Bí wọ́n se jí adarí ìjọ Àgùdà gbé lọ rèé ní Okigwe ní ìpínlẹ̀ Imo

Oríṣun àwòrán, Facebook
Adari ile ijọsin Aguda, Jude Kingsley Maduka ni wọn ti jigbe ni ile ijọsin rẹ ni ilu Ogii town ni ijọba ibilẹ Okigwe, ni ipinlẹ Imo.
Iroyin ni Maduka lọ si ayẹwo awọn ori ijọ rẹ ni awọn ọdaran naa jigbe.
Ninu lẹta ti akọwe ile ijọsin naa fi lede, Princewill Iwuanyungu ni wọn ti sọ eyi.
Ọjọ kejilelogun, Osu Kẹsan an, ọdun 2012 ni wọn fi ami ororo si Maduka lori gẹgẹ bi adari ile ijọsin.
Maduka naa ni adari ile ijọsin King Catholic Church of Ezinachi/Ugwuago Parish to wa ni ilu Okigwe.
BBC Igbo kan si agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Imo, Henry Okoye ni ori foonu.
O ni awọn adigunjale naa lo sekọlu si ni nkan bi aago mẹjọ ale ni Ọjọ Ẹti.
Bakan naa lo fikun un pe igbiyanju ti n lọ lọwọ lati doola ẹmi rẹ, ati lati mu awọn to jigbe.
Amọ o fikun un pe titi di asiko yii awọn ko I tii gburo awọn ajinigbe naa, bẹẹ si ni wọn ko tii kan si mọlẹbi rẹ kankan.















