Pictures of Buhari's son's wife: Àwọn ọmọ Nàìjíríà ń wa ẹnu lé ìyàwó ọmọ Ààrẹ Buhari torí àwọn aṣọ ìgbéyàwó rẹ̀ tó ṣí ara sílẹ̀

Zarah Nasir Ado Bayero

Oríṣun àwòrán, Other

Àwọn aworan ọmọ Emir Bichi, Zarah Nasiru Ado Bayero, tó fẹ́ ọmọkùnrin Ààrẹ Muhammadu Buhari, Yusuf Buhari tí kún fọ́fọ́ sí orí ayélujára tí àwọn ọmọ Nàìjíríà sì ń gbá yuun pẹlu ẹjọ́ lórí rẹ.

Ọmọbabìnrin ìlú Kano yìí tí ìròyìn ni yóò di ìyàwó ilé Yusuf Buhari nínú oṣù kẹjọ yìí ni a gbọ́ pé wọn yà fọto rẹ níbi eto ayẹyẹ idagbere tí àwọn obìnrin ẹlẹgbẹ ṣe fún un ní ìlú Abuja.

Ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ lọ sí ti ń jáde nípa irú aṣọ tí Zarah wọ.

Aṣọ funfun kan bí àṣà àwọn ó oyinbo tí ọ̀pọ̀ Kristẹni ń wọ ṣe ìyàwó lóde òní ni Zarah wọ tí àwọn kan sì ń sọ pé ìwọkuwọ lo wọ.

Lójú àwọn míì, ó si ara sílẹ̀ lápá ibi igba aya rẹ.

Zarah Nasir Ado Bayero

Oríṣun àwòrán, Other

Àmọ́ ibi tí wọn tilẹ̀ ń doju kọ ju ni ọdọ àwọn Ọlọpaa ẹsin Islam, Hisbah ni Kano tí wọn máa ń pariwo titẹle òfin Islam ni Ipinle naa.

Orúkọ Hisbah yìí ni àwọn èèyàn ṣáá ń rán mọ ẹnu lórí ayélujára laarin ọ̀sẹ̀ yìí.

Àkọlé fídíò, Oba Gbolahan Timson shomolu: Obasanjo ti jẹ́wọ́ pé 'Mistake' ni Buhari ṣùgbọ́n...

Nigba ti àwọn míì ń bu ẹnu atẹ lu àwòrán imura rẹ lórí ayélujára torí irú ìdílé to tí jáde àti èyí tó ń lọ, àwọn míì kò rí ohun kankan tó burú nínú aṣọ náà.

Won ni: fún irú ayẹyẹ tí àwọn obìnrin máa ń ṣe fúnra wọn ti ọkan bá fẹ́ lọ ilé ọkọ. Imura rẹ kò pọ to nkan táwọn obìnrin míì ń wọ fún irú ayẹyẹ idagbere yìí.

Ẹwẹ, irú itako báyìí kii se tuntun ni apa Ariwa orile-ede Naijiria níbi tí ẹsin Islam àti àṣà rẹ tí gbilẹ to sì pọn dandan.

Àkọlé fídíò, Igi Ọ̀pẹ abàmì tó dá ní orí 42 l'Ekiti rèé o, 'bí mo ṣe ríi l'orí mi ń dìde fììì'