UK tí ṣòfin, akẹ́kọ̀ọ́ ilẹ̀ òkèèrè kò ní ráyè kó ẹbí dání bẹ̀rẹ̀ ní 2024

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn akẹkọọ to wa fawọn eto ẹkọ giga kan(postgraduate students on non-research courses) ko ni lanfaani lati gbe awọn mọlẹbi wọn lọwọ labẹ ofin tuntun to fẹ mu adinku ba ajoji to n wọ ilẹ Gẹẹsi.
Ikede yi n waye lọjọ meji ṣaaju ọjọ ti wọn yoo gbe akojọpọ iroyin to ṣafihan pe iye awọn to n gba ọna ẹburu wọ ilẹ Gẹẹsi ti to 700,000 lọdun yi.
Lọdun to kọja iwe igbelu visa 135,788 ni wọn fun awọn to tẹle akẹkọọ ilẹ okere wa ti eleyi si fẹ sunmọ ilọpo mẹsan iyi iwe ti wọn fi sita lọdun 2019.
Olotu ijọba Rishi Sunak sọ fawọn minisita pe igbesẹ yi yoo mu adinku ba iye awọn to n wọ ilẹ wọn.
O sọ fawọn igbimọ alaṣẹ pe ilana tuntun yi ti yoo bẹrẹ ni ọdun 2024 yoo mu iyatọ to lapa ba iyen awọn to n wọlu bayii.
Amọ ko le sọ ni pato iru ipa ti yoo ko lara iye awọn to n wọlu tori pe wọn kii ka awọn akẹkọọ to wa n kawe ọlọdun kan ati mọlẹbi wọn papọ.
Lọsẹ to kọja,o ni awọn minista n ṣagbeyẹwo awọn '' ilana meloo kan'' lati mu iye awọn to n wọ ilẹ wọn ku ṣugbọn ko si alaye pato lori dedee iye eeyan ti wọnfẹ dinku si.
Ẹgbẹ Conservatives ti ṣaaju ṣe ileri lati mu iye awọn to n wọ ilẹ wọn wa sile di bi 100,000 lọdun ṣugbọn wọn pa ọrọ yi ti ṣaaju idibo ọdun 2019 lẹyin ti wọn ko ribi sọ di imuṣẹ.
Labẹ ikede tuntun yi,awọn mọlẹbi akẹkọọ ti ko si lara awọn ti ijọba ṣa lẹṣa ko ni ribi bawọn gbe nilẹ Gẹẹsi.
Lọdun to kọja visa 135,788 ni wọn fawọn mọlẹbi to tẹle akẹkọọ wa ti eleyi si jẹ alekun si 54,486 ti wọn fun ni visa lọdun 2021.
Iye yi le ni ilọpo meje visa 19,139 ti wọn fawọn eeyan lọdun 2020.
Iye awọn wọnyi ti lekun si lati igba ti wọn ti bẹrẹ si ni faaye gba awọn ti kii ṣe akẹkọọ lati ilẹ Yuroopu wọle lẹyin Brexit.
Bẹẹ naa si ni awọn to n kọwe lati wọle ṣe n pọ si lẹyin ti iyipada faaye gba ki awọn akẹkọọ ilẹ okere lanfaani ọdun meji lati duro waṣẹ nilẹ Gẹẹsi lẹyin ti wọn pari ẹkọ wọn.
Akọwe ileeṣẹ eto abẹle Suella Braverman sọ pe ''alekun yi kọja tatẹyinwa ati pe asiko to bayii lati funkun mọ lilo oju ọna yi ki a baa le mu adinku ba iye awọn to n wọ ilẹ wa.''
Ninu ọrọ rẹ si ile a'sofin, o fi kun pe igbesẹ yi mu dọgba n dọgba wa laarin mimu adinku ba iye awọn to n wọ ilẹ Gẹẹsi ati didaabo bo anfaani fọrọ aje ilẹ naa latara fifaaye gba awọn akẹkọọ lati ilẹ okere.
Ṣé lóòtọ́ ni UK fẹ́ fi òfin de kíkó ẹbí dání gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ̀ọ́ láti ilẹ̀ òkèèrè?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn iroyin to n lọ ni pe ijọba Olootu ijọba United Kingdom, Rishi Sunak, yoo bẹrẹ agbeyẹwo ofin tuntun ti yoo fi ofin de awọn akẹkọọ masters ati phd lati ma a ko ẹbi wọn wa si orilẹ-ede naa.
Iwe iroyin The Sun sọ pe Ọjọbọ ọsẹ yii ni igbesẹ naa yoo bẹrẹ.
Bakan naa ni awọn iroyin kan sọ pe ọjọ Iṣẹgun tabi Ọjọru, ni awọn minisita yoo kede awọn ọna ti wọn yoo gba lati gbogun ti igbesẹ kiko ẹbi wa gẹgẹ bi akẹkọọ.
Ṣaaju ni ijọba orilẹ-ede United Kingdom ti sọrọ nipa bi ọgọọrọ awọn akẹkọọ lati ilẹ okeere sẹ n ya wọ orilẹ-ede naa pẹlu ẹbí wọn, alti asiko diẹ sẹyin.
Abajade iwadii ti ijọba fi sita ni oṣu Kọkanla, ọdun 2022, fihan pe awọn ajeji ni orilẹ-ede naa ti pe 504,000.
Olootu ijọba UK sọ fun BBC pe awọn ajeji to n wa si orilẹ-ede naa ti pọ ju, ti oun si n wa oriṣiriṣi ọna lati mu adinku ba a.
Iroyin sọ pe Sunak n wa ọna lati din bi awọn akẹkọọ lati ilẹ okeere ṣe n lọ fun awọn eto ẹkọ (degree) ti ko pojuowo, ati bi wọn ṣe n n ko idile wọn wa.
Bakan naa, ni oṣu Kọkanla, ọdun 2022, akọwe ijọba, Suella Braverman sọ pe lootọ ni bi iye eeyan to n wọle si UK le ribẹ nitori ogun to n waye ni Ukraine, Afghanistan ati Hong Kong, ati paapaa nitori bi awọn eniyan ilẹ Gẹẹgi ṣe ko eeyan mọra.
O ni ṣugbọn “awọn araalu n reti ki a mojuto awọn ẹnu’bode wa, ka si mojuto mimu adinku ba awọn atipo”.
Ileesẹ to n ri si onka ni orilẹede UK, fihan ni oṣu Kọkanla ọdun 2022 pe eeyan bi 1.1 miliọnu lo wọ UK ni 2022, ṣugbọn nigba ti wọn ṣe iṣiro awọn to jade pada, awọn to n gbe ni UK ti lé si pẹlu 504,000.
Eyi ko ṣẹyin bi eeyan 170,000 lati Ukraine ṣe sa wa si UK nitori ogun Russia, ati eeyan 76,000 lati Hong Kong, to fẹ jẹ anfaani eto ijọba UK lati sọ awọn eeyan di ọmọ orilẹ-ede naa.
Yatọ si awọn eeyan naa, eeyan 277,000 lo tun wọ UK lati kẹkọọ, eyi to fẹ ẹ jẹ ida meji ti ọdun 2021.
Iye akẹkọọ lati ilẹ okeere to wa ni UK
- 2016/17: 450,835 - 19.0% of total
- 2017/18: 469,160 - 19.4%
- 2018/19: 496,110 - 20.2%
- 2019/20: 556,625 - 22.0%
- 2020/21: 605,130 - 22.0%
Iye owo ti awọn akẹkọọ lati ilẹ okeere ti san ni awọn fasiti ni UK
- 2016/17: £6.63bn - 37.3% of total
- 2017/18: £7.37bn - 38.7%
- 2018/19: £8.28bn - 40.8%
- 2019/20: £9.41bn - 42.9%
- 2020/21: £9.95bn - 42.4%
Akọsilẹ lati Higher Education statistics agency
Kini gbogbo eto yii tumọ si?
Botilẹ jẹ pe a ko tii le sọ awọn nnkan ti yoo wa ninu ofin tuntun naa, iroyin to n lọ ni pe yoo fi ofin de awọ̀n akẹkọọ ipele eto ẹkọ giga keji, Masters, lati ma a mu aya, ọkọ tabi ọmọ wa mọ.
Amọ ijiroro si n lọ pe ko ni i kan awọn akẹkọọ to n ṣe PhD, nitori eto ẹkọ ti wọn ma n gba ọpọ ọdun, bakan naa ni iṣẹ wa nilẹ fun wọn lati ṣe lẹyin eto ẹkọ wọn.
Akọsilẹ oṣu Kẹwaa 2022 fihan pe awọn ọmọ Naijiria lo ko ẹbi wọn wọle si UK ju awọn orilẹ-ede mii lọ, lọdun to kọja, paapaa gẹgẹ bi akẹkọọ.
Orilẹede India ni awọn akẹkọọ ti wa ju, lẹyin naa ni China to jẹ 114,837 – amọ 401 pere ni awọn ẹbi to tẹle wọn wa.
Ṣugbọn ni ti awọn ọmọ Naijiria, 34,000 ni awọn to wọ fasiti ni UK, wọn si ko ẹbi to jẹ 31,898 wọle.
Ohun kam to fojuhan ni pe ọrọ aje UK lọ soke si, nitori owo to wọle ni ẹka awọn abani ṣeto irinajo.












