Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ajìjàgbara ‘Yoruba Nation’ làwọn jàǹdùkú tó kọlú iléeṣẹ́ rédíò Amuludun n’Ibadan -Ọlọ́pàá

Aworan awọn janduku ti ọlọpaa mu ati aworan aṣia Yoruba nation

Oríṣun àwòrán, other

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti fi ọrọ lede lorii bi kele ofin ṣe gbe awọn eeyan marun-un otootọ ti o jẹ ọmọ ẹgbẹ to n ja fun dasilẹ orilẹ-ede Yoruba ti wọn pe ni 'Yoruba Nation', lẹyin ikọlu ti wọn ṣẹ si ileeṣẹ redio apapọ Naijiria, Amuludun FM to n bẹ ni agbegbe Moniya nilu Ibadan l'owurọ ọjọ Aiku.

Ninu atejadẹ ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Ọṣifẹsọ Adewale fi ṣowo si BBC Yoruba, wọn ṣe alaye wi pe ni nnkan bii aago mẹfa idaji ni ileeṣẹ ọlọpaa gba ipe pajawiri wi pe awọn ajijagbara kan ti yabo ileeṣẹ redio Amuludun 99.1 FM pẹlu erongba lati kede ominira ara wọn kuro lọwọ ijọba Naijiria lori redio naa.

Awọn afurasi ti wọn mu ni ibi iṣẹlẹ naa pẹlu okanojọkan ogun ti wọn di mọra ni, Noah Atoyebi ẹni ogbọn ọdun, Gbenga Adeleke ẹni ọdun mẹẹdọgbọn, Abdulganiyu Mustafa Kolawole ẹni ọdun marunlelọgbọn, Bashiru Kehinde O., ati Fajola Elija eni ọdun marundinlaadọta.

Ileeṣẹ ọlọpaa fi idi rẹ mulẹ wi pe ko si oṣiṣẹ ileeṣẹ redio naa kankan to fi ara pa nibi iṣẹlẹ naa nitori awọn ẹṣọ aabo tete fi ara han nibẹ.

Ni bayii, igbakeji Kọmisana Ọlọpaa n'ipinlẹ

Ọyọ ti le iwaju isẹ iwadii ati ofintoto lori iṣẹlẹ naa, ki wọn le nawọ gan awọn ti o ba tun ku ninu awọn afurasi naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa fi idaniloju han wi pe aabo to daju too waye nibi ayẹyẹ ijọba tuntun ti yoo gun ori aleefa lọla ode yii, gẹgẹ bi wọn ṣẹ n ke si gbogbo obi ati alagbatọ pe ki wọn mojuto awọn ọmọ wọn ki ẹnikẹni ma baa lo wọn lati da omi alaafia ilu ru.

Ẹgbẹ Yoruba nation ni awọn kọ lo kọlu ileeṣẹ redio Amuludun

Nibayii, ẹgbẹ ajijagbara Yoruba Nation ti pariwo sita pe awọn kọ lo wa nidi ikọlu si ileeṣẹ redio Amuludun lọjọ Aiku.

Ọkan lara awọn agbẹnusọ fun ẹgbẹ naa, Koiki ṣalaye loju opo ayelujara rẹ pe ikọlu naa kii ṣe iṣẹ ọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa ati pe awọn janduku kan to wa labẹ eeyan kan ti wọn n pe ni Onitiri ni wọn ṣe iṣẹ laabi naa.

Koiki ni awọn janduku naa ti wọn n pe ara wọn ni ‘fake ominirayoruba22’ ni wọn n pe ara wọn ni mọ “ẹgbẹ Yoruba Nation”

Àwọn jàǹdùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amuludun FM n'Ibadan, já ètò gbà mọ́ àwọn òṣìṣẹ́ lọ́wọ́

Aworan iwọde kan

Oríṣun àwòrán, other

Ọrọ di boolọ yago ni ileeṣẹ redio apapọ Naijiria ẹka ti Amuludun 99.1fm to wa lagbegbe Moniya ni ilu Ibadan lọjọ Aiku pẹlu bi awọn ọdọ kan ṣe kọlu ileeṣẹ redio naa.

Iroyin sọ wi pe ṣe ni awọn ọdọ naa n fi ẹhonu han lori awọn ohun kan ti a ko tii le fi idi rẹ mulẹ lasiko ti a fi n ko iroyin yii jọ.

Gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ, awọn ọdọ naa dede yawọ ileeṣẹ redio naa, wọn si ja gbogbo eto ti wọn ṣẹ lọwọ lori afẹfẹ gba.

Botilẹ jẹ pe eredi ti wọn fi gbe iru igbesẹ naa ko tii han si ẹnikẹni titi di akoko yii, ohun ti a le fi idi rẹ mulẹ ni pe awọn ẹṣọ aabo ti fi ara han nileeṣẹ redio naa, wọn si ti le awọn janduku naa lọ.

Iroyin ti a gbọ sọ pe nnkan bii agogo mẹfa owurọ ni awọn janduku naa de si ayika ileeṣẹ naa. Gbogbo awọn oṣiṣẹ to wa lẹnu iṣẹ atawọn to ṣiṣẹ lalẹ mọju ti wọn si n sun orun diẹ ki wọn to gba ọna ile lọ ni wọn sare asadiju fun ẹmi mi lasiko ti awọn janduku naa bẹrẹ wahala wọn.

L'ọjọ kẹwaa oṣu kẹwaa ọdun 2007 ni wọn da ileeṣẹ redio Amuludun silẹ, Yoruba ponbele si ni wọn fi n ṣe eto nibẹ.

Ẹkunrẹrẹ iroyin n bọ laipẹ