Olawale Dada: Igbá bárà kọ́ ló kàn, àwa náà n ṣoríire láyé pẹ̀lú ìpèníjà 'Cerebral Palsy'

Àkọlé fídíò, Olawale Dada: Igbá bárà kọ́ ló kàn, àwa náà n ṣoríire láyé pẹ̀lú ìpèníjà 'Cerebral Palsy'

Mo ta gúgúrú rí, ṣùgbọ́n mo dúpẹ́ ibi ti mo dé lónìí, nítorí, mo níṣẹ́, mo gbéyàwó, mo tún bímọ- Olawale Dada

Oriṣiriṣii eeyan ni Elẹdaa da si aye bi o ṣe wu amọkoko lo mọ awọn ẹda ọwọ rẹ ni igbagbọ Yoruba.

Ogbeni Olawale Dada ree to jẹ oniṣowo to n ta ile, to n ta ilẹ, to tun n ba ni wale pẹlu gbogbo ipenija ara to n koju rẹ.

Olawale Dada ṣalaye kikun nipa bi oun ṣe n gbe pẹlu ipenija to jẹ ko nira lati rin, lati sọrọ daadaa ati lati yan fanda.

O ni ko rọrun rara ṣugbọn pẹlu ooreọfẹ Olorun.

Dada

Olawale Dada gba awọn to n la iru iṣoro ipanija ara yii kọja nimọran.

O ni gbigbe igab bara kọ ni o n kan ati pe ko si ohun ti Olorun ko le e ṣe ninu aye ẹda laye.

Olawale ni: Mo niṣẹ lọwọ, Mo gbeyawo, mo tun bimọ.

Dada

Olawale Dada gba awọn Obi awọn omo to ba ni ipenija ni imọran pe ko si nkan ti abara pa n ṣe ti awọn naa ko le ṣe laye.

Dada