Buhari ṣì ní ẹ̀tọ́ di òru May 28 láti yáwó, gbé iṣẹ́ fún kọngílá síta- Fashola

Babatunde Fashọla SAN

Oríṣun àwòrán, @Fasola

Ijoba apapọ Naijiria ti fesi sí ọrọ ti awọn eeyan kan n sọ lori bi isejoba Buhari ṣe tun n ya alekun owo pẹlu bi o ṣe ku dẹdẹ ki saa rẹ pari.

Minisita fun iṣẹ ode ati ile gbigbe, Babatunde Fashọla, SAN ni titi di iṣẹju to kẹyin ninu saa ìṣèjọba yìí lawọn ṣi lanfani ati ya owo sii tabi gbe iṣẹ fun kọngila.

Ni oru ọjọ kejidinlọgbọ ni saa iṣejọba Buhari yoo pari lẹyin ọdun mẹjọ nipo ti Bọla Ahmed Tinubu yoo si gba aṣẹ iṣejọba gẹgẹ bi aarẹ orilẹede Naijiria.

Ilu Akurẹ ni ipinlẹ Ondo ni Minisita Fashọla ti sọ ọrọ yii lasiko to fi n ṣe ifilọlẹ atunṣe opopona onibeji Akurẹ si Ado Ekiti.

Amofinagba Babatunde Fashọla ni gbogbo awọn to n sọ ọrọ si ijoba lori idi to ṣi fi n ya owo fun iṣẹ akanṣe, dipo ki o fi silẹ fun ijoba tuntun to n bọ ṣalaye pe ọmọde lo n ṣe iru awon eeyan bẹẹ nitori pe “wọn ti gbagbe pe oganjọ oru ọjọ kejidinlọgbọn oṣu karun un ni saa ijọba yii ṣẹṣẹ pari.”

O ni oríṣiríṣi ahesọ ọrọ lawọn eeyan kan ti gbe kiri pe Fashọla ko fẹran Ekiti ati Ondo, eletito ni o ja si irọ patapata.

O fi kun un pe awọn kan mu aba wa pe ṣe ni ki ijọba kan da ọda si opopona naa ṣugbọn oun loun faake kọri pe rara, onibeji ni ki opopona naa jẹ, ijọba yoo si tun bẹrẹ lati ibẹrẹ pẹpẹ ni

Amofin Babatunde Fashọla ni bi idagbasoke nnkan amayedẹrun yoo ba wa ni awujọ, ọna meji laraalu yoo ti mu lati mu ki o ṣeeṣe -yala ki ijọba ya owo sii tabi ki ijọba fi kun iye owo ori lori araalu.

O ni aadọrun biliọnu naira ni atunṣe opopona naa yoo na ijọba, ọdun meji ni wọn yoo si fi ṣe e.