Ààrẹ Buhari tọrọ àforíjì ní ọwọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà nínú ọ̀rọ̀ ìdágbére rẹ̀

Oríṣun àwòrán, muhammadu buhari/twitter
Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti tọrọ aforiji lọwọ awọn ọmọ Naijiria ninu ọrọ idagbere rẹ.
Aarẹ Buhari sọ eyi ni owurọ Ọjọ Aiku to ku ọjọ kan ko gbe ijọba kalẹ fun Bola Tinubu ti awọn araalu dibo yan.
Ninu ọrọ rẹ, aarẹ Buhari ni ki awọn araalu dariji oun fun awọn agbekalẹ ijọba oun to mu inira ba awọn ọmọ Naijiria.
O ni awọn gbe igbeṣẹ naa lati mu ki ọrọ aje Naijiria ma dẹnukọlẹ pẹlu bi nkan ṣe n lọ ni agbaye.
O ni lọna ati mu ki eto ọrọ aje Naijiria ni idagbasoke awọn gbe awọn igbesẹ kọọkan to mu inira ba awọn ọmọ Naijiria to si tọrọ idariji lọwọ wọn.
Aarẹ ni awọn mọ daju pe awọn igbeṣẹ naa ko ba awọn araalu lara mu, amọ awọn nilo lati gbe igbeṣẹ na.
O ni igbeṣẹ ijọba naa mu itẹsiwaju ba eto ọrọ aje ni Naijiria, ti o si n so eso rere.
Ọjọ Aje, Ọjọ Kọkandinlọgbọn ni ijọba aarẹ Buhari yoo dopin lẹyin ti o lo ọdun mẹjọ ni ipo.
Ààrẹ Buhari bá àwọn ọmọ Nàìjíríà sọ̀rọ̀ ìdágbére, àwọn kókó pàtàkì tó jẹyọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, muhammadu Buhari/twitter
Ko si ohun to ni ibẹrẹ ni awọn agba a maa wi.
Ijọba aarẹ Buhari to bẹrẹ pẹlu ọrọ akọkọ rẹ si awọn ọmọ Naijiria ti n lọ si opin diẹdiẹ pẹlu ọrọ idagbere aarẹ si araalu.
Lori ẹrọ amohunmaworan ni aarẹ ti ba awọn araalu sọrọ ni igba ikẹhin.
Aarẹ Buhari yoo gbe ijọba kalẹ fun Bola Ahmed Tinubu ti araalu dibo yan.
Ayẹyẹ igbejọba kalẹ yi yoo waye lọjọ Aje tii ṣe ọjọ Kọkandinlọgbọn oṣu yi.
Ṣaaju asiko yi ni aarẹ ba araalu sọrọ.
Ninu ọrọ aarẹ, o dupẹ lọwọ araalu fun atilẹyin ijọba rẹ bẹẹ naa lo si fi imoore rẹ han ni paapa adura araalu lasiko ti o wa nipo ailera ni saa rẹ akọkọ.
Bi esi idibo ko ba tẹ yin lọrun, ẹ gba ile ẹjọ lọ
Aarẹ gbosuba fun eto idibo to waye eleyi to juwe gẹgẹ bi eyi ti wọn fi tara tara dije rẹ julọ ninu akọsilẹ itan idibo Naijiria.
Bakan naa ni aarẹ mẹnu ba ọrọ gbigba fun ohunkohun ti ileẹjọ ba sọ ni paapa lori ọrọ esi idibo to waye.
O ni ilana eto idibo Naijiria faaye lẹ fun gbigba ile ẹjọ lọ ti abajade ko ba tẹ eeyan lọrun.
O ni idi ree tawọn ti esi idibo ko tẹ lọrun fi lanfaani lati kọdi sile ẹjọ.
Amọ o ni '' bo ti le wu ku idajọ ile ẹjọ le jẹ,mo rọ gbogbo awọn ti ọrọ kan lati gba idajọ yi pẹlu ọkan kan ki ẹ si pawọpọ lati mu agbega ba Naijiria''
'Tinubu ni oludije to ja fafa julọ'

Oríṣun àwòrán, Muhammadu Buhari/twitter
Labẹ eleyi, aarẹ kan saara si Bola Ahmed Tinubu ti araalu dibo yan gẹgẹ bi aarẹ.
O ṣapejuwe Tinubu gẹgẹ bi ẹni ti ni kaitiyan ti o si ni ifẹ ilu lọkan.
Buhari loun ni igbagbọ pe Tinubu yoo tẹsiwaju pẹlu ibi ti ijọba oun ba eto ilu de.
O ni Tinubu ni oludije to pegede julọ ninu awọn oludije to du ipo aarẹ.
O pari ọrọ rẹ lori Tinubu pe ''awọn araalu yan daadaa''
Ọmọ Naijiria,ẹ ji,ẹ ma sun lori ọrọ aabo

Oríṣun àwòrán, muhammadu buhari/twitter
Labẹ ọrọ ti aarẹ sọ ni idagbere lori eto aabo.
O ni ijọba oun gbiyanju lati mu adinku ba iwa agbesunmọmi,janduku, adigunjale ati awọn ipenija mii.
Aarẹ sọ pe lati le mu ki awọn aṣeyọri toun ṣe tẹsiwaju, o sọ faraalu pe '' ẹ gbọdọ ri pe ẹ ko sun gbagbera,ki si pawọpọ pẹlu awọn agbofinro''
Labẹ ijọba aarẹ ipenija nla ni aabo jẹ ti ọpọ araalu si ni o ku diẹ kaato pẹlu bi aarẹ ko se koju awọn ipenija bi ajinigbe ati agbesunmọmi.
O jọ pe aarẹ naa gba awọn kudiẹkudiẹ yi ninu ọrọ rẹ pẹlu bo se ni oun n ba awọn obi kẹdun ọkan lori awọn ''ọmọ to wa ni igbekun'' ati awọn obi ọrẹ ati ẹbi ti o padanu ẹmi awọn eeyan wọn ninu awọn ikọlu ti ko nidi yi.
Aarẹ pari ọrọ rẹ lori aabo pe awọn agbofinro n ṣiṣẹ takun lati ri pe wọn tu awọn to wa ni igbekun silẹ lai si ipalara kankan fun wọn.
Awọn koko miran ti aarẹ mẹnuba
Ọrọ ti aarẹ sọ pọ amọ ni ṣoki awọn koko miran to mẹnu ba ree
- Aarẹ Buhari dupẹ lọwọ awọn aṣofin Naijiria fun atilẹyin ijọba rẹ
- Aarẹ sọ nipa akitiyan ijọba rẹ lati mu ọrọ aje Naijiria burẹkẹ si
- Igbiyanju ijọba rẹ lati ṣe agbekalẹ eto idibo to yanranti faraalu
- Igbiyanju lati koju iwa ajẹbanu ati riri owo gba pada lọwọ awọn to ko ọrọ ilu pamọ
- Ṣiṣe atilẹyin lati ri pe awọn ọmọ Naijiria di ipo giga mu lagbaye
- Aarẹ tọrọ aforinjin












