Ọwọ́ tẹ ẹni ọdún 27 tí wọ́n furasí pé ó pa ìyá-àgbà ẹni ọgọ́rin ọdún lẹ́yìn tó fipá-bá-a lò-pọ̀

Ajọ ọlọpaa ipinlẹ Ondo lo ti fi oju afurasi ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn kan, Chinecherem Wiima, lede fun ṣiṣekupa iya ẹni ọgọrin ọdun kan, Felecia Aderibigbe.
Afurasi ọun to jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Ẹbọnyi to si fi ilu Ọrẹ ṣe ibugbe lati igba kekere rẹ ni wọn fi panpẹ ọba mu lẹyin ti wọn ba ẹrọ ilewọ oloogbe na lapo rẹ.
Wiima, gẹgẹ bi alukoro ajọ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Funmilayo Odunlami-Omisanya ṣe sọ, ni awọn araalu bẹrẹ si nii funra si lẹyin to lọọ ri mariwo ọpẹ mọlẹ niwaju ile oloogbe naa lalẹ ọjọ ti awọn ọmọ rẹ ko rii mọ.
Odunlami-Omisanya ni “Felicia Aderibigbe ni o di awati ni Ọjọru, ọjọ kejidinlogun oṣu yi lẹyin ti ko pada wale lati oko to lọ.
“Eyi lo mu ki awọn ọmọ rẹ o ke gbajare ti wọn si bẹrẹ sii waa kiri.
“Ni nkan bii aago mẹwaa alẹ ọjọ naa ni Wiima, to maa n ba iya naa ṣe iṣẹ oko, waa ri mariwo ọpẹ mọlẹ niwaju ile iya naa.”
Alukoro ajọ ọlọpaa naa tẹsiwaju pe “awọn araalu bere idi ti Wiima fi gbe iru igbesẹ yi amọ o wi fun wọn pe wọn yoo mo itumọ rẹ to ba di ọjọ keji.
“Eyi lo mu ki wọn muu ti wọn si ba foonu iya naa lapo rẹ leyi ti wọn fi faa le awọn agbofinro lọwọ.
“Ẹyin eyi ni wọn ri oku iya naa ninu oko ti ipo to wa si fihan pe wọn fi ipa baa lo pọ ki wọn to gba ẹmi rẹ.
“Lakoko iwadii wa ni afurasi naa ṣee lalaye pe niṣe ni ohun ba iboju, ada ati foonu iya naa ninu oko amọ ohun ko mọ boya oti ku nitori ohun ko rii”.
Afurasi ọun to ni iṣẹ ẹyin kikọ ni ohun n ṣe ṣalaye fun ikọ iroyin BBC Yoruba pe ohun ko fi oju kan iya naa depo pe ohun yoo gba ẹmi rẹ.
Wiima ni “nigba ti mo ri awọn ọmọ iya naa ti wọn paruwo wọ inu oko ni mo tẹle wọn.
“Akoko yi ni mo ri ada, foonu ati ibomu iya naa ti mo si koo”.
O fikun pe alaanu ohun ni iya naa jẹ ti ko le jẹ ki ohun o ṣee ni ijamba kọọkan.
Ẹwẹ, alukoro ajọ ọlọpaa ni afunrasi naa yoo foju ba ile ẹjọ lẹyin ti wọn ba pari gbogbo iwadi wọn.












