Working religious women: Mo rí i pé kò sí obìnrin Mùsùlùmí tó n ṣe bàtà ló jẹ́ kí n kọ́ ọ - Aminat Adegoke
Elehaa Amina Adegoke to n ṣe bata ni BBC lọ ba lalejo lati jẹ ki awọn ọdọ, paapaa awọn obinrin to gba ẹsin ri awokọṣe rere lasiko yii.
Iṣẹ ni iṣẹ n jẹ ni ọrọ awọn agba nilẹ ku ootu, oojiire bi?.
Aminat jẹ iyawo ile ẹni ọdun mọkanlelọgbọn ti o gba ẹha lọdọ ọkọ rẹ ninu ẹsin Islam lai kabamọ.
O ṣalaye bi oun ṣe lọ kọ iṣẹ bata ṣiṣe ati irufẹ atilẹyin ti ọkọ rẹ fun un lasiko naa.
Eyi tun jẹ iṣẹ to ran si awọn ọkọ obinrin to ba gba ẹsin yala ti Musulumi tabi ti Kristiẹni tabi ti ẹlẹsin abalaye lati maa pese iranlọwọ ati atilẹyin to yẹ fun wọn.
- Ẹ̀nìkan sọ fún mi pé iṣẹ́ ìdọ̀tí ni màá ṣe láti là, ni mo ṣe ń ta ìwé lójú pópó - Wikipedia
- Mo tọrọ ikú pẹ̀lú májèlé torí wàhálà ọkọ́ àmọ́ Ọlọ́run kò fún mi - Onírú tí kò ríran
- "Mo fẹ́rẹ̀ ra ‘Sperm’ láti dá ọmọ bí torí n kò lọ́kọ títí di ẹni ọdún 47"
- Ẹni ọdún mẹ́rin ni mo bẹ̀rẹ̀ Kéwú, 1967 ni mo ṣe wòlímọ̀, mo lè kéwú láti ìbẹ̀rẹ̀ dópin- Tunde Bakare
Amina ṣalaye bi awọn onibara rẹ ọkunrin ṣe maa n fi Whatsapp baa sọrọ nitori wọn ti mọ pe Elẹhaa ni oun tabi ki awọn iyawo wọn ba oun sọrọ tabi ki wọn ba ọkọ oun sọrọ lori ẹrọ foonu oun.
O fihan pe ẹsin ko sọ pe ki eeyan ma ni apa lati ṣiṣẹ.
Elẹhaa Amina Adegoke wa gba awọn obinrin to gba ẹsin bii tirẹ niyanju pe ẹha ko yẹ ko di wọn lọwọ lati ṣe aṣeyọri.
O ni ki wọn gbiyanju ipa wọn pẹlu adura lọwọ Olorun fun aṣeyọri.

