Àwọn ọlọ́pàá ti sọ̀rọ̀sókè fún Òbí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Fakunle lórí ìṣẹ̀lẹ̀ 'Tear gas' tó wáyé ní Osogbo lánàá

Àkọlé fídíò, "Afẹ́fẹ́ ló gbé teargas ọlọ́pàá wọ ilé ẹ̀kọ́ ní Osogbo, kìí ṣe ìkọ̀lù"
Akẹkọọ Ile ẹkọ Fakunle

Àwọn Ọlọpaa Mopol 39 squadron n'ilu Osogbo àti àwọn ọmọ ilẹ̀ ẹ̀kọ́ gírámà Fakunle fe koju ara wọn leyin ti wọn ti yín èéfín tajútajú sókè.

Ni déedé agogo mẹ́jọ àbọ̀ àárọ̀ ọjọ́ Iṣẹ́gun, ọjọ ketalelogun, oṣù karùn-ún, ọdún 2023 ni ìṣẹ̀lẹ̀ naa ṣẹlẹ̀ ní ilé ẹkọ girama kan tí wọn pé orúkọ rẹ ni Fakunle Comprehensive High School to wa ni òpópó ọna tó lọ sí IKirun nílùú Osogbo nipinle Osun.

Ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ náà ni bí àwọn Ọlọpaa tí wọn ń pè ní Mobile Police 39 squadron to wa ni adojú kọ ilé ẹkọ girama tí Fakunle Comprehensive High School ni àwọn Ọlọpa náà ti yín èéfín tajútajú (teargas) sókè.

Ni eyi tí afẹ́fẹ́ sì gbé lọ sínú ilé ẹkọ girama náà. Tó sì ṣe ìkọlù sì ọmọ mọ́kànlélógún nínú àwọn ọmọ ilé ẹkọ náà.

Nínú iwadii wá là gbọ pé àwọn ọmọ ilẹ̀ ẹkọ náà múra ìjà sí àwọn Ọlọpaa náà ṣùgbọ́n tí àwọn olùkọ́ wọ́n kó fi àayè silẹ fún ìwà bẹẹ rárá.

Nibo ni ọ̀rọ̀ dé dúró báyìí?

Lákòókò tí iko BBC News Yorubá ṣe abewo sí ilé ẹkọ náà lowuro ọjọ kẹrìnlelógún ni olórí ilé ẹkọ naa Nurat Hassan ṣe àlàyé díẹ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Adari ile ẹkọ Fakunle sọ pé lotítọ ni ìṣẹ̀lẹ̀ naa sẹlẹ, kí ìṣẹ̀lẹ̀ kò tó bẹ̀rẹ̀ ni àwọn tí lọ sọ fún àwọn Ọlọpaa náà ṣùgbọ́n wọn kò gbọ ọ̀rọ̀ sì àwọn lẹ́nu rárá.

Ṣùgbọ́n a dúpẹ́ pé gbogbo àwọn ọmọ tó fara gba ninu ìkọlù náà ni wọ́n ti kúrò ní ilé ìwòsàn láti àná.

Fakunle

Kini ileeṣẹ ọlọpaa sọ lori iṣẹlẹ naa?

Iko yí tesiwaju nínú iwadii wá sí ilé isẹ àwọn Ọlọpaa tí ìpínlẹ̀ Osun nibi ti Alukoro àwọn Ọlọpaa ipínlẹ̀ Osun, Yemisi Ọpalola tí fi idi ìṣẹ̀lẹ̀ naa múlẹ̀ pé lotítọ ni, ati pe àwọn tí ṣe abewo sì ilé ẹkọ naa àti ilé ìwòsàn tí wọ́n gbé àwọn ọmọ náà lọ.

Bakan naa ni ọga àwọn Ọlọpa nipinle, Osun Patrick Longẹ naa ṣe abewo sì ilé ẹkọ naa àti ilé ìwòsàn tí wọ́n gbé àwọn ọmọ náà lọ.

Nibẹ lọ lo tí sọ̀rọ̀ tó sì fi wọ́n lọ́kàn balẹ pé irú èyí kò ní sẹlẹ mọ.

Kini ilééṣe ijọba to n mojuto ọrọ eto ẹkọ sọ?

Akowe àgbà eto ẹ̀kọ́ ni Ipinle Osun Ministry of Education, Adelani Aderinola lo sọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ pé àwọn ọmọ náà tí rí ìwòsàn.

Bẹẹ sì ni àwọn tí bá ọga Ọlọpaa ṣe ìpàdé papọ lọ iṣẹlẹ náà tí ọga Ọlọpaa Patrick Longe sì fi àwọn lọkan balẹ pé kò sí irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹẹ mọ.

Ó tún sọ̀rọ̀ nínú ọ̀rọ̀ pé àwọn ọmọ tí ìkọlù náà kọlu lo jẹ mọ́kànlélógún 21 gẹ́gẹ́ bí àlùkò àwọn Ọlọpa náà se se alaye.

Teargas tí àwọn ọlọ́pàá tú sílẹ̀ sọ ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ di èrò iléèwòsàn ní Osogbo

Awọn ọlọpaa to n yin teargas

Oríṣun àwòrán, EPA

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ipaya gba ilu Osogbo lọjọ Iṣẹgun, lẹyin ti iroyin jade si ilu pe awọn akẹkọọ ile ẹkọ ghirama Fakunle Comprehensive School, Osogbo, kan di eero leewosan lẹyin ti wọn fa afẹfẹ gaasi simu.

Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Karun-un, ni iṣẹlẹ naa waye.

Iroyin sọ pe awọn akẹkọọ kan daku rangbọndan lẹyin ti wọn fin afẹfẹ teargas, eyi ti awọn ọlọpaa kogberegbe, ti ọfiisi wọn wa ni adojukọ ile ẹkọ naa tu teargas silẹ.

Awọn ọlọpaa naa ni ibudo PMF 39, Osogbo, la gbọ pe lasiko ti wọn n dan awọn irinṣẹ wọn wo ni nnkan bi aago mẹsan-owurọ ni wọn tu afẹfẹ teargas naa silẹ.

Lẹyin ti wọn tu u silẹ, ni oorun ati eefin teargas naa wọ inu ọgba ile ẹkọ Fakunle, to wa ni adojukọ ọfiisi awọn ọlọpaa naa, ti awọn kan lara wọn fi daku.

Awọn akẹkọọ ọhun ti wa ni kilaasi wọn nigba ti iṣẹlẹ naa waye.

Kia si ni awọn olukọ, pẹlu iranlọwọ ileesẹ adoola ẹmi ti ipinlẹ Osun, bẹrẹ si ni gbe awọn akẹkọọ to daku, lọ si ileewosan aladani kan to wa nitosi , ati ileewosan fasiti ipinlẹ Osun.

Iroyin ohun to ṣẹlẹ yii lo mu ki ọpọlọpọ obi yabo ile ẹkọ naa lati mu ọmọ wọn lọ sile, ti awọn kan si n dari si ileewosan lati wa ọmọ wọn.

Oludari ajọ to adoola ẹmi nipinlẹ Osun, Elizabeth Arowosafe, sọ fun iwe iroyin Punch pe akẹkọọ mọkanla ni awọn gbe lọ si ileewosan Uniosun, nigba ti ko si aaye fun wọn mọ ni ileewosan aladani to wa nitosi ile ẹkọ naa.

Bakan naa ni awọn alaṣẹ ile ẹkọ girama naa paṣẹ fun gbogbo awọn akẹkọọ tó kù lati ma a lọ si ile wọn.

Ileeṣẹ ọlọpaa fesi lori iṣẹlẹ naa

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Osun, Arabinrin Yemisi Opalola, sọ ninu atẹjade kan to fi sita ni owurọ Ọjọru pe awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa ṣe abẹwo si ile ẹkọ ọhun, lati wo bi nnkan ṣe ri.

“Gbogbo awọn akẹkọọ naa lo ti gba itọju nileewosan, ti wọn si ti pada si ile awọn obi wọn.”

Bakan naa ni Arabinrin Opalola sọ p bi awọn ọlọpaa ṣe tu teargas silẹ kii ṣe tuntun, nitori pe ara awọn igbaradi wọn ni gbogbo igba ni.

O ni afẹfẹ lo gbe eefin gaasi naa wọ inu ọgba ile ẹkọ.