Ìpọ̀njú àti ikú ọkọ mí ló sún mí dé ìdí bàtà ṣíṣe

Àkọlé fídíò, Ka nipa iriri arabinrin to ṣe n bata alara fawọn gbajumọ ati oriade ilẹ Yoruba
Ìpọ̀njú àti ikú ọkọ mí ló sún mí dé ìdí bàtà ṣíṣe
Aworan Ololade

Ninu awọn obinrin to n gbe ohun rere ṣe ni ipinlẹ Osun ni Oyedeji Monsurat Ololade wa.

Oludasilẹ ati alakoso ileeṣẹ to n ṣe bata igbalode yi si ti sọ fun BBC nipa irinajo rẹ debi ti orukọ rẹ ti wa di ilumọọka.

Ọmọ bibi ilu Modakeke yi sọ nipa iriri rẹ ni paapa irinajo rẹ nile ọkọ ati bi iku ọkọ rẹ ṣe jẹ iṣẹlẹ manigbagbe niigbesi aye rẹ.

O ni'' A ko rinrinajo lọkọlaya pẹ ki iku to mu ọkọ mi lọ.Ọjọ kẹta ti ọmọ mi pe ọdun kan ni baba rẹ ku''

Monsurat ṣalaye pe ibeere toun kọkọ beere lọwọ awọn to wa pẹlu oun ni''bawo ni ṣe fẹ ṣe?''

Idahun si ibeere yi si wa nipa igbiyanju ati ipinnu si Ọlọrun pe ''ma jẹ ki n mọ wipe ọkọ mi ti ku.''

Awọn gbajumọ ati Ọba lo n ra bata mi

Ololade ṣalaye pe lati igba toun ti bẹrẹ bata ṣiṣe ni agbega ti n ba iṣẹ oun.

O ni oun mu iyatọ ba iṣẹ yi nipa iru bata to n jade lati ileeṣẹ rẹ.

'' Eko ti mo ni mu mi ro wipe ki ni mo le ṣe nidi bata yi.Awọn ijakulẹ ti mo ri lo mu mi ṣe iwadii ti mo si ri pe ọpọ owo ni Naijiria fi n ra bata lati ilẹ okere.''

O ni oun ko ri bata igbalode pupọ ni ilu Oṣogbo ati pe obinrin ko pọ nidi iṣẹ.

Nipa kikọ orukọ awọn eeyan si bata rẹ, eleyi mu ki iyatọ wa ninu bata rẹ.

O ṣalaye pe ninu awọn alabara rẹ ni King Wasiu Ayinde, Ọba Oluwo to fi mọ Ọba Modakeke.

O gba awọn to la idojukọ kọja pe ki wọn ma se wo wi pe o ti tan.

''Ọwọ wa nikadara wa wa. To ba ṣe pe iṣẹ aṣẹwo nimo yan laayo, mo le ti ku bayi''