò ṣe pè mí síbi àmì ẹ̀yẹ AMVCA dàbí ìgbà tí wọ́n bá dìtẹ̀ mọ́ mi – Ibrahim Chatta

Oríṣun àwòrán, Ibrahim Chatta
Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Ibrahim Chatta, ti sọ pe bi wọn ṣe n yọ ọwọ oun kuro lawo awọn ami ẹyẹ ere tiata ni Naijiria da bii pe wọn n ditẹ mọ oun ni.
Chatta lo sọrọ naa ninu ifọwero kan lori redio Lagelu FM, to wa niluu Ibadan.
Ọrọ yii lo n jade lẹyin ami ẹyẹ Africa Magic Viewers’ Choice Awards, AMVCS, to waye lẹnu lọlọ yii.
Ṣaaju ni ọpọ awọn ololufẹ rẹ ti kọkọ n woye eredi ti wọn ko ṣe kofiri rẹ nibi ami ẹyẹ naa nigba ti ọpọ awọn akẹgbẹ rẹ wa nibẹ.
Pupọ ninu awọn eeyan naa ni wọn gbagbọ pe o yẹ ki wọn fun ni ami ẹyẹ fun iṣẹ ribiribi to ṣe ninu ere ‘King of Thieves,’ ti wọn si fa ere naa kalẹ gẹgẹ bii eyii to milẹ titi.
Gẹgẹ bii oun ti Chatta sọ, yatọ si pe wọn kii fa oun kalẹ fun ami ẹyẹ, wọn ko tun fiwe pe oun si gbagede ibi ti ami ẹyẹ naa ti waye.
O ni bi wọn ko ṣe fi orukọ oun silẹ lara awọn ti yoo gba ami ẹyẹ ko dun oun, amọ o jẹ oun iyalẹnu pe wọn ko tun fi iwe pe oun sibi ami ẹyẹ naa.
“Ko dun mi bi wọn ko ṣe fun mi ni ami ẹyẹ nitori ko si bi eeyan ṣe le mura siṣẹ to, awọn akẹgbẹ rẹ naa n ṣiṣẹ, ẹni to basi ṣe daadaa ju ni wọn maa n mu lẹẹkan lọdun.”
“Amọ iṣoro to wa nibẹ ni pe wọn kii fiwe pe mi, eyii to mu ko da bii pe ṣe ni wọn n ditẹ mọ mi.”
“Lootọ ni pe kii ṣe gbogbo eeyan ni wọn maa fun ni ami ẹyẹ ṣugbọn o yẹ ki wọn fiwe pe mi sibi eto naa.”
“Nigba mii mo maa n ro pe iṣẹ mi ni ko to nitori mo maa n ri awọn ọmọ to ṣẹṣẹ bẹrẹ iṣẹ nibi eto naa…”
Chatta pari ọrọ rẹ pe bi wọn ṣe yọ ọwọ oun kuro lawo ami ẹyẹ naa ko ni yẹ oju oun kuro lara afojusun oun.
Lẹyin naa lo ni ami ẹyẹ Oscar gangan lo n wu oun lati gba, oun si gbagbọ pe Ọlọrun yoo jẹ ko ṣeeṣe.












